2023 Presidency: Kokoko lara mí le, Mo kàn ń gbà ìtọ́jú ni- Tinubu ṣàlàyé ìdí tó sì fi wà ní London

Oríṣun àwòrán, Tinubu
Aṣíwájú ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, Bola Ahmed Tinubu sọ̀rọ̀ sókè lẹ́yìn bi ọjọ́ mẹ́ta tí oníruuru fótò bí àwọn olóṣelú ṣe ń se àbẹ̀wò sí ní ilú London lati lọ kíi, tó fi mọ ààrẹ Nàìjíríà, Muhammadu Buhari.
Sùgbọ́n Asíwajú Ahmed sọ pé, kokoko ni ara òun lé, òun kan n gba itọjú lásán nilú London ni.
Tinubu fi ọ̀rọ̀ yìí dá àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asojú sòfin láti ìhà Arèwá tó ṣe àbẹ̀wò si ni ilú London lọ́jọ́ Eti lójú.
Gómínà ìpińlẹ̀ Eko nígbà kan rí, ti ó ti wà ni ilú London láti bi oṣù mẹ́ta sẹ́yìn, lẹ́yìn tí o lọ ṣe iṣẹ́ abẹ̀ orókún rẹ̀, ẹ̀wẹ̀, ó sàpèjúwe ìtójú náà bi èyí tí ó nira púpọ̀.
Tinubu sọ pé, "Ọlọ́rún àti àwọn ènìyàn bi ti yín yii lo jẹ ki ara mi le kokoko, mo kan gba ìtójú ni, sùgbọ́n ó nira gidi"
Lati ìgbà tí Tinubu tí lọ sí ilú London ni ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń bẹ̀ẹ́ wò níbẹ̀, láti orí ààrẹ Muhammadu Buhari, Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ asòfin, Femi Gbajabiamila, Gómìnà Abdullahi Ganduje ti ìpińlẹ̀ Kano, Dapo Abiodun, ti ìpínlẹ̀ Ogun.
Àwọn mííràn tún ni, Babajide Sanwo-Olu ti ìpińlẹ̀ Eko Rotimi Akeredolu (Ondo), àti Kayode Fayemi (Ekiti).
Pípẹ́ ti Tinubu pé ni ìlú London yìí tí mú kí ọ̀pọ̀ máá bu ẹnu àtẹ́ lùú pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ló yẹ kí ó dúró sí láti gba ìtójú.
Tó fi mọ́ Reno Omokri tó sọ pé, ti Tinubu bá di ààrẹ lọ́dún 2023, òun náà yóò máá lọ ilú òyìnbó bọ̀ láti lọ máá gbá òitọ́jú bi ti ààrẹ Buhari tó m fi owó ara ilú ló tójú ara rẹ̀ lókè òkun.
















