IPOB Sit-at-home: Ìjọba ní ẹnikẹ́ni tó bá dá wàhálá sílẹ̀ lórúkọ IPOB yóò fojú winá òfin

Nnamdi Kanu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ṣeeṣe ki rogbodiyan bẹ silẹ lapa ila oorun guusu Naijiria nibi ti ẹya Igbo pọ si lẹyin edeaiyede to waye lori ofin joko sile ẹ, ti ẹgbẹ ajijagbara fun idasilẹ Biafra, IPOB ṣe fawọn ẹya Igbo.

Lọsẹ to lọ ni IPOB ti kọkọ leri pe ẹnikẹni ko ni lọ sibi kan nilẹ Igbo lati oni ọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu kẹjọ ọdun 2021, ayafi ti ijọba apapọ ba fi olori wọn, Nnamdi Kanu silẹ.

IPOB sọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Emma Powerful fi sita pe, ofin konle o gbele yoo gberasọ lọjọ Aje lati ago mẹfa owurọ si mẹfa irọle lojoojumọ, titi ti Kanu yoo fi kuro lahamọ ajọ DSS.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ IPOB ni ọna to tapa si ofin ni ijọba Naijiria fi gbe Kanu lati orilẹede Kenya wa si Naijiria.

''Gbogbo ọja, ile ẹkọ, ibudokọ, papakọ ofurufu ati nibi gbogbo kaakiri ilẹ Igbo lo gbọdọ wa ni titi pa lati aarọ di irọlẹ.

Àkọlé fídíò, Female Car AC Repairer: Abimbola Adedigba ní àfojúsùn òun ni láti ní abúlé mẹkáníkì láìpẹ́

A mọ ipa ti igbesẹ yii le ni lori ọrọ aje ṣugbọn a n ṣe eyi lati jẹ ki gbogbo agbaye mọ pe a wa lẹyin olori wa, Kanu gbọingbọin.

Gbogbo awọn ajeji to ni Biafra naa gbọdọ tẹle ofin yii niwọn igba ti wọn si nilẹ Igbo.

Ẹnikẹni ko gbọdọ jade ki ikọlu pẹlu awọn agbonfinro maa ba ṣẹlẹ, a ko fẹ ki awọn oṣiṣẹ eleto abo Naijiria dunkoko mọ ẹnikẹni,'' ẹgbẹ IPOB ṣalaye.

Ṣugbọn ninu ọrọ tiẹ, aburo Kanu gan an, Kanunta Kanu kede wi pe oun ti paṣẹ pe ki wọn si so ofin jokoo silẹ ẹ rọ na fun igba diẹ.

Ninu atẹjade ti Kanunta naa fi sita, o ṣalaye pe awọn so ifẹhonuhan konle o gbele ọhun rọ nitori awọn akẹkọọ ile ẹkọ girama to n ṣe idanwo NECO lọwọ.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

O ni awọn yoo maa kede ọjọ mii ti a o ṣe ifẹhonuhan naa laipẹ fun gbogbo eeyan.

Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ri, Chukwuemeka Ezeife ti bu ẹnu atẹ lu erongba IPOB lati fofin konle o gbele de awọn eeyan nilẹ Igbo.

Ezeife ni igbesẹ yii ko ni bimọ 're fun ilẹ Igbo lọna kanakn, bẹẹ ni ko si iranwọ kankan to le ti inu rẹ jade.

Ijọba ipinlẹ Enugu naa ti kilọ fawọn ọmọ ẹgbẹ IPOB pe ẹnikẹni to ba da rogbodiyan silẹ rugi oyin.

Ijọba rọ awọn araalu lati lọ si ibi iṣẹ oojọ wọn lai bẹru nitori eto abo to peye yoo wa fun gbogbo eeyan.