Bí mo ṣe ná $88,521 lórí, igún, ìfun eerin, agbárí kìnnìhún láti gbé ẹbọ

Ọkunrin kan ti wọn mu fun ẹsun lilo orukọ ẹlomiran àti iluni ni jibiti ti ṣalaye bi o ṣe na ẹgbẹrun lọ́mejidinlaadọrun ati ẹẹdẹgbẹta dọla to gba lọwọ ẹni to lu ni jibiti.
Ọdaran naa, to n jẹ Jamiu Isiaka ni wọn ti ran lọ si ẹwọn ọdun mejidinlọgbọn fun lilo orukọ olubadamọran pataki lori ọrọ to nm lọ ati iroyin fun aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina.
Wọn ni o jẹbi ẹsun lilu ọmọ South Korea kan keun Sig Kim ni jibiti owo dọla 88,521 tó jẹ ọgbọ̀n mílíọnu Naira.
Isiaka lasiko to n bẹbẹ pe oun ko jẹbi ẹsun gẹ́gẹ́ bi iroyin NANS se sọ lo ṣalaye fun ile ẹjó giga ipinlẹ Kwara to fi ikalẹ si ilu Ilorin pe oun fi owo naa gbe ẹbọ ni.
Diẹ ninu owo naa, ni oun fi ra igun, awọn eerin, ifun eerin, agbari kinnihun ati ẹdọ gorilla ti oun sapọp lati gbe ẹbọ.
Ẹka ajọ EFCC ti kọkọ gbe ọdaran naa lọ di ile ẹjọ ni ọjọ kẹrinla, ninu osu kẹfa ọdun 2019 lori ẹsẹ mẹrin eyi ti o si ni oun ko jẹbi ẹsun.
Lasiko idajọ rẹ adajọ Mahmud Abdulgafar ṣalaye pe ẹri to daju ti wa niwaju ile ẹjọ, olujẹjọ naa si jẹbi ẹsun ti wọn fi kan
Lẹyin eyi ni adajọ ni o jẹbi ẹsun ti o si ni ki o lọ ẹwọn ọdun meje fun ẹsun kọọkan kí o si maa ṣe bi o ṣe n pari ọkan.
Ile ẹjọ tun ni ki wan gba gbogbo nkan ni rẹ fun ijọba apapọ nitori pé gbogbo nmǹmkan ti o kojọ lọna aitọ.
Àwọn nnkan ti wọn gba lọwọ rẹ ni ile ilẹ kan ni Oke-Foma, Ilorin, ọkọ Toyota Corolla, Amohunmaworan ẹrọ amuna wa, ati amuletutu.
Bakan naa ni ile ẹjọ ni ki o ṣe atunsẹ lọdọ ẹni ti o lu ni jibiti.
Il ẹjọ ni o n pe ara rẹ ni olubadamọran pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina ati adari ile isẹ NNPC Maikanti Baru fun Keun Sig Kim ọmọ South Korea lati lu ni jibiti ọgbọn miliọnu Naira.
Awọn ọlọpaa ati ajọ EFCC mu ẹri jade lori bi o se gba owo gọbọi lọwọ Keun nitori o pe ara rẹ ni ọga agba kan ninu ijọba ati pe oun n ran lọwọ lati gba awọn iwe ni NNPC.

















