Femi Fani-Kayode's defection: Ẹgbẹ́ OPC s'òkò ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Femi

Fani-Kayode ati Iba Gani Adams

Oríṣun àwòrán, OPC

Ẹgbẹ Oodua Peoples Congress ti fi ẹsun kan Minisita irina ofurufu tẹlẹri, Femi Fani-Kayode pe ijọba gan ni o n ṣiṣẹ fun lasiko to n ṣe pẹlu awọn ajafẹtọ Yoruba Nation.

Eyi jẹ jade ninu atẹjade ẹgb naa eyi ti akọwe ẹgbẹ Yinka Oguntimehin fọwọ si ninu eyi ti wọn ti sọ fun awọn araalu pe ki wọn tun maa reti awọn ọdalẹ mii pe awọn mii bi Fani-Kayode o le ṣai ma tun jade lati ẹkun Guusu-Iwọ Oorun.

Wọn ṣapejuwe Fani-Kayode gẹgẹ "aṣiṣẹ f'oṣelu ti ko ni afojusun kankan" ati pe ko ni "ootọ inu kọbọ".

Ẹgbẹ naa ni ko ya awọn lẹnu rara pe Femi lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC toripe oun atawọn eekan ẹgbẹ naa ti n fara yira kaakiri orilẹede.

Ṣaaju ko to lọ darapọ mọ APC, FFK jẹ ọkan lara awọn oloṣelu to n fọn rere ajijafẹtọ Yoruba Nation, Sunday Adeyemo ti ọpọ maa n pe ni Igboho.

Bakan naa, Igboho ti sọọ ri ninu atẹ́jade rẹ ti agbẹnusọ rẹ tẹlẹ, Olayomi Koiki fi sita ninu oṣu kẹta ọdun 2021 pe "Alẹnulọrọ pataki ni Oloye Femi Fani-Kayode to n ti awọn lẹyin ninu ija fun orilẹede Yoruba Nation. A ni gbogbo idaniloju ninu rẹ (Fani-Kayode)".

Ẹgbẹ OPC wa rọ awọn ọmọ Yoruba pe ki wọn ma roo pe ijanikulẹ ni ohun ti Minisita tẹlẹri ṣe toripe "bii ọga lawọn oloṣelu Naijiria ti wọn maa n pa awọ da ni gbogbo igba".