COP 24: àwọn olórí orílẹ̀-èdè ṣe ìpàdé ọ̀nà àbáyọ

Oríṣun àwòrán, AFP/getty
Àwọn onimọ nipa ayipada ojú ọjọ́ forikori lori ọna abayọ ati Ìgbẹ́sẹ̀ tuntun to fẹ́ ba ètò inú àyípadà ojú-ọjọ́.
Orilé-ede Poland ni gbogbo awọn eekan lori ipade nipa ayipada oju ọjọ ti pade ki wọn le fẹnuko lori adehun Paris Climate Change 2020.
Gbogbo àwọn to forikori naa gba pe awọn ofin tuntun ti wọn fẹnuko le wọnyii ni yoo mu ẹdinku ba awọn ewu to n de ba igbesẹ ayipada oju ọjọ ni agbaye.

Oríṣun àwòrán, @Jasper junen
Koko to wa ninu adehun Paris naa ni pe ki onikaluku orilẹ-ede kọọkan sa ipa rẹ ki ooru ma mu jù lagbaye ati pe ki koowa maa ṣe nkan to maa mu ooru dinku lagbaye si iwọn meji.
Awọn onimọ kikun nipa oju ọjọ ni ti a ko ba gbe igbésé akin yii, ọpọlọpọ nkan lo maa bajẹ paapaa nilẹ Adulawọ.
Wọn ni ọgbẹlẹ maa wa ni eyi to maa pada bi ìyàn ati ìṣẹ́ lawujọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Mohammadu Buhari ti Naijiria naa wa lara awọn to pesẹ sibi iṣide apero naa. O ni Naijiria ti gbaradi lati rii pe wọn mu ipinnu wọn ṣe lori adehun ti Paris 2020 ọhun.
Bakan naa ni Buhari parọwa fawọn orilẹ-ede to ku lati rii pe wọn mu ofin naa ṣe laarin ọdun diẹ to ku ninu gbendeke naa.
O ni Naijiria ti n sa ipa rẹ lati mu ofin naa ṣe nipa pipese nkan to maa jẹ ki wọn muu ṣẹ lasiko nitori iṣoro ayipada oju ọjọ ni Naijiria ti ri pé o wa lara nkan to n fa ija laarin awọn darandaran ati agbẹ ni ariwa Naijiria .















