Facebook, Instagram, WhatsApp ti dẹnukọlẹ̀? Ìdí tó fi ṣẹ́lẹ̀ rèé

Aworan Facebook, WhatsApp ati Instagram

Oríṣun àwòrán, Google

Gbogbo iṣẹ ti oju opo Facebook, WhatsApp ati Instagram n ṣe lo ti ṣaadede dawọ duro lọjọ Aje ọjọ kẹrin, oṣu Kẹwaa.

Ohun lo si ti ko ọpọlọpọ to wa lawọn oju opo naa si idamu ti wọn o le rii lo tabi ba ara wọn sọrọ jakejado agbaye.

Awọn itakun ayelujara yii ni iroyin ti kọkọ jade pe wọn o ṣiṣẹ ni nkan bii ago mẹrin kọja iṣẹju marundinlọgbọn irọlẹ ago orilẹede Naijria lọjọ Aje.

Ṣe ni awọn to n lọ si oju opo naa n ri esi "ko lọ", "ko lọ" eyi ti oloyinbo n pe ni "error message".

Ṣe ni awọn oni nkan gan bẹrẹ si ni fi ọrọ si oju opo Twitter. @WhatsApp fi ọrọ sita pe, "a mọ pe awọn kan n la iṣoro kọja lọwọ lọwọ pẹlu lilo WatsApp wọn.

A n ṣiṣẹ lorii rẹ lati mu ohun gbogbo pada bọ sipo a o si fi ọrọ sita lori ibi ti a baa de laipẹ. Ẹ ṣeun fun suuru yin".

Esi awọn eeyan lori Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ṣe ni awọn eeyan ti ko kọrẹ rara ti bẹrẹ si ni fi iriri wọn soju opo Twitter ati oriṣiriṣi aworan oun to n ṣẹlẹ.

Facebook ati Instagram

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni @Facebook naa gba tẹle e ti wọn kọ ọrọ soju opo Twitter pe, "a mọ pe awọn kan n la iṣoro kọja lọwọ lọwọ pẹlu lilo awọn aapu wa ati iṣẹ ti wọn n ṣe.

A n ṣiṣẹ lorii rẹ lati mu ohun gbogbo pada bọ sipo a si tọrọ aforiji fun inira ti a ba ti jẹ ki ẹ la kọja.

Esi awọn eeyan lori Twitter

Oríṣun àwòrán, Google

@InstagramComms naa o gbẹyin, "Instagrama ti awọn ọrẹ rẹ n la iṣoro diẹ kọja lati lo awọn oju opo wa.

A n ṣiṣẹ lati mu ohun gbogbo pada si bo ṣe yẹ. Ẹ ba wa baa ṣe ri, o maa to ṣiṣẹ".

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

Oju opo Facebook eyi to ni to eeyan biliọnu mẹta to n loo kaakiri agbaye maa dẹnukọlẹ lẹẹkọkan.

Ninu oṣu Kẹta ọdun 2021 ati oṣu Karun ọdn 2020 eyi to si maa n wu oniruuru esi jade lori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Pabanbari ibẹ tun wa ni pe lati igba ti ijọba apapọ Naijiria ti gbẹsẹ le oju opo Twitter latinu oṣu Kẹfa ọdun 2021 lawọn ọmọ Naijiria ti darale oju opo Facebook ti awọn mii ṣi n lo Twitter nipa lilo ọna oju itakun Virtual Private Networks.

Esi awọn eeyan lori Twitter

Oríṣun àwòrán, Twitter

Eeyan bii miliọnu mẹtalelọgbọn ni Naijiria lo n lo oju opo ayelujara deede, WhatsApp jẹ oju opo ibaraẹnisọrọ ti wọn n lo ju lorilẹede naa to si ni to eeyan to le ni miliọnu aadọrun to n loo gẹgẹ bi akọsilẹ.

Nkan bii ida 61.4 awọn ọmọ Naijiria lori ayelujara lo n lo Twitter, 86.2 n lo Facebook, 81.6 per lo n lo YouTube, 73.1 lo n lo Instagram, nigba ti 67.2 n lo Facebook Messenger.

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan