Laylatul Qadr: Wo pàtàkì alẹ́ ọjọ́ 10 tó gbẹ̀yìn àwẹ̀ Ramadan

Oríṣun àwòrán, Reuters
Oṣu Ramadan jẹ ọkan lara akoko ninu iwe kajọ kaṣu ẹsin Islam to wa fun iwẹnumọ fun awn Musulumi gẹgẹ bi wọn ṣe n ṣe iṣẹ ẹsin wọn.
Ẹwẹ, ọjọ mẹwa to gbẹyin ni asiko naa maa ṣe pataki gidi gan fun awọn Musulumi toripe wọn lee ṣe kongẹ oru ọjọ kan to n jẹ oru mimọ.
Wọn maa n pe alẹ ọjọ ọhun ni Laylatul Qadri eyi to lee tumọ si "alẹ pipaṣẹ agbara tabi ayanmọ".
Kí ló dé tí wọ́n ń wá Laylatul Qadr?
Laylatul Qadr jẹ ọkan lara awọn aṣalẹ to da yatọ ninu iwe kajọ kaṣu ẹsin Islam to si jẹ akoko ti Allah ṣe iṣipaya Quaran fun Anọbi Muhammad.
Alẹ ọjọ kan yii wa ninu alẹ ọjọ mẹwa to kẹyin lasiko awẹ Ramadan amọ ko sẹni to mọ ọjọ gangan to jẹ ṣugbn igbagbọ wa pe o ṣeeṣe ko jẹ ọkan ninu awọn ọjọ yii - ọjọ kọkanlelogun, ikẹtalelogun, ikarundinlọgbọn, ikẹtadinlọgbọn tabi ikọkandinlọgbọn.
O ni ọrọ Anọbi Mohammed kan to sọ pe "ẹnikẹni to gbadura lọjọ Laylatul Qadr ninu igbagbọ ati otitọ, yoo gba idariji gbogbo ẹṣẹ atẹyinwa rẹ".
Bakan naa ninu ẹsin Islam, wọn tun jẹ ko di mimọ pe bi eeyan ba gbadura ni alẹ yii, yoo da bii pe ẹni naa ti gbadura fun oṣu ẹgbẹrun kan gbako eyi to to ọdun bii mẹtalelọgọrin.
Ṣé o dara lati ṣe adura iṣọ oru(dua) lalẹ ọjọ yii?
Awọn ọmọwe ẹsin Islam ni ọkan lara adura gbọọrọ ti wọn maa n ṣe lalẹ Laylatul Qadr ni "O Allah, lootọ ni o n dariji, o fẹran iforiji, torinaa dariji mi (Allahumma innaka Afuwwun tuhibbul `afwa fa`fu `annee).
Ka Quran rẹ
Wọn maa n ri asiko Ramadan gẹgẹ bi oṣu Quaran torinaa awọn Musulumi a maa pa gbogbo iwe mii ti wọn ni ti lati gbajumọ kikọ, kika ati mimọ Quaran.
Tẹwọ adura fun ara rẹ
Wọn maa n gba awọn Musulumi nimọran lati ni akọsilẹ gbogbo nkan ti wn ba fẹ ki Ọlọrun ṣe fun wọn yala o kere tabi o tobi, gbadura naa daradara.












