Sun Sets: Ǹ jẹ́ o mọ agbègbè mẹ́fà tí òòrùn kìí ti wọ̀ fún àádọ́rin ọjọ́ lórílẹ̀ ayé?

Oríṣun àwòrán, Andrew Fusek Peters
Igbe aye gbogbo ẹda lo wa yika wakati mẹrinlelogun tii se odidi ọjọ kan, wakati mejila fun ọsan ati wakati mejila fun oru.
Amọ bawo ni aye ẹda kan yoo ti ri, ti oorun ko ba pa oju de fun ọjọ gbọọrọ, bawo ni wọn se fẹ mọ ọṣan yatọ si oru?
Bawo ni awọn arinrin ajo afẹ yoo ti se ni ibudo kan ti oorun ko ba wọ nibẹ fun aadọrin ọjọ leralera?
- Baba Ijesha yóò farahàn nílé ẹjọ́ lónìí, àwọn ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe níbẹ̀ nìyí
- Wo ìdí tí àwọn tọkọ-taya kan ṣe ń ṣe ìgbéyàwó nínú pósí
- Wo obìnrin tó ní ojú ara méjì, ilé ọmọ méjì àti ẹsẹ̀ mẹ́rin
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ara fún ọkùnrin àti obìnrin
- "Ìgbéyàwó wa pé ọdun mẹ́ẹ̀dógún, àmọ́ ìgbà mẹ́wàá péré la ní ìbálòpọ̀"
- Obìnrin kan wọ ‘Wedding Gown’ láti wá ọkọ lójú pópó. Òpin ayé dé!
- Òkú obìnrin tí mò ń lọ wẹ̀ yọ sí mi, ohun tó sọ rèé - Agbókùújó
- Wo àwọn obìnrin kan tó ń fi ìbálòpọ̀ ṣe àlejò, tí wọn kìí sì wẹ̀
- Bí egungun bá há ọ lọ́fun, wo ohun méje tó ṣe láti yọ́
- Wo èèwọ̀ mẹ́wàá to fi lè bọ́ lọ́wọ́ ewu iná gáàsì
Koda iye onka ọjọ gan ko ye awọn araalu gan to wa ni awọn irufẹ ibudo bẹẹ mọ nigba ti oorun ko wọ mọ rara?
Awọn agbegbe mẹfa ree yika agbaye nibi ti oorun kii ti wọ rara, gbogbo akoko ọsan ni nibẹ laisi oru.
Ibudo mẹfa ni agbaye ti oorun kii ti wọ:
Orilẹede Norway:
Ni orilẹede Norway, ni agbegbe ti aye ti yipo, (Norway, in the Arctic Circle) ni wọn n pe ni "Ilẹ ti oorun ti n jade loru".
Lati osu karun ọdun, eyiun May titi di ipari osu keje July, oorun kii wọ ni agbegbe yii rara fun ọjọ mẹrindinlọgọrin
Ni agbegbe Svalbard lorilẹede Norway, oorun maa n ran lati ọjọ Kẹwa osu Kẹrin April titi wọ ọjọ Kẹtalelogun osu Kẹjọ August ni.
Ẹyin naa le seto lati se abẹwo si agbegbe yii lawọn akoko ta mẹnuba naa , kẹ si duro fun ọjọ pipẹ lai foju kan okunkun tabi oru.
Agbegbe Nunavut ni orilẹede Canada:

