St Helens Dog: Àlàyé rèé lórí bí ajá ọ̀sẹ̀ kan ṣe pa ọmọ ọdún kan àti oṣù márùn-ún sínú ilé

Aja

Ara meeriri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ kan to waye ninu idile kan ni St Helens nilẹ Gẹẹsi.

Aja kan ti olowo rẹ ra lati maa sọ ile lo ma sadede kọlu ọmọ wọn, ọmọ ọdun kan ati osu marun, ti ọmọ naa si jade laye.

Isẹlẹ naa lo waye ninu ẹbi kan ni Bidston Avenue, agbegbe Blackbrook nilu St Helens.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọkan lara awọn aladugbo salaye pe se ni oun n gbọ ẹkun ọmọ naa kikankikan amọ oun ko fi oju kan aja naa.

O ni oun kan soso to jẹ oun logun ni lati daabo bo ẹmi ọmọ ọhun.

Bella-Rae

Oríṣun àwòrán, FAMILY PHOTOGRAPH

Bawo ni ọmọdebinrin naa se ku?

Gẹgẹ bi ileesẹ ọlọpaa Merseyside ti salaye, ọmọde naa ti orukọ rẹ n jẹ Bella-Rae lo ku nile iwosan ni deede aago mẹrin ku isẹju mẹwa lọjọ Aje to kọja.

Awọn mọlẹbi ọmọ naa ni bi o tilẹ jẹ pe ko si ni aarin awọn mọ, awọn ko ni gbagbe rẹ lailai, ti aaro rẹ yoo si maa sọ awọn loore koore.

Joanne Matthews tii se aladugbo miran ni oun ri ọkọ alaisan pajawiri, eyiun Ambulansi niwaju ile naa, ti awọn ọlọpaa bii mẹwa si yọju.

"Mo ri ti wọn mu aja naa bọ sita, n ko mọ irufẹ aja to jẹ amọ lati ẹyin wa, o dabi aja Staffordshire bull terrier tabi pit bull."

Mattews, tii se obinrin ẹni ọdun mẹtalelaadọta ni ọmọdebinrin to rẹwa ni ọmọ to ku naa.

O fikun pe oun kan maa n ri tawọn mọlẹbi ọmọ naa kan maa n kọja lọ ni, ti awọn si maa n se hello si ara awọn.

Awọn ọlọpaa to n duro niwaju ile ọmọ to ku

Ọsẹ kan sẹyin ni ẹbi ọmọ naa ra aja to pa ọmọ wọn - Ọlọpaa

Ileesẹ ọlọpaa lo kede pe ẹbi Bella-Rae sẹsẹ ra aja naa ni ọsẹ kan sẹyin ni, ko to wa kọlu ọmọde naa, to si seku pa a.

Wọn ni awọn dokita atawọn osisẹ ti isẹ wọn fara pẹ isegun sọ pe awọn ọgbẹ ti aja naa da si Bella-Rae lara, lo mu ki ẹmi rẹ bọ lojiji.

Aja naa ni ileesẹ ọlọpaa ọhun ti pa, ti wọn si ni awọn yoo se ayẹwo rẹ lati mọ boya ọna ti ko bofin mu ni wọn fi peelo rẹ, ko to wale aye.

Bakan naa ni wọn ni awọn yoo se awari ẹni to lo aja naa tẹlẹ, ko to ta a sita, gẹgẹ bi ara iwadi awọn.

Steve Brizell tii se ọkan lara awọn ọga ọlọpaa naa ni "Ọkan lara ọna ti ko dara ni ọmọde naa, Bella-Rae gba jade laye.

Ọkọ alaisan pajawiri naa gbe Bella-Rae lọ sile iwosan amọ pẹlu gbogbo aayan awọn ọlọpaa lati doola ẹmi rẹ, pabo lo ja si."