Reno Omokri: Gbogbo ẹ̀yín tí ẹ bá ní dola ninú ''acount'' yín sí Naijiria, inú ewu le wà

Naira notes (file photo)

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iro ni, ko si ohun to jọ pe a fẹ gbẹṣẹ le owo awọn eniyan to wa ni ''domiciliary account'' - CBN

Ileeṣẹ Banki apapọ lorilẹede Naijiria, CBN ti ni irọ patapata ti ko si otitọ kankan nibẹ ni iroyin gbe ijọba fẹ gbe ẹṣẹ le apo asunwọn ọwọ awọn eniyan to wa ni iye owo ilẹ okeere.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti ni awọn ẹni ibi lo n pa irọ fun awọn eniyan.

CBN ni awọn ko ni lailai gbe iru igbesẹ bẹẹ nitori awọn ọmọ to wa ni apo iṣuna yii kii ṣe ti wọn, nitori naa awọn ko le e gbe ẹṣẹ le.

Àkọlé fídíò, Ebun Oloyede Olaiya Igwe sọ ohun tí ojú rẹ̀ rí lásìkò àìsàn kídìnrín tó yọ ọ́ lẹ́nu

''Awọn ẹni ibi to fẹ da wahala silẹ lawujọ, ki awọn eniyan bẹrẹ si ni bẹru ni wọn n fi iru iroyin bayii lede.''

''Ẹyin araalu ko si ohun to jọ igbesẹ bẹẹ, wọn kan fẹ ba igbagbọ ti awọn eniyan ni ninu banki apapọ jẹ ni.''

Bakan naa ni wọn fikun un pe iroyin ti wọn ko ba ti ri ni oju opo wọn ko wa lati ọdọ wọn,nitori naa ki awọn eniyan ma gbe ọkan ara wọn soke nitori awọn oniroyin ẹlẹjẹ.

Àkọlé fídíò, Africa Eye wádii àwọn tó wà nídìí ìgbésùmọ̀mí ni Mozambique

CBN ni gbogbo awọn to wa ni idi iroyin ofege yii ni yoo foju wina ofin.

$100 bills - file photo

Oríṣun àwòrán, AFP

Saaju ni Reno Omokri ti sọrọ:

Gbogbo ẹ̀yín tí ẹ bá ní dola ninú ''acount'' yín sí Naijiria, inú ewu le wà

Agbẹnusọ tẹlẹri fun aarẹ Goodluck Jonathan, Reno Omokri ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn ba ni owo ilẹ okeere si inu apo isuna ''Account'' wọn lati ṣọra ṣe nitori ijọba Naijiria ṣetan lati gbẹṣẹle owo wọn.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

Ninu fidio to fi lede ni Reno Omokri ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria bẹẹ pe ki wọn ko owo wọn kuro ni apo isuna ''Domiciliary account''

Omokri ni idi ni pe gbese ti orilẹede Niajiria ti jẹ si ilẹ okeere ti kọja keremi, eleyii to ti mu ijọba jẹ iye owo to to triliọnu mẹrindinlogoji.

Gbogbo ẹ̀yín tí ẹ bá ní dola ninú ''account'' yín sí Naijiria, inú ewu le wà - Reno Omokri

O ni eleyii tun mọ si pe orilẹede Naijiria ko ni owo lati san awọn gbese ti wọn jẹ awọn orilẹede ni agbaye.

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

''Aarẹ Buhari fun ara rẹ sọ ni ipade Ajọ Iṣọkan Agbaye, UN pe ki awọn ti wọn jẹ ni gbese fi silẹ fun awọn nitori iya ati iṣẹ ti ohun ba wọn finra.''

''Amọ wọn tun n bere fun iranlọwọ lati ya owo miran, eleyii ti ko mu ọpọlọ dani fun ẹnikẹni, ti yoo si fa Naijiria si oko ẹru.''

Omokri ni eleyii tun mọ si pe ijọba yoo bẹrẹ si ni gbeṣẹ le owo awọn eniyan to wa ni banki, paapaa awọn owo ilẹ okeere ti awọn eniyan ko fi ọwọ kan.

O wa parọwa si awọn eniyan lati lọ ko owo wọn kuro ni domiciliary account, nitori owo to wa ni apọ iṣuna yii jẹ biliọnu mẹrindinlogun naira.

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan