Air Marshal Sikiru Smith: Àwọn ajínígbé tú Ọ̀gágun ojú òfurufú Sikiru Smith sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Awọn ajinigbe to ji ọgagun oju ofurufu kan ajagunfẹyinti Sikiru Smith gbe ti tuu silẹ ko maa lọ lalafia.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Adekunle Ajisebutu lo fi aridaju rẹ han.
Ni agbegbe Lekki ni wọn ti ji i gbe ni ọsẹ diẹ sẹyin nigba ti iroyin ni o n boju to iṣẹ rẹ ni Ajah l'Eko nigba ti awọn agbebọn to da nkan boju ya wọ ibẹ ti wọn si jii gbe.
Iroyin ni ọkọ oju omi kan ni wọn fi gbee lọ. Gẹgẹ bi awakọ rẹ ṣe ṣalaye, Ọgagun naa n ba awọn ajinigbe naa faa ṣaaju itusilẹ rẹ.
- Mínísítà Sunday Dare gbéná w'ojú Obasanjọ tó ní Buhari ò pèsè iṣẹ́ f'áwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà
- 'Àwa akẹ́ẹ̀kọ́ tako bí àwọn adarí fásitì OAU ṣe ti iléẹ̀kọ́, ìfẹ̀hónúhàn tẹ̀síwújú lórí ikú akẹgbẹ́ wa'
- Ọlọ́pàá tají padà lẹ́yìn 'Coma' oṣù mẹ́sàán, 'sack letter' làwọn ọ̀gá rẹ̀ fi kíi káàbọ̀
- Ọwọ́ tẹ bàbá ẹni ọdún 52 tó ń bá ọmọ rẹ̀ lòpọ̀ fún ọdún méjì
Bi wọn ṣe ji Ọgagun Smith gbe
Awọn ajinigbe tun soro nilu Eko pẹlu bi wọn ṣe ji ọgagun fẹyinti Sikiru Smith.
Adugbo Ajah nilu Eko ni wọn ti ji ibatan ọga agba ọlọpaa Musiliu Smith yi gbe lọjọ Aje.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ lati ọdo ileeṣẹ iroyin Naijiria The Punch,Smith n mojuto iṣẹ agbaṣe kan ni lasiko tawọn agbebọn ya bo ibudo iṣẹ naa.
A gbọ pe niṣe ni wọn bẹrẹ si ni yinbọnsoke ti wọn si ji Smith gbe salọ.
Inu ọkọ oju omi ti wọn gbe si itosi ni wọn gbe Smith si ti wọn si na papa bora.
- Baba Ijesha yóò farahàn nílé ẹjọ́ lónìí, àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe níbẹ̀ nìyí
- Sotitobire pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀wọ̀n gbére
- Kíláàsì wó lé ọmọ ilé ẹkọ́ mẹ́ta lórí, ọ̀kan ti kú, ẹ wo ohun tó ṣe méjì tó kù
- Ìran mi ò ja ẹ̀ṣẹ́ rí, ẹ̀gbin yìí ló ta lé mi tí mo fi di "Scorpion" Ọ̀gá ọ̀gá nínú ìjà
- "Láí fábàdà, a kò pín ipò ààrẹ sẹ́kùn gúúsù ní 2023"
- Wo agbègbè mẹ́fà tí òòrùn kìí ti wọ̀ fún àádọ́rin ọjọ́ nílé ayé
- Wo èrò Afenifere àti Ilana Omo Oduduwa lórí ọ̀rọ̀ Alaafin pé kò s'ọ́nà nínú pínpín Nàìjíríà
Iroyin naa tẹsiwaju pe awakọ ọgagun yi lo ke gbajare pe wọn ti jin ọga oun gbe salọ.
Kọburu Odili ninu ọrọ to sọ ṣalaye pe awọn wa nibi tawọn ti n ṣiṣẹ ni ki awọn agbebọn yi to wa ji ọga rẹ gbe.
''awọn agbebọn yi dasọ boju wọn si bẹrẹ si ni yinbọn soke titi ti wọn fi ji ọga mi gbe salọ''
Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ọlọpaa nipinlẹ Eko lori ọrọ yi, arakunrin Adekunle Ajisebutu sọ pe lootọ lawọn gbọ si iṣẹlẹ naa.
O ni iwadii n tẹsiwaju ati pe ọrọ ẹlẹgẹ ni iṣẹlẹ ijinigbe yi tori naa awọn ko fẹ sọ nkankan ti yoo ṣe akoba iwadii to n lọ lọwọ.
''Awọn ajinigbe ko ti sọ nkankan.Bi a ba tun mọ si nipa iṣẹlẹ yi, a o fi ọrọ naa to yin leti''













