52 year old man rapes daughter: Ọwọ́ tẹ bàbá ẹni ọdún 52 tó ti ń bá ọmọ rẹ̀ lòpọ̀ fún ọdún

Ifipalopo

Oríṣun àwòrán, @Embyr

Lati ipinlẹ Ogun ni iroyin Kayefi kan ti bọ si wa lọwọ pe ọwọ tẹ afurasi ẹni ọdun mejilelaadọta kan Adebayo Akinrinoye ti wọn si ti fi si atimọle ọlopaa fun sun pe o n ba ọmọ lajọṣepọ.

Ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹsan ni akara tu s'epo ti awọn ọlọpaa si fi ṣikun ofin mu u . Ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni ọmọ rẹ ọhun ti a fi ailorukọ bo laṣiri.

Aridaju eyi jẹ jade lati inu atẹjade ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti wọn fi ṣọwọ si BBC Yoruba.

Afurasi naa n gbe ni agbegbe Idi Oparun, Matogun Agbado ni ipinlẹ Ogun. Awọn ọlọpaa lọ gbe e lẹyin ti wọn gba iwe ifẹsunkan ti ọmọ rẹ kọ to mu wa si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Agbado.

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Ninu iwe naa ni ọmọ ọhun ti fi ẹsun kan baba oun ti n fipa ba oun lopọ latigba to ti wa ni ọmọ ọdun mẹrinla lati igba naa si ni afurasi ọhun ti n fipa baa lopọ.

Arabinrin ọmọ ọdun mẹrindinlogun naa ṣalaye pe gbogbo akitiyan oun lati mu dawọ baaba oun duro ninu gbogbo iwa ko tọ yii lo ja si pabo to si maa n bọ si ẹyin eti rẹ lo mu ki oun wa fi ẹjọ sun.

Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nigba ti wọn ka iwe ifẹsun kan ọhun, kete ni DPO ọlọpaa, CSP Kehinde Kuranga ran awọn ọlọpaa lọ si ile naa nibi ti wọ ti fi ṣikun ofin mu arakunrin naa.

Nigba ti wọn fi ọrọ waa lẹnu wo, afurasi naa jẹwọ pe lootọ ni oun n ba ọmọ oun lopọ amọ ki ọmọ dari ẹṣẹ ji oun.

Ẹwẹ, ọrọ ti di ọrọ ijọba bayii, kọmisọna Ọlọpaa, Edward Awolowo Ajogun si ti paṣẹ pe ki wọn gbe afurasi naa lọ si ẹka wọn to n ri si ọrọ idile fun itẹsiwaju iwadi ati fifi jofin.