Lagos Petrol Souvenir: Obìnrin tó pín epo pẹtirólù ní gbọ̀ngàn ayẹyẹ sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìdájọ́

Oríṣun àwòrán, lapearlnyc/Instagram
Idunnu ti subu lu ayọ fun obinrin kan to ha epo petrolu gẹgẹ bi ẹbun fawọn alejo rẹ nibi ayẹyẹ iwuye rẹ.
Bẹẹ ba gbagbe, iroyin naa lo gbalẹ kan lasiko ti epo wọn doju rẹ nilu Eko, ti obinrin naa si n ha epo ninu gbọngan ayẹyẹ fawọn alejo rẹ.
Lọjọ Ẹti to kọja nile ẹjọ dajọ pe obinrin naa jẹbi awọn ẹsun tijọba fi kan, to si ni ko lọ se ẹwọn ọdun meji lọgba ẹwọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ajá pa ọmọ olówó rẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ kan tí wọn rà á
- Abdulahi Adamu di alága àpapọ̀ tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC
- Lẹ́yìn ò rẹyìn, Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ ìpèsè ìrànwọ́ fún Ukraine lórí ìkọlù Russia
- Fayemi, Oyetola, Ganduje gúnlẹ̀ síbi ètò ìdìbò láti yan adarí APC l'Abuja
- Ọwọ́ tẹ Pásítọ̀, afurasí tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn búrọ́dà ṣọ́ọ̀sì mẹta láti ìdí ẹ̀yìn
- Agbébọn ṣé ikọlù sí pápákọ̀ òfurufú Kaduna, èèyàn kàn kú níbẹ
- Ọ̀rọ̀ tí Kemi Afolabi sọ síta lẹ́yìn táwọn kan ráńṣẹ́ síi torí ìtọ́jú àìsàn Lupus tó ní
- Olùdásílẹ̀ ìjọ méjì di afurasí tó pa ọmọ ìjọ lásìkò ìsìn, wo bí wọ́n ṣe sin òkú rẹ̀ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá
Idajọ yii lo ti n mu ki ọpọ eeyan maa gba bii ẹni gba igba ọti lori ayelujara.
Amọ nigba to n fesi lori idajọ naa, obinrin naa, Pearl Chidinma Ogbolu, tii se erelu Ọkin tilu Orile Kemta dupẹ lọwọ Ọlọrun lori ọrọ naa.
Erelu Ọkin, to gbe ero rẹ naa soju opo Instagram rẹ salaye pe oun dupẹ pe ọrọ naa ti kuro nile ẹjọ ti ọkan oun yoo si le papọ soju kan.
"Gbogbo ohun ti Ọlọrun ba se, daradara ni, oun si ni Oluwa.
Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan to pe mi atawọn to wa wo mi.
Mo gba gbogbo ẹbi ti wọn da mi, ti gbọngan ayẹyẹ naa, ti wọn ti pa lati igba ti ọrọ naa ti sẹlẹ, yoo si jẹ sisi pada."

Oríṣun àwòrán, lapearlnyc/Instagram
Miliọnu kan naira nile ẹjọ ni ki n san:
Erelu Ọkin wa sisọ loju rẹ pe lodi si iroyin to n lọ kaakiri pe ẹwọn ọdun meji ni oun maa se, o ni miliọnu kan naira ni owo itanran oun.
"Maa tiẹ le maa sun, maa hanrun bayii.
Wọn faini mi ni miliọnu kan naira owo itanran, mo si ti san gbogbo owo naa lẹkunrẹrẹ.
Mo wa dupẹ lọwọ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Agbẹjọro agba fun ipinlẹ naa, Ọmọwe Muiz Banire atawọn agbẹjọro rẹ.
Mo dupẹ, mo ti kuro nile ẹjọ oo:
Erelu Ọkin wa n fo fayọ pe oun ti kuro nile ẹjọ.
O ni oun yoo wa ri aaye bayii lati pada lọ maa saanu fun ọpọ eeyan gẹgẹ bi oun ti n se tẹlẹ.
O fikun pe isẹ ti oun gbajumọ ni lati maa mu ki aye tubọ rẹwa si fun ọpọ eeyan.
Arewa obinrin naa wa gbadura pe ki Ọlọrun bukun gbogbo awọn ololufẹ oun.
Bawo ni Erelu Ọkin se di ero ile ẹjọ:
Obinrin ọhun, Pearl Chidinma Ogbolu ni ọba ilu Orile Kemta, ọba Adetokunbo Tejuosho fi jẹ oye Erelu Okin tilu naa.
Amọ lasiko iwuye naa ni Erelu tuntun ọhun n pin epo pẹtiroolu bii ẹbun nibi ayẹyẹ naa, eyi to fa awuyewuye lori ayelujara.
Lọjọ Kẹrin oṣu Kẹta ni ayẹyẹ to ti pin bẹntiro gẹgẹ bi ẹbun amurele yii waye ni gbọngan Havilah Events Centre, to wa ni agbegbe Victoria Island, nilu Eko.
Koda, ijọba Eko kan fara ya lori isẹlẹ yii, tawọn ọlọpaa si lọ gbe obinrin naa ti mọ atimọle, ko to di pe wọn gbe lọ sile ẹjọ.
Lẹyin igbẹjọ naa, iroyin jade pe ile ẹjọ ti sọ obinrin naa si ẹwọn ọdun meji lori pe o pin eroja to le gbina ninu gbọngan ayẹyẹ ti ọpọ ero peju si.

