Northern Governors Meeting: Akeredolu ní ìpàdé àwọn gómìnà àríwà kò ní kí ààrẹ má wá láti Gúúsù ní 2023

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu
Alaga awọn gomina ni ẹkun Guusu Naijiria, Oluwarotimi Akeredolu ti fesi si abọ ipade awọn gomina lẹkun ariwa Naijiria eyi ti wọn se lọjọ Aje.
Awọn gomina lati Ariwa Naijiria lo panupọ sọ pe awọn ko faramọ ọrọ tawọn gomina Guusu sọ pe aarẹ gbọdọ wa lati ẹkun awọn lọdun 2023.
Nigba to n fesi lori ikede naa, Akeredolu ni awọn gomina ariwa ni ẹtọ labẹ ofin lati sọ ohun ero wọn lori ibo aarẹ ọdun 2023.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìpanu ''small chops'' ló mú kí sọ́jà da omi ìdọ̀tí lé mi lórí - Corper Fidelia
- Ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn Baba Ijesha àti Princess tó ní ó fẹ́ bá ọmọ òun lájọṣepọ̀
- Sotitobire pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ẹ̀wọ̀n gbére
- Kíláàsì wó lé ọmọ ilé ẹkọ́ mẹ́ta lórí, ọ̀kan ti kú, ẹ wo ohun tó ṣe méjì tó kù
- Ìran mi ò ja ẹ̀ṣẹ́ rí, ẹ̀gbin yìí ló ta lé mi tí mo fi di "Scorpion" Ọ̀gá ọ̀gá nínú ìjà
- "Láí fábàdà, a kò pín ipò ààrẹ sẹ́kùn gúúsù ní 2023"
- Ọlọ́pàá kan d'àwátì l'Ogun, ẹbí rẹ̀ fẹ́ gbé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lọ sílé ẹjọ́
- Àlàyé rèé lórí bí sọ́jà ṣe lu àgùnbánirọ̀ obìnrin, tó da omi ìdọ̀tí le lórí
Gomina ipinlẹ Ondo ni iwọfa lẹnu, ko si ẹni to le sọ pe ki awọn gomina ariwa ma sọrọ, amọ eyi ko ni ohun kan ṣe pẹlu igbesẹ awọn gomina apa Guusu.
Laipẹ yii lawọn gomina apa Guusu sọ nibi ipade wọn to waye niluu Enugu pe, aarẹ Naijiria gbọdọ wa lati apa Guusu lọdun 2023.
Bakan naa ni wọn tun jiroro lori ọrọ gbigba owo ori VAT eyi ti wọn fẹnu ko le lori pe, awọn ijọba ipinlẹ lo yẹ ko maa gbaa.

Ẹ̀yin gómìnà Ariwa, ẹ dá a padà! Ààrẹ Naijiria gbọ́dọ̀ wá láti Gúsù ní 2023 - Afenifere
Bakan naa ni ẹgbẹ Afenifere ti fesi si ọrọ ti awọn gomina lati Ariwa Naijiria sọ pe ko si ninu ofin Naijiria pe ki wọn o maa pin ipo aarẹ kaakiri awọn ẹkun to wa ni Naijiria.
Akọwe ikede fun ẹgbẹ naa, Jare Ajayi sọ fun iwe iroyin Punch pe iyalẹnu lo jẹ pe awọn gomina naa sọ ọrọ yii, bo tilẹ jẹ pe awọn kan lara wọn ti kọkọ sọ pe ẹkun Guusu lo yẹ ki aarẹ ti wa lọdun 2023.
Ọgbẹni Ajayi sọ pe iha ti awọn gomina naa kọ si ọrọ naa fihan pe ọrọ ori ahọn ni iṣọkan ti wọn n polongo wa, ko si ninu ọkan wọn.

Oríṣun àwòrán, the Punch
O ni lootọ ni ko si ninu iwe ofin Naijiria pe ki wọn o maa yan aarẹ ni ẹkun kọọkan, "amọ o n waye nitori ki iṣọkan le wa".
"Lootọ ni ẹgbẹ Afenifere gba pe ko si ibi ti aarẹ ko ti le wa, amọ akoyawọ ati ilana dọgba-dọgba tọka si pe ẹkun Gusu ni aarẹ Naijiria gbọdọ ti wa lọdun 2023.
"Nipa ṣiṣe bẹẹ nikan ni alaafia fi le wa ni orilẹ-ede yii."