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Agbegbe Nunavut to wa ni orilẹede Canada naa sunmọ agbegbe ti aye ti yipo (Arctic Circle)ni awọn apa iwọ oorun ariwa orilẹede Canada.
Agbegbe yii maa n ri oorun ni ojoojumọ fun osu meji gbako, amọ nigba to ba di akoko otutu, inu okunkun biri biri ni agbegbe naa maa n wa fun ọgbọnjọ, tii se osu kan gbako.
Eyi tumọ si pe oorun kii ran rara lawọn akoko ti otutu ba mu lagbegbe naa.
Orilẹede Iceland:
Orilẹede Iceland lo jẹ erekusu to tobi julọ ni ilẹ Yuroopu lẹyin United Kingdom, bakan naa lo jẹ orilẹede ti ẹfọn ẹyọ kan soso ko si nibẹ rara.
Lasiko ooru, ko si okunkun rara ni orilẹede Iceland , to ba si ti di osu Kẹfa June, oorun kii wọ nibẹ rara.
Tẹ ba fẹ mọ bi ọsan ati oru bi Ọlọrun se da wọn, ẹ le se abẹwo si erekusi Akureyri ati Grimsey to wa ni agbegbe ti aye ti yipo.
Agbegbe Barrow ni Alaska lorilẹede Amẹrika:

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lati ipari osu Karun May titi wọ ipari osu Keje July, oorun kii wọ ni agbegbe Barro to wa nipinlẹ Alaska ni orilẹede Amẹrika.
Amọ to ba di ibẹrẹ osu Kọkanla November, ọgbọnjọ pere ni oorun fi maa n yọ, eyi si ni wọn n pe ni 'polar night'.
Itumọ rẹ ni pe ilẹ naa yoo wa ninu okunkun lasiko ti otutu ba mu, ti oorun ko si ni yọ nibẹ mọ.
Bakan naa ni agbegbe yii gbajumọ fun awọn yinyin to ti di oke, o si dara lati se abẹwo si agbegbe yii lasiko ooru tabi otutu.
Orilẹede Finland:
Orilẹede Finland jẹ ilẹ to kun fun ẹgbẹlẹgbẹ adagun odo ati erekusu .
Ọpọ agbegbe to wa ni orilẹede Finland lo n ri oorun taarata fun ọjọ mẹtalelaadọrin gbako lasiko ti ooru ba mu.
Amọ lasiko otutu, ko ni si oorun rara, ti ko si nmi yọ rara.
Idi ree ti awọn eeyan orilẹede Finland kii se sun pupọ lasiko ooru ati ni asiko otutu.
Ti ẹ ba wa ni agbegbe yii, ẹ ni anfaani lati ri 'ina ila oorun' ina to mọlẹ rokoso, ti eeyan si tun le sere idaraya sisare lori yinyin.
Orilẹede Sweden:
Lati ibẹrẹ osu Karun May si ipari osu kẹjọ August, ni orilẹede Sweden ti maa n foju kan oorun ti yoo yọ lati aago mẹwa aarọ, ti ko si ni wọ mọ.
Tẹ ba lọ sibẹ, ẹ le lo akoko yin lati maa fi se ere idaraya Golf, pa ẹja ninu odo tabi rinrin ajo afẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èrò Afenifere àti Ilana Omo Oduduwa lórí ọ̀rọ̀ Alaafin pé kò s'ọ́nà nínú pínpín Nàìjíríà
- Wo iye àwọn olóṣèlú tó ti lọ ṣàbẹ̀wò sí Tinubu ní London
- Kíláàsì wó lé ọmọ ilé ẹkọ́ mẹ́ta lórí, ọ̀kan ti kú, ẹ wo ohun tó ṣe méjì tó kù
- Ìbẹ̀rùbojo wọ ìlú méjì ní ìhà Àrìwá Naijiria, Boko Haram tún ti gbàjọba níbẹ̀!
- Bí o bá ń fẹnukonu ju iye ìṣẹ́jú ààyá yìí lọ, wo adúrú kòkòrò tí wàá tí ibi ẹnu kò
- Fá irungbọ̀n rẹ, kòó forí kó ìyà lọ́wọ́ ìjọba Afghnistan - Taliban
- Wo ìdí tí CAN fi fún Imaamu kan l'ami ẹyẹ níbi ayẹyẹ ńlá ọdún 45 ti CAN pé
- Àdúrà Saga gbà, òun pẹ̀lú Nini jáde lọ́jọ́ kan náà
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'


















