Umbilical cord: Ẹ dẹ́kun fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ- Dókítà

Oríṣun àwòrán, Science Photo Library
Dokita kan ti kilọ fun awọn obinrin lati dẹkun ati maa lo ọṣẹ ifọyin, oru to n jade lati ara atupa ati omi gbigbona fun itọju okun to so olubi pọ mọ iya ọmọ.
Nigba to n sọrọ pẹlu akọroyin ileeṣẹ iroyin abẹle Punch, dokita naa tun kilọ fun awọn obinrin lati ṣọra fun lilo igbẹ maalu fun itọju okun yii kan naa.
O ni nitori o le yọri si aisan, eyii to le yọri si iku aitọjọ irufẹ ọmọ bẹẹ.
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ibi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé? Kínni pàtàkì ibi ọmọ?
- Àwọn dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sùgbọ́n...
- Àrà kengé! Alábòyun ṣe iṣẹ́ abẹ pẹ̀lú abẹfẹ́lẹ́, ó gbé ọmọ jádé nínú ara a rẹ̀
- Ọmọ ìkókó yìí bẹ̀rẹ̀ ǹkan oṣù l'ọ́mọ oṣù mẹ́rin, ó tún kojú àìsàn jẹjẹrẹ ilé ọmọ
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
Dokita ọhun to jẹ adari ẹka kan nile iwosan awọn ̣ọmọ wẹwẹ Massey Street Children Hospital niluu EKo, Olanike Olutekunbi sọ pe itọju okun to so olubi pọ mọ iya ọmọ bẹrẹ lati igba ti wọn ṣẹṣẹ bi ọmọ naa.
O ni lẹyin ti wọn ba bi ọmọ ọhun ni wọn maa ge okun naa, wọn si gbọdọ ṣe itọju àpá ibi ti wọn ti ge lori idodo ki kokoro aifojuri ma baa gba ibẹ wọle si agọ ara ọmọ jojolo.
Olutekunbi sọ pe "Okun to so olubi pọ mọ iya ọmọ naa le wú, o si le maa pọn, ati pe kokoro aifojuri le gba ibẹ wọle si agọ ara inu ọmọ tuntun lati inu ẹjẹ."
"Irufẹ ọmọ bẹẹ le ni aisan 'tetanus' paapaa ti iya rẹ ko ba tii gba abẹrẹ ajẹsara rẹ ṣaaju."
Dokita naa ṣalaye pe inu ewu nla ni irufẹ ọmọ bẹẹ yoo wa ti iya rẹ ko ba kiyesara.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, o ṣe pataki ki okun to so olubi pọ mọ iya ọmọ wa ni imọtọ fun anfani ọmọ ti wọn ṣẹṣẹ bi.
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
- "Who wants to be a Milionaire'' tí pada sí orí afẹ́fẹ́! ẹyin olólùfẹ́ rẹ̀, ẹ kú oríire!
- Iná ìjọba gbé àwọn olújọ́sìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì lásìkò ìsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi, ẹ̀mí mẹ́rìn lọ si!
- Òjò alágbára rọ̀ ní Ikare-Akoko, ilé àádọ́jọ bá a lọ, èèyàn kan tún kú
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ẹ̀yà kan wà ní Africa, tó jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nípa sí sọ nkan ọmọkùnrin di nla ní ìlànà ìbílẹ̀?
O ni "Lara awọn nnkan ti awọn eeyan maa n lo lati ṣetọju okun to so olubi pọ mọ iya ọmọ wọn ni igbẹ maalu, atupa, omi gbigbona, agbo, atawọn nnkan mii to lewu pupọ fun ọmọ jojolo."
Lasiko to n da si ọrọ naa, dokita mii, Ayodele Renner sọ pe okun yii lo so ọmọ naa pọ mọ ile ọmọ ninu iya rẹ.
Ọmọ naa maa n gba afẹfẹ oxygen lati inu olubi ati okun yii, okun naa lo si jẹ ki ọmọ ọhun wa laaye ninu iya rẹ.
O ni ọmọ naa le fara kasa arun ti wọn ba fi ọṣẹ ifọyin ṣe itọju okun to so pọ mọ iya rẹ, nitori naa ki awọn iyalọmọ dẹkun ati maa ṣe bẹẹ.





















