Aishat Adesina: Àwa akẹ́ẹ̀kọ́ lòdì sí bí àwọn adarí iléẹ̀kọ́ OAU ṣe ti fásitì, ìfẹ̀hónúhàn tẹ̀síwújú lórí ikú akẹ́ẹ̀kọ́

OAU

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ni Fasiti Ọbafemi Awolowo ,NANS ti tako aṣẹ adari ileẹkọ naa pe ki awọn akẹkọọ kuro ni ileewe naa ni kiakia.

Ẹgbẹ awọn akẹkọọ ọhun ninu atẹjade ti wọn fi lede ṣe apejuwe aṣẹ fasiti naa gẹgẹ bi ohun to lodi si ẹtọ awọn akẹkọọ.

Awọn alaṣẹ fasiti naa lo paṣẹ ọhun lẹyin ti awọn akẹkọ bẹrẹ ifẹhọnu nitori ọkan lara wọn Aishat Adesina to gbẹmi mi lasiko to n ṣe aisan, ti wọn si gbe e lọ si ileewosan to wa ninu ọgba fasiti naa.

Àkọlé fídíò, 'Ìyà Muinat kú nígbà tó ń mu ọmú lọ́wọ́ ni èmí ìyà-ìyá rẹ̀ ń tọ́jú rẹ̀ kí ògiri kíláàsì tó wó pa á'

Ninu ọrọ ti wọn sọ, awọn akẹkọọ faraya nitori pe wọn da ẹbi iku akẹkọọbinrin naa ru ileewosan fasiti OAU nitori aibikita wọn ni eto ilera akẹkọọ naa nigba to lọ si ileewosan ọhun fun iwosan.

''Awọn oṣiṣẹ ileewosan fasiti naa ko dahun si obinrin ọhun to n ṣe aisan, ti wọn si fi silẹ titi ti ẹmi fi bọ ni ara rẹ.''

''Lẹyin naa ni wọn paṣẹ pe ki wọn gbe e lọ si ileewosan Adventist to wa ni igboro, amọ ileewosan naa ni akẹkọbinrin naa ti ku ki wọn to gbe e de ibẹ''.

Awọn akẹkọọ OAU to n se iwọde

''Ẹtọ wa ni lati fi ẹhonuhan, amọ kaka ki awọn alaṣẹ ba wa sọrọ nigba ti a kesi wọn, niṣe ni wọn kọ iwe si awọn akẹkọọ lati fi ọgba silẹ''

''A ko ni ibi kankan lọ nitori awọn akẹkọọ n kọ idanwo wọn lọwọ, nitori naa ki awọn alaṣẹ da ero wọn pada.''

Ẹgbẹ awọn olukọ naa wa kesi awọn akẹkọọ lati tẹsiwaju ifẹhonuhan to n waye naa paapaa ni iwaju ileẹkọ naa lati tako aṣẹ adari fasiti naa.

Bakan naa ni wọn paṣẹ ki awọn alaṣẹ ileewe naa ṣi ileewe pada fun awọn akẹkọọ lati pari idanwo ti wọn n ṣe lọwọ.