Gender discrimination: Ó pakasọ! Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan fi kọ ìyàwó rẹ̀ tó bí ìbẹta sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, others
Iroyin eleyi ṣeni ni Kayeefi pẹlu bi a ṣe gbọ pe arakunrin agbẹ kan ti ṣe kọ iyawo rẹ́ silẹ nitori pe o bi ọmọ mẹta.
Ọmọ mẹta nikan kọ, o ni nitori pe wọn jẹ ọmọ obinrin.
Iṣẹlẹ yi waye ni agbegbe ijọba ibilẹ Chikun ni ipinlẹ Kaduna.
- Ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá mú ààrẹ látí ìhà àríwá Niajiria ní ìdìbò ọdún 2023 yóò pòfo- Gomina Akeredolu
- Eré ìfẹ́ di eré ẹkún! Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò tí wọ́n n bá ara wọn sùn nínú adágún odò
- Yorùbá ẹ fura o! Ìwẹ̀fá ìjọba àpapọ̀ gbáà ní Fani-Kayode tó ń díbọ́n bí ọ̀kan lára wa
- Ojú ọjọ́ gbìgbóná jànyinjànyin ti kọjá kèrémí káàkiri àgbáyé
- Ọkùnrin kan dèrò àtìmọ́lé ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ewúrẹ́
Immamu agba kan ni Kaduna Tanimu Musa lo fi ọrọ yi ṣakawe lasiko apero kan to da lori iwa ipa si awọn obinrin ni ipinlẹ Kaduna.
Immamu naa sọ pe ẹsin Islammu ati Kristẹni to jẹ ẹsin meji to gbajumọ ni Naijiria ko fi aaye gba ka maa hu iwa ipa sawọn obinrin.
Bẹẹ lo jẹri si pe ẹsẹ ti arabinrin yi ṣe niwaju ọkọ rẹ ni pe o bi ọmọ obinrin mẹta dipo ọmọ ọkunrin to nifẹ si nitori o ri ọkunrin gẹgẹ bi arole.
Imaamu Tanimu sọ pe o ṣeni laanu pe iru ipenija idẹyẹsi si awọn obinrin bayi si n tẹsiwaju lawujọ ati pe asiko to lati tẹra mọ idanilẹkọ awọn eeyan.
O wa gba awọn obi ni iyanju ki wọn ran awọn ọmọ wọn lọ si ile ẹkọ nitori ẹkọ jẹ ogun wọn ti yoo ṣatọna bi wọn yoo ṣe da duro lọjọ waju.
- Kí ẹnikẹ́ni má gbé ìyá mi síta mọ́, mí o ní agbẹnusọ kankan mọ́- Sunday Igboho
- Judasi ìran Oduduwa ni Femi Fani-Kayode pẹ̀lú bó ṣe darapọ̀ mọ́ APC- Sheikh Gumi
- Ẹ máa gbàá nìṣò, àwa Gómìnà ìhà Gúúsù f'ọwọ́ sí kí ìpínlẹ̀ má gba VAT
- Agbẹnusọ àjọ EFCC Wilson Uwujaren ti ṣàlàyé nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gá àjọ náà lósàn ọjọ́bọ
- Ó pakasọ! Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan fi kọ ìyàwó rẹ̀ tó bí ìbẹta sílẹ̀















