2023 Presidency zoning: Shekarau ni káwọn gómìnà Yorùbá yé pariwo ní gbangba nípa ẹni ti ààrẹ kàn

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gomina Ìpínlẹ̀ Kano tẹ́lẹ̀, Ibrahim Shekarau ti fohùn ránṣẹ́ si awọn gomina Ìpínlẹ̀ mẹtadinlogun tí iha Guusu Naijiria.
O ni pe ki wọn ye ko ẹgbẹ́ jọ láti sọ̀rọ̀ ibẹru lori pe wọn fẹ gba ipo Ààrẹ lọdun 2023.
Shekarau to n ṣojú aarin gbungbun Ìpínlẹ̀ Kano nílé igbimọ aṣofin agba lo sọ èyí lori eto orí amohunmaworan Channels kan.
Nibẹ lo ti ni lẹyin Ààrẹ Muhammadu Buhari, ó yẹ ki Ààrẹ to n bọ lọ́dún 2023 yẹ ko wa lati ẹkùn Guusu lati le jẹ ki jijẹ anfani náà kaari gbogbo ọmọ Naijiria.
- Ṣé Facebook, Instagram, WhatsApp tiyín náà ti dẹnukọlẹ̀? Ìdí tó fi ṣẹ́lẹ̀ rèé
- Àwọn dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sùgbọ́n...
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
- Kí ní ọ̀rọ̀ mí tí ẹ mú bẹnu lórí onimọ̀ àyẹ̀wò 'Forensic' tí ilé ẹjọ́ pè kó wá jẹ́rìí?- Yomi Fabiyi
- Ta ni Whitemoney tó gba N90 miliọnu nínú ìdíje BBNaija 2021?
Ó tún fi kun un pe ṣe ni ó yẹ ki ẹgbẹ́ òṣèlú APC pin tíkẹẹti ipò Ààrẹ wọn si ọdọ eeyan to dangajia to láti ṣeé ni ẹkùn Guusu fun idibo to n bọ lọ́nà eyi ti ko ju oṣù mejidinlogun lọ mọ bayii.
Ẹwẹ, Shekarau sọ oko ọrọ si awọn gomina Guusu pe wọn ń gbimọ pọ láti ja fun ipò Ààrẹ lọ́dún 2023.
Gẹ́gẹ́ bí idibo ọdún 2023 ṣe ń sunmọ, orisirisi akitiyan lọ ti n lọ nínú òṣèlú.
Àwọn gomina mẹtadinlogun ìhà Guusu ti pe ipade nígbà méjì ti wọn si n pe fún kí agbára isejoba bọ si apa ọdọ wọn.
Bákan naa ni awọn gomina iha Ariwa mokandinlogun naa ti ṣepàdé lose to kọja.
Nibi ti wọn si tako igbese ati ìpinnu awọn akẹgbẹ́ wọn ní Guusu tí wọn ni ẹnikẹni ti ibo rẹ bá pọ ju náà ni yoo di Ààrẹ nínú ètò idibo to n bọ.
Lórí ètò náà, Shekarau ni ó ṣe ni laanu pé ọrọ a ń to ó, a ó to o ti wa sọ ìjọba awarawa di kíkóra jọ ni ẹlẹkun n jẹkun.
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
Torí èyí, Shekarau bu ẹnu atẹ lu oniruuru ipade àwọn gomina Guusu to sì ni kí wọn jawọ ninu kíkọ awọn ẹgbẹ́ mii lórílẹ̀èdè lati ṣe iru nkan táwọn naa n ṣe.
Ó ni ó yẹ ki wọn ba ara wọn sọ̀rọ̀ laarin ẹgbẹ́ ju ki wọn maa pariwo ni gbangba.
Òun ni tìrẹ ni bo tilẹ̀ jẹ́ pé òun gba pe èèyàn to dangajia lọ yẹ kó jawe olubori, òun sì gba pe ki wọn jẹ ko kari ni Naijiria
"àmọ́ ibi tí mo kan ti lodi si awọn gomina iha Guusu ni kikora jọ láti máa sọ pé dandan awọn lo kan.
Mo lérò pé ọrọ àárín òṣèlú lo yẹ ki eleyii jẹ."





















