US election 2020: Bi kò tilẹ̀ wọlé, ẹ wo ayípadà tí Ààrẹ Trump mú bá awọn orilẹede ní àgbáyé

Aarẹ orilẹede Amerika kii ṣe aarẹ ilẹ rẹ nikan, amọ awọn orilẹede lagbaye ma n rii gẹgẹ bi adari ni agbaye.
Ohunkohun ti aarẹ ilẹ Amerika ba ṣe, gbogbo agbaye ni yoo mọ ọ ni ara.
Bakan naa ni aarẹ orilẹede Amerika, Donald Trump ko da yatọ ninu awọn aarẹ wọn yii.
Nitori naa ẹ jẹ ki a wo awọn ohun ti aarẹ Trump ṣe to yatọ si awọn aarẹ to ku, to si kan awọn eniyan kaakiri lagbaye.
Bawo ni awọn eniyan ṣe ri aarẹ Trump lagbaye?
Ni ọpọlọpọ Igba ni aarẹ Trump ti ma n kede pe orilẹede Amerika lo lagbara julọ lagbaye,
Amọ iwadii ti fihan wi pe ọrọ ko ri bẹẹ mọ labẹ akoso aarẹ Donald Trump.

Ni awọn orilẹede ni Ilẹ Yuroopu, iwadii fihan pe awọn eniyan ko ri ilẹ Amerika bi ti tẹlẹ mọ, fun igba akọkọ ni ogun ọdun.
Ni Ile Gẹẹsi, ida eniyan 41 lo gba ti Trump, ida 31 ni Ilẹ Faranse ati ida 26 lorilẹede Germany.
Se Aarẹ Trump ni igbagbo ninu ayipada oju ọjọ (Climate Change)?
Ko si ẹni to le sọ pato ipa ti aarẹ Trump kọ si ayipada oju ọjọ.
Igba miran o ti sọ wi pe ko si ohun to n jẹ ayipada oju ọjọ.
Nigba miran si ni yii, aarẹ Trump ti sọ wi pe oju ọjọ ṣe pataki si oun.
Amọ, aarẹ Trump kọ lati buwọlu Paris Agreement to ni ki awọn eniyan ma lo ohun ti yoo ba oju ọjọ jẹ.
Aarẹ Trump ni Paris Agreement yoo gba iṣẹ lọwọ ọpọlọpọ awọn ọmọ ilẹ Amerika.
Aarẹ Trump ti ibode pẹlu awọn orilẹede miran
Lẹyin ọsẹ kan ti aarẹ Donald Trump gori oye ni o gbe ofin kalẹ to tako orilẹede meje to jẹ ti awọn ẹlẹsin Musulumi.
Nibayii, orilẹede mẹtala ni aarẹ Trump ti fi ofin to lagbara de bayii nipa wiwa si orilẹede Amerika.
Bakan naa ni aarẹ Trump kọ ibode ti ko ni faaye gba awọn ara orilẹede Mexico lati ma a wọ ilẹ Amerika lati ibode to so awọn mejeeji pọ.
Iroyin Ofege lasiko aarẹ Donald Trump
Laiko aarẹ Donald Trump ni iroyin ofege peleke julọ lagbaye.
Bi aarẹ Trump ṣe n fẹsun kan awọn ileeṣẹ iroyin nilẹ Amẹrika wi pe awọn lo wa nidi iroyin ofege,
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bakan naa ni awọn ileeṣẹ iroyin naa n kede pe awọn iroyin ti ko fẹsẹ mulẹ ni aarẹ Trump ma n kọ ibi ara si.
Ikọ ọmọogun Amerika ni awọn orilẹede Gbungun lagbaye
Ni Oṣu Keji, ọdun 2019 ni Aarẹ Trump sọ wi pe oun yoo pe gbogbo awọn ọmogun ilẹ naa to wa lorilẹede Syria nitori pe ogun ti wọn n ja naa ko nidi mọ.
Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Trump ni orilẹede to ba ni agbara lagbaye kii ja ogun ti ko nidi.

Nibayii, aarẹ Trump ti ko lara awọn ikọ ọmọogun orilẹede Amerika kuro ni Afghanistan, Iraq ati Syria.
Ija laarin Aarẹ Trump ati orilẹede China, to fi mọ ọrọ aje
Aarẹ Trump lati igba to ti gori oye ni o ti wọ iya ija pẹlu orilẹede China nipa ọrọ aje.
Aarẹ Trump ma n sọ ni ọpọ igba pe orilẹede China n gba awọn ileeṣẹ to jẹ ti ti wọn mọ wọn lọwọ.
Nitori naa ni orilẹede China ati Amerika ṣe gbe owo ori to lagbara le ori ọja to n wọ orilẹede mejeji lati ọdọ ara wọn.
Ogun to fẹrẹ bẹ silẹ laarin orilẹede Iran ati Amerika
Orilẹede Amẹrika ati Iran ti wọ iya ija lati ọdun 1979, lẹyin ti ijọba ti Amerika ṣe agbatẹru fun ni Iran forisanpọn nigba ti wọn gba ijọba lọwọ rẹ.
Ọmọ orilẹede Amerika mejilelaadọta ni Iran jigbe nigba naa ninu ileeṣẹ ijọba orilẹede Amerika to wa ni Iran.
Ija naa tẹsiwaju ni ọdun 2018 nigba ti aarẹ Trump fopin si adehun pẹlu ilẹ Iran lori ohun ija Nuclear, ti wọn si fofin de wọn.

Oríṣun àwòrán, AFP
Orilẹede Iran kọ lati gbọ ọrọ si Trump lẹnu, eleyii to mu ki ọrọ aje wọn dẹnukọlẹ.
Bakan naa ni aarẹ Trump tun ṣekupa ọgagun to lagbara julọ lorilẹede Iran, Qasem Suleimani to n saaju awọn ogun to n ṣẹlẹ ni orilẹede gbungun lagbaye.
Amọ, igbiyanju orilẹede Iran lati gba ẹsan lara orilẹede Amẹrika jasi iku eniyan 176, lẹyin ti ikọ ọmọogun ilẹ Iran ja ọkọ ofurufu ti wọn ro wi pe ti ikọ ogun jabọ, lai mọ pe awọn araalu lo wa ninu ọkọ ofurufu naa.