"Lai fabada, a ko ni pin ipo aarẹ si ẹkun guusu"
Ọjọ Aje ni awọn gomina to wa lawọn ipinlẹ mọkandinlogun to wa lẹkun ariwa Naijiria yari pe ipo aarẹ ko ni wa si ẹkun guusu lọdun 2023.

Oríṣun àwòrán, Simon Lalong
Ipinnu wọn yii lo tako adehun ti awọn gomina lẹkun guusu Naijiria se lasiko ipade wọn to waye laipẹ yii pe ẹkun guusu Naijiria ni ipo aarẹ gbọdọ wa lọdun 2023.
Eyi si lo wa lara ohun ti awọn gomina ẹkun ariwa Naijiria fi ohun sọkan le lori nibi ipade ti wọn se pẹlu awọn ọba alaye lọjọ Aje eyi to waye nile ijọba nilu Kaduna.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo agbègbè mẹ́fà tí òòrùn kìí ti wọ̀ fún àádọ́rin ọjọ́ nílé ayé
- Wo iye àwọn olóṣèlú tó ti lọ ṣàbẹ̀wò sí Tinubu ní London
- Kíláàsì wó lé ọmọ ilé ẹkọ́ mẹ́ta lórí, ọ̀kan ti kú, ẹ wo ohun tó ṣe méjì tó kù
- Ìbẹ̀rùbojo wọ ìlú méjì ní ìhà Àrìwá Naijiria, Boko Haram tún ti gbàjọba níbẹ̀!
- Bí o bá ń fẹnukonu ju iye ìṣẹ́jú ààyá yìí lọ, wo adúrú kòkòrò tí wàá tí ibi ẹnu kò
Alaga ẹgbẹ awọn gomina naa, tii tun se gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong si lo ka atẹjade ti wọn fisita lopin ipade wọn ọhun lorukọ awọn akẹẹgbẹ rẹ.
Gẹgẹ bi awọn gomina naa ti wi, pinpin ipo aarẹ, gẹgẹ bi awọn gomina ẹkun guuusu se n beere fun, tako ofin ilẹ wa tọdun 1999 ti wọn se atunse rẹ.
Wọn ni aarẹ ti wọn ba dibo yan gbọdọ ba ilana ti ofin ilẹ wa la kalẹ mu, lara rẹ si ni ko ni ibo to pọ julọ.
Bakan naa ni wn lo gbọdọ ni ida mẹẹdọgbọn ninu ọgọrun gbogbo ibo, ko si tun ni ida meji ninu mẹta ibo yika ipinlẹ mẹrindinlogoji to wa lorilẹede wa.
Gomina Lalong tọkasi pe bi o tilẹ jẹ pe awọn gomina kan lati ẹkun ariwa Naijiria ti fontẹ lu ibeere awọn gomina guusu pe ki ipo aarẹ bọ si ẹkun guusu lọdun 2023.
Amọ o ni apapọ awọn gomina lẹkun ariwa koro oju si ipe yii patapata.
Lori ọrọ owo ori ọja VAT to n fa awuyewuye laarin awọn ipinlẹ kan ati ijọba, awọn gomina ariwa fẹnuko pe niwọn igba ti ẹjọ naa ti wa nile ẹjọ, awọn ko ni sọrọ nipa rẹ.
Amọ Lalong salaye pe ko yẹ ki awọn gomina naa si owo ori ọja mu si owo ọja tita.
O ni bi ipinlẹ kọọkan ba gbe ofin owo ofin ọja kalẹ nipinlẹ rẹ, ọrọ naa yoo di gbigba owo ori ọja lọna pupọ eyi ti yoo mu ki ọja gbe owo lori, ti okoowo lati ipinlẹ kan si ekeji yoo si dẹnu kọlẹ.
Nipa aifararọ eto aabo lẹkun ariwa ilẹ yii, awọn gomina lẹkun naa gbosuba sileesẹ ologun lori aayan lati gbogun ti awọn agbebọn ati idaluru lẹkun naa.
Amọ awọn gomina yii wa fi oju laifi wo bi awọn osisẹ eleto idajọ kan se n lẹdi apo pọ pẹlu awọn onisẹ ibi naa, ti wọn i n tu awọn ọdaran ti wọn ba mu silẹ.


















