Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò tí wọ́n n bá ara wọn sùn nínú adágún odò

Awọn ololufẹ meji lori ibusun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ere ifẹ di ere ẹkun fun ọkunrin ati obinrin kan to jẹ ololufẹ , lasiko ti wọn n ni ibalopọ ninu adagun odo.

Ololufẹ meji ọhun ni iroyin sọ pe wọn n wẹ ninu odo Bosomtwi, ni ẹkun Ashanti, lorilẹ-ede Ghana, ti wọn si tun pinnu lati gbadun ara wọn si i, nipa ibalopọ ninu odo naa.

Nibi ti wọn ti n gbadun ara wọn lọwọ, ni wọn ti lẹpọ.

Ere ni, awada ni. Afi bi ẹni pe 'oluwẹri to wa ninu odo naa n binu si wọn pe wọn ri oun fin pẹlu ibalopọ wọn'.

Gbogbo igbiyanju wọn lati tuka lo ja si ofo, eyi to mu ki wọn o bẹrẹ si ni pariwo ẹ gba wa o, ẹ gba wa o.

Ariwo wọn ni iroyin sọ pe o de eti awọn eeyan to wa ni tosi, ti awọn naa wa a wẹ, ti wọn fi sare si wọn.

Ninu fidio kan to wa lori ayelujara ni awọn eero iworan to duro ti wọn ti n gbiyanju lati tu wọn ka.

Àkọlé fídíò, Ayo Ewebiyi Mama Oriki: Ọwọ́ Òbí, Ìjọba àti àwọn Ọba ni ìdágbàsókè Yorùbá wà lásìkò yìí

Ṣugbọn ofo ni igbiyanju wọn.

Bẹẹ naa si ni ololufẹ meji ọhun pariwo ẹ gba wa pẹlu omije loju, eyi to fihan pe wọn n jẹ irora.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

"Ao ni i ṣe bẹẹ mọ".

Ti wọn si n tọrọ idariji lọwọ awọn oriṣa, nitori irora to ba wọn.

Àkọlé fídíò, Jẹ́ ká lọ sílu mi: Kò sí ìtàn Ibadan láìsí Efunsetan, Òkè méje, Bower's Tower àtàwọn ǹkan