CBN: Banki àpapọ̀ Nàìjíría ti pasẹ titi ojú òpó Aboki FX pa

Banki àpapọ̀ Nàìjíría ti pasẹ titi ojú òpó Aboki FX pa

Banki apapọ Naijiria ti ni oun yoo ti Aboki FX to maa n sọ bi awọn to n ṣe pasiparọ owo ilẹ okere (Bereau de change) ati àwọn ara ilú yoo se ma ra owo ilẹ okere, dọla ati oọun.

Ori atagba Aboki FX yii ni banki ọhun sọ bayii pe ko ba ofin mu ati pe iṣẹ ọdaran ni wọn n se nibẹ.

Gomina banki apapọ naa, Godwin Emefiele to sọ ọrọ yii lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade igbimọ ofin owo u=ile okere to waye ni ilu Abuja lonii.

Bakan naa lo fi kun un pe awọn yoo fi ẹni to ni atagba naa, Olusegun Oniwinde jofin .

O ni "mo ti sọ fun awọn akọsẹmọsẹ wa lati koju mọoju opo iroyin rẹ , ki o si mọ daju pe a o mu oun pẹlu nitori pe a ko le gba ki iru nkan bayii ma tẹsiwaju"

Gẹgẹ bi Emefiele ṣe sọ awọn ko si ẹni to da "burudi ṣenji" kankan mọ yatọ si awọn tó n ṣe katakara ati awọn to n ta ọja si oke okun.

Lasiko ti a nkọ iroyin yii lọwọ, Burudi ṣenji ni ayipada dọla kan jẹ ẹdẹgbẹta ati aadọrin naira loju opo Aboki FX.

Oju opo naa ṣalaye pe awọn burudi ṣenji n ra dọla ni ẹẹdẹgbẹta naira le ọgọta ti wọn si n taa fun ara ilu ni ẹẹdẹgbẹta naira le aadọrin.