Padora Papers tú àṣírí àwọn olóṣèlú 336 tó ní iléeṣẹ́ àti dúkìá káàkiri àgbáyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko din ni oloṣelu mẹwaa ni Naijiria ti iwe Pandora pappers ti fi ẹsun jẹgudu-jẹra kan nigba ti awọn orilẹ-ede mẹjọ ni Afrika naa fara gba ninu atẹjade iwe naa.
Lapapọ, ọọdunrun ati mẹrindinlogoji oloṣelu ni iwe naa fi orukọ wọn lede ninu atẹjade kan ti ajọ awọn akọroyin kan to n ṣe iwadii finifini, International Consortium of Investigative Journalists, fi lede.
Pandora Papers yii jẹ iwe kan to tu aṣiri iye dukia to wa ni ikawọ awọn oloṣelu atawọn alẹnulọrọ kan lagbaye.
- Ṣé Facebook, Instagram, WhatsApp tiyín náà ti dẹnukọlẹ̀? Ìdí tó fi ṣẹ́lẹ̀ rèé
- Ẹ yé kóra jọ pọ̀ láti d'ẹ́rù b'olẹ̀ pé ọwọ́ Yorùbá ni Ààrẹ 2023 gbọ́dọ̀ bọ́ sí - Shekarau
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ
- Àwọn dókítà tí fagilé ìyanṣẹ́lódì ọlọ́jọ́ gbọọrọ, sùgbọ́n...
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba ẹ darapọ̀ mọ́ wa látí tako ìjọba Naijiria lórí àtìmọ́lé Nnamdi Kanu - IPOB
Awọn akọroyin bii ẹgbẹta (600) kaakiri agbaye lo korajọ lati yẹ awọn iwe bii miliọnu mejila lati awọn ile ifowopamọ si kaakiri agbaye wo ki wọn to fi abajade iwadii wọn lede.
Wọn ṣawari ibaṣepọ laarin awọn ileeṣẹ bii ẹgbẹrun kan atawọn oloṣelu ti wọn ni awọn lo ni awọn ileeṣẹ naa, lara awọn oloṣelu naa ni awọn olori orilẹ-ede wa.
Gẹgẹ bii atẹjade to wa ninu Padora Papers ọhun, awọn oloṣelu to lamilaaka marun un ni Côte d'Ivoire lo ko owo ilu pamọ nilẹ okeere.
Awọn oloṣelu mẹta lati Ghana ni orukọ wọn wa ninu iwe naa pẹlu.
Iwe ọhun tun fi orukọ oloṣelu meji-meji lede lati Chad, Kenya ati Congo Brazzaville nigba ti awọn oloṣelu mẹta lati Garbon wa nibẹ.
Oloṣelu mẹsan an lati orile¬̣-ede Angola lo wa nibẹ, nigba ti Zimbabwe ati South Africa ni meji-meji ti Mozambique si ni ẹyọ kan.
- Ìgbà méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ikọlu wáyé láwọn ọgbà ẹwọn Nàìjíríà
- Genevieve ṣàlàyé ànfààní tó wà nínú ìbásùn òwúrọ̀ kùtù fáwọn lọ́kọ láya
- Ẹ wo àwọn adarí ìjọ ní Naijiria tó tako abẹ́rẹ́ àjẹ́sára Covid-19 àti àwọn tó faramọ
- Wo ǹkan mẹ́ta tó n jẹ́ kí abẹ́ obìnrin má a rùn...
- Ọwọ́ sìkún ọlọ́pàá tẹ Bolanle afurasí adigunjalè làyájọ́ òmìnira Nàìjíríà
- Kí ní ọ̀rọ̀ mí tí ẹ mú bẹnu lórí onimọ̀ àyẹ̀wò 'Forensic' tí ilé ẹjọ́ pè kó wá jẹ́rìí?- Yomi Fabiyi
- Ta ni Whitemoney tó gba N90 miliọnu nínú ìdíje BBNaija 2021?

















