Ikeja Electric blackout: ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ bẹ̀rẹ̀ láti Oct 11 ní àwọn agbègbè kan ní ìpínlẹ̀ Eko kò ní gbádùn iná ọ̀ba

Ikeja Electric

Oríṣun àwòrán, Others

Ileeṣẹ apinnaka, Ikeja Electric PLC ti kede pe awọn agbegbe to wa ni abẹ iṣakoso awọn ko ni le e lo ina ọba fun ọṣẹ mẹjọ.

Ikeja Electric ni idi ti eleyii yoo fi waye ni lati ṣe atunṣe awọn ẹrọ agbenaka wọn, 132kv lines ti ileeṣẹ ijọba Transmission Company of Nigeria, TCN yoo ṣe atunṣe rẹ.

Adari ẹka ton risi atunṣe ina ọba, Olajide Kumapayi lo fi iroyin naa to awọn oniroyin leti ni agbegbe Ikeja.

Kupaniyi ni atunṣe ina ọba naa ti yoo bẹrẹ ni Ọjọ Kọkanla, Osu Kẹwaa ni wọn yoo ṣe lati mu ki awọn opo ina to n gbe ina ni agbara si fun igbayegbadun awọn eniyan.

O ni o ti le ni aadọta ọdun ti wọn ti ri awọn opo ina yii, eleyii to si ti jẹ ki agbara rẹ dinku ju ti atẹyinwa lọ.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

Ninu ọrọ rẹ, awọn agbegbe ti aisi ina ọba yii yoo jẹ inira fun ni agbegbe Oregun, Police Training College, Oba Akran, Oke Ira, Ogba, Magodo , Anifowoshe ati Omole Phase One.

Kumapayi ni saa keji re e ninu igbesẹ ati tun ina ọba naa ṣe lati opopona Iwọ oorun Ikeja si Ọta, to fi de Alimosho.

Others

Oríṣun àwòrán, Others

''Gbogbo awọn aluminium ti TCN fi ṣe awọn ẹrọ agbenaka naa ni wọn yoo tun ṣe si ti igbalode, ki awọn eniyan le jẹ anfaani ina ọba ju ti tẹlẹ lọ.''

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

''Ohun ti eleyii yoo fa ni aisi ina ọba laarin aago mẹjọ si aago mẹfa irọlẹ ni ojoojumọ fun ọṣẹ mẹjọ yii, nitori gbogbo ẹrọ ti ohun gbe ina lọ si awọn agbegbe yii ni wọn yoo pa ni awọn asiko yii.''

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

''Awọn ileeṣẹ to jẹ onibara wa ti eleyii yoo fa idiwọ fun ni Ikeja City Mall, Police College, Ileewosan Lagos State University Teaching Hospital ati ileẹjọ giga Ikeja High Court.''

Ileeṣẹ Ikeja Electric ni laipẹ ni atunṣe naa yoo koju si agbegbe Alimosho ati Agege fun saa keji atunṣe awọn ẹrọ apinaka.

Bakan naa ni wọn fikun un pe o da awọn loju wi pe atunṣe yii yoo jẹ anfaani fun awọn ọmọ Naijiria to jẹ olubara wọn lẹyin ti wọn ba pari atunṣe naa.