NECO result 2020: Akẹ́kọ̀ọ́ 26, 277 ló pegedé ní ìdánwò NECO ọdún 2020 tó jáde

Oríṣun àwòrán, other
Fun awọn akẹkọọ to joko ṣedanwo NECO oṣu kọkanla ọdun to kọja, esi idanwo aṣekagba naa ti jade.
Ajọ NECO kede esi idanwo naa lowurọ Ọjọbọ ti wọn si ni laarin ẹgbẹrun mẹrindinlọgbọn ati ọrinlelugba o din mẹta (26,277) akẹkọọ ninu ẹgbẹrun mọkandinlogoji o le ẹẹdẹgbẹta ati mẹta (39, 503) akẹkọọ to jọko ṣe idanwo naa lo yege ninu imọ ẹkọ marun ninu eyi ti ẹkọ ede oyinbo ati iṣiro wa.
- A mú olódodo lọ́ ṣáájú ọjọ́ ibi - Leke Adeboye kọ lẹ́yìn ìròyìn pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Dare Adeboye jáde láyé
- Ọjọ́ 30 ni wọ́n fẹ́ fi gbé mi pamọ́, ariwo ọmọ ìjọ ló jẹ́ kí wọ́n tú mi sílẹ̀ - Father Mbaka
- Ṣé o mọ àwọn òrìṣà ìṣẹ̀mbáyé méje tó di ilẹ̀ gbogbo àgbáyé mú?
- Ọwọ́ NDLEA tẹ ìyá ẹni ọdún 80 pẹ̀lú oògùn olóró bíi kokeni, heroin, colorado àti skuchies
Ninu atẹjade kan ti akọwe agba ajọ NECO, Ọjọgbọn Godswill Obioma fi sita lolu ileeṣẹ ajọ idanwo naa to wa ni ilu Minna ni ipinlẹ Niger, ẹgbẹrun mọkanlelogoji ati ọtalerinwo o din ẹyọkan lawọn akẹkọọ to forukọsilẹ fun idanwo naa, ẹgbẹrun mọkandinlogoji o le ẹẹdẹgbẹta ati mẹta (39, 503) akẹkọọ lo joko ṣe idanwo ọhun.
O ni ẹgbẹrun mẹfa ati ọtalerinwo o le marun ni iṣẹlẹ aṣemaṣe to waye lasiko idanwo naa eleyi to kere si ẹgbẹ mẹtadinlogun o le mẹrin ni ọdun 2019.










