Marriage Crisis: Pásítọ̀ ní ìyawò òun yọ ilé ọmọ rẹ̀ láì bún òun gbọ́, kò sì gbá ìbálòpọ̀ fún òun

Stephen Macharia

Oríṣun àwòrán, Wambui wa Mwangi

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Pasitọ kan ti sọ pe igba mẹwaa pere ni oun ba iyawo oun ni ibalopọ gẹgẹ bii lọkọ-laya bo tilẹ jẹ pe wọn ti jọ n gbe gẹgẹ bii tọkọ-taya fun ọdun marundinlogun.

Ojiṣe Ọlọrun naa, Stephen Macharia, sisọ loju ọrọ yii ninu fidio kan to gba ori ayelujara lasiko to n ba akọroyin kan, Jane Wambui Wamwangi ni Kenya fọrọwerọ.

Pasitọ naa ṣalaye pe, alẹ ọjọ igbeyawo naa ni oun ti kọkọ n fura si obinrin ọhun lẹyin ti ko gba lati ba oun ni ibalopọ.

Bo tilẹ jẹ pe o ni oun ko mọ eredi to ṣe hu irufẹ iwa bẹẹ, ṣugbọn oun ko gbagbọ pe o n yan ale lẹyin oun.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, obinrin naa ko bi ọmọ kankan fun oun ni gbogbo ọdun marundinlogun ti wọn fi wa papọ, amọ o ti bi ọmọ kan tẹlẹ ṣaaju ki wọn to pade.

Àkọlé fídíò, Abdulfatai Balogun: N kò ríran àmọ́ oníṣòwò Yoghurt ní mí tó ń fi àwìn sàánú fún oníbàárà

Iyawo mi yan alabasisẹ mi ni ale:

O ni oniruru ipenija ni oun dojukọ ninu igbeyawo naa, ṣugbọn oun nifẹ obinrin naa denu, oun ko si huwa ipa si ninu ile.

Ko pẹ ti igbewayo naa bẹrẹ, ti pasitọ naa gbọ pe obinrin ọhun n ni ibaṣepọ pẹlu ọkan lara awọn alabaṣiṣẹ rẹ, ti ọkunrin ti ọrọ naa kan si jẹwọ pe lootọ ni, ṣugbọn iyawo rẹ ọhun ko naani ẹsun naa.

Pasitọ Stephen Macharia ṣalaye pe iyawo oun yọ ile ọmọ rẹ sọnu lọna ati mase bi ọmọ kankan fun oun.

Lẹyin o rẹyin, Pasitọ Macharia lọ sile ẹjọ lati jawe ikọsilẹ fun iyawo rẹ ọhun, ile ẹjọ naa si dahun ẹbẹ rẹ lẹyin ọdun marun un to pe ẹjọ naa.

Wayi o, Macharia ti fẹ obinrin miran, obinrin ọhun si ti bi ọmọ mẹta fun.

Pasitọ ọhun ti wa rọ awọn ọdọ ki wọn ṣe iwadii finnifinni nipa ẹnikẹni ti wọn ba fẹ gbe niyawo ki wọn to pinnu lati fẹ irufẹ ẹni bẹẹ, ki wọn ma baa kabamọ.

Àkọlé fídíò, Wo ohun tí Professor Peller wí tó kó bá a gẹ́gẹ́ bí ìyàwó rẹ̀, Lady Peller ṣe tú u síta