Mide Martins: Ohun tó bá wu oníkálukú kó sọ, mò ń gbìyànjú lórí ọ̀pọ̀ bùkátà ìwájú mi

Aworan Mide ati iya rẹ Funmi

Oríṣun àwòrán, Mydemartins

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba, Mide Martins ti fesi si ọrọ ti akẹgbẹ rẹ ninu isẹ tiata, to tun jẹ ọrẹ mama rẹ, Ashabi Olorisha sọ pe ko tun iboji mama rẹ, Funmi Martins tabi tọju aburo rẹ, Damilare.

Ọrọ Damilare aburo rẹ lo kọkọ lu ori ayelujara pa tẹlẹ eyi ti ọpọ eeyan da ẹnu bo Mide pe ko tọju rẹ, lẹyin ti mama wọn ti ku tan.

Awọn ẹbi ṣepade pọ lati yanju ọrọ naa ni itubi inubi nigba naa.

Ṣugbọn laipẹ yii oṣere tiata kan, Ashabi Olorisha to fi ilẹ Amẹrika se ibujoko sọrọ pe Mide ko ṣe ohun kan si oju orori mama rẹ, ẹni to ti ku fun ogun ọdun bayii.

Bakan naa ni wọn ni Ashabi tun sọ pe Mide fi gbogbo ẹbi silẹ lai bikita, to si n palẹmọ lati se ariya alarinrin fun iranti ogun ọdun ti mama rẹ jade laye.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap

Ṣugbọn Mide fesi ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin City People pe, oun mọ ohun ti oun n ṣe, ati pe oun ko le maa sọ ohun ti oun n ṣe fawọn eeyan lori ayelujara.

''Mi o le pa ara mi, mo mọ ohun ti mo ti gbe ṣe fun Damilare ti wọn sọ pe mi o bikita nipa rẹ yii.

Ohun to ba wu onikaluku ni ki wọn maa sọ, mo n gbiyanju agbara mi.

Eeyan ni emi naa, kii ṣe wi pe mo ni gbogbo nkan tan, ṣugbọn mo n gbiyanju pẹlu diẹ ti mo ni.

Mo si ni baba laye, ko si ẹni to beere pe bawo lo ṣe n jẹun, mo tun ni aburo mii to jẹ ọkunrin yatọ si Damilare.

Emi naa si ni awọn ọmọ temi naa. Bukaata pọ fun mi lọtun losi, amọ awọn eeyan kan ṣa wa lati bu ẹnu atẹ lu mi.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Nibo ni mo ti fẹ rowo lati pe Alhaji Wasiu Ayinde, KWAM 1 lati wa ṣere fun iranti ogun ọdun iku mama mi pẹlu bukaata to wa nilẹ fun mi yii?

Ọdọọdun ni mo maa n ṣe iranti mama ṣugbọn n ki i pariwo nipa rẹ."

Bakan naa ni Mide Martins salaye siwaju si pe oun maa n ṣe eto adura lọdọọdun fun iya oun, oun ṣi tun maa n ṣe iranwọ fawọn alaini lati ṣe iranti mama oun, ṣugbọn oun ko ki n gbe si ori ayelujara.

O ni ki onikaluku fi oun silẹ, ki wọn si jẹ ki Ọlọrun da oun lẹjọ bo ba jẹ ọmọ buruku ni oun tabi ọmọ daadaa.

Gbajumọ osere tiata naa ni oun ko ni lọ ya owo lati ṣe iranti ogun ọdun iku mama oun, bo ba ṣe wu oun ni oun maa ṣe e.

Mide Martins tẹsiwaju pe "Mo ti fa gbogbo eeyan to n sọ pe mi o tọju Damilare le Ọlọrun lọwọ, ko baa jẹ Ashabi Olorisha tabi aburo mama mi.

Ọlọrun nikan lo le dajọ fun gbogbo wa, iwọfa lẹnu, ohun to ba wu ẹlẹnu lo le fi ẹnu rẹ sọ.

Ẹ fi mi silẹ, ẹ jẹ ki Ọlọrun ati mama mi ṣe idajọ mi.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

Mi kii ṣe ẹnikan to maa n fi ọrọ ẹbi si ori ayelujara fawọn eeyan lati ri.

Bo ya iyẹn lo jẹ ki wọn maa sọ pe mi o ṣe eleyii, mi o ṣe tọhun.

Ṣugbọn iru ẹda ti Eleduwa da mi niyẹn, ko da mi lati maa saba fi ọrọ awọn ọmọ ti mo bi gan an sori ayelujara.

Mo fẹ ri Ashabi Olorisha fun ra mi lati beere idi ti o fi n sọ oriṣiiriṣii nipa mi gan an.

Bakan naa lo ṣe video pe mo n fẹ Sir Shina Peters, nigba ti mama mi mọ, lo jẹ ki mama mi ku.

Mo fẹ bi i leere nibi ti o ti n ri awọn iroyin to n sọ yii gan an.

O wu mi lati beere lọwọ rẹ idi to fi fẹ ba mi lorukọ jẹ, ti o fi n sọ oriṣiriṣii nipa mi,'' Mide lo ṣalaye bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rs bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf