El-Zakzaky: Àwọn ọmọ Nàìjíría fẹ́ òfin Islam ju ìjọba awarawa lọ

Ibrahim El-zakzaky

Oríṣun àwòrán, other

Adari awọn ẹgbẹ Islam, Islamic Movement in Nigeria, Sheikh Ibraheem El-Zakzaky ti ni awọn ọmọ orilẹede fẹ idari ofin ẹsin Islam bi anfani rẹ ba wa fun wọn.

O ni awọn ọmọ Naijiria yoo nifẹ ati gba ilana idari awọn oyinbo alawọfunfun da shun eyi ti ko mu ilọsiwaju de ba wọn.

Ọmọwe ẹsin Islam yii to tun jẹ olori ẹgbẹ ajafẹtọ Shiite iyẹn ẹgb kan to gbagbọ ninu ifẹhonuhan lati ja fẹtọ n fi ẹsun kan ijọba pe wọn fi ẹtọ oun dun oun nipa bi wọn ṣe fofin de ko ma lọ si oke okun fun itọju ara rẹ lẹyin to jade ni atimọle.

Adari ẹgbẹ Shiite yii ti igbagbọ wa pe o ni ibaṣepọ pẹlu ijọba ilẹ Iran fi ọrọ yii lede lasiko eto ori amohunmaworan Press TV ti Iran kan ti wọn n fọrọ waa lẹnu wo eyi ti wọn ṣafihan rẹ ni ilu Kano laarin ọsẹ.

Ọjọ kejidinlogun oṣu keje ọdun 2021 ni El-Zakzaky gba itusilẹ lati igba ti wn ti juu sẹwọn ninu oṣu kejila ọdun 2015 fun ẹsun pe o n dari awọn ọmọlẹyin rẹ lati ṣe ikọlu si Ọga agba awọn ologun to ti di aṣoju orilẹede Naijiria si orilẹede Benin Republic bayii.

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

O gbagbọ pe titi di asiko yii, wọn ṣi n ko oun ni papamọra tori ijọba Naijiria ko fun oun laye lati rinrinajo lọ si oke okun pẹlu iyawo rẹ fun itọju.

El-Zakzaky ṣi aṣọ loju ọrọ pe ẹgbẹ Shiite kanlẹ n ja fun ilana iṣejọba ti yoo maa tẹle ẹsin Islam ko rọpo ijọba awarawa ni Naijiria.

"Mo nigbagbọ pe bi ifẹnuko gbogbo ọm orilẹede ba wa nipa idibo tabi lori awọn ọ̀rọ̀ kan ti wọn yoo si bi awọn eeyan leere pe iru ilana ijọba wo lẹ fẹ?

Ṣe eyi tẹẹ ba bẹrẹ lati ọjọ yii to jẹ tawọn oyinbo ni abi ilan Islam?

O da mi loju pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ eeyan ni yoo mu ilana Islam lati ṣejọba. Tori ijọba awọn eniyan ni yoo pada jẹ".

Ẹwẹ, o ni ijọba Naijiria n bẹru pe ẹgbẹ ajafẹtọ ẹsin Islam yoo fi ijijagbara fipa gbe ofin ati ilana iṣejọba ẹsin Islam kalẹ ni Naijiria gẹgẹ bo ṣe ṣlẹ ni Iran lọdun diẹ sẹyin to si ni wọn gba labẹlẹ pe ero awọn niyẹn.

Àkọlé fídíò, Nàìjíríà kàn wà ni, ẹ ò páàsì, ẹ ò féèlì, ẹ ò kúrò ní kíláàsì kan náà - Àwọn ọ̀dọ́