Ajá dóòlà ọmọ tuntun tí ìyá rẹ̀ bò mọ́lẹ̀ láàyè ni Thailand

Oríṣun àwòrán, khaosod
Ni Ariwa orilẹede Thailand ni Aja kan ti doola ọmọ tuntun jojolo kan lẹyin ti iya ọmọ naa to jẹ ọdọ bo o mọlẹ ni aaye.
Ọmọkunrin naa ni iya rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹẹdogun, bo mọlẹ ki awọn obi rẹ maa ba a mọ pe o loyun.
Ajá naa ti orukọ rẹ n jẹ Ping Pong lo n gbẹ ilẹ, to si n gbo ni ori papa kan nitosi abule Ban Nong Kham, nigba to ṣakiyesi ẹsẹ ọmọ naa to yọ sita.
Ariwo aja yii si lo mu ki olowo rẹ o ṣawari ohun to n mu u gbo, to si ri ẹsẹ̀ ọmọ tuntun naa.
Ni kiakia ni awọn ara abule sare gbe ọmọ naa lọ sileewosan, nibiti awọn dokita ti tọju rẹ, ti wọn si fidirẹmulẹ pe ilera rẹ ṣi wa ni pipe.

Oríṣun àwòrán, khaosod
Nibayi, awọn alaṣẹ ti fi ẹsun pipa ọmọ ti, ati igbiyanju lati ṣekupani kan iya ọmọ naa nile ẹjọ.
Panuwat Puttakam to jẹ ọlọpaa nileesẹ ọlọpaa Chum Phuang sọ fun iwe iroyin Bangkok Psot pe iya ọmọ naa ti wa ni abẹ amojuto awọn obi rẹ ati onimọ nipa ihuwasi ẹda.
O fikun un pe ọmọbinrin naa kabamọ iwa to hu. Awọn obi rẹ naa si ti pinnu lati tọju ọmọ tuntun ọhun.