Adájọ ní kí obìnrin tó fí bẹntiró ṣe ẹ̀bùn àmúrelé ní 'ówàńbẹ̀' fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì gbára tàbí ...

Oríṣun àwòrán, Citypeople/lapearlnyc/instagram
Ile ẹjọ to n gbẹjọ awọn aṣayan ẹsẹ nipinlẹ Eko eleyi to fi Oshodi ṣe ibujoko ti dajọ ẹwọn dun meji fun arabinrin to fi bẹntiroo ṣe ẹbun ni owanbẹ nilu Eko.
Arabinrin Chidinma Ogbulu ni adajọ Kehinde Ogundare gbe idajọ ẹwọn ọdun meji lelẹ fun un lẹyin to bẹbẹ pe oun jẹbi ẹsun naa lỌjọbọ niwaju adajọ.
Bakan naa lawọn to pe lẹjọ fi ẹri han adajọ lati le fidi ẹjọ ti wọn pe mulẹ.
- Obìnrin tó wà nídí ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé l'Eko ti yọjú síta
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ṣe ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé l'Eko
- Ọkùnrin kan fípa bá obìnrin tó sùn sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ lòpọ̀! Wo bí gbẹgẹdẹ ṣe gbiná
- Olùdásílẹ̀ ìjọ méjì di afurasí tó pa ọmọ ìjọ lásìkò ìsìn, wo bí wọ́n ṣe sin òkú rẹ̀ láì sọ f'Ọ́lọ́pàá
- Àwọn oúnjẹ tó n gbayì níbi ayẹyẹ báyìí
Lọjọ Aje to kọja ni wọn mu Chidinma ti wọn si gbe lọ siwaju ile ẹjọ yi labẹ akoso ẹka to wa ni Ikeja to si fi Oshodi ṣe ibujoko.
Kọmiṣana ọlọpaa Eko, Abiodun Alabi ti ṣaaju paṣẹ ki wọn mu arabirin naa lẹyin ti fidio ibi ti wọn ti n pin kẹẹgi epo bẹntiroo ti gbode loju opo ayelujara.
Lọjọ Kẹrin oṣu Kẹta ni ayẹyẹ to ti pin bẹntiro gẹgẹ bi ẹbun amurele yi waye ni Havilah Events Centre, to wa ni Victoria Island,Eko.
- Tọkọtaya kó sí gbaga ọlọ́pàá f'ẹ́sùn jíjí ọmọ ọjọ́ mẹ́fà gbé
- 'Ojú ara méjì ni mo ní, wọ́n sì bí i mọ́ mí ni'
- Ọwọ́ tẹ Pásítọ̀, afurasí tó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn búrọ́dà ṣọ́ọ̀sì mẹta láti ìdí ẹ̀yìn
- Olúwa mi, kò tọ́ ká bẹ ẹ̀ṣẹ̀ ọmọ wò lára baba; Ẹ ṣọ́ra fún ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn lórí ayelujára o!- Agbẹjọ́rò Ramon Adedoyin
Lẹyin igba naa wọn fi ẹsun onigun mẹrin kan eyi to da lori mimu ipalarea ba alaafia ilu, wiwu iwa to lewu si ẹmi awọn eeyan nipa pipin eronja to le gbina ni ode ati gbigbero lati se akoba fẹlomiran.
A tun gbọ pe wọn fẹsun kan pe o ṣowo gbigbe epo laigbaṣẹ sinu kondoro.
Ninu idajọ ti adajọ gbe kalẹ o sọ pe:
- Ki Ogbulu ṣẹwọn oṣu mta lori ẹsun akọkọ tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun mẹẹdogun Naira
- Ẹwọn ọdun kan tabi ko si san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira lowo itanran lori ẹsun ẹlẹẹkeeji
- Ẹwọn ọdun kan bakan naa lori ẹsun kẹta tabi ko san owo itanran ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira

















