Lagos petrol souvenir: Erelu Okin, Obìnrin tó ṣayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé tọrọ àforíjì, Ó ní àìláròjinlẹ̀ òun ló fàá

Oríṣun àwòrán, Citypeople/lapearlnyc/instagram
Ni ọjọ Abamẹta ni okiki fidio kan gbilẹ, nibi ti awọn alakoso ayẹyẹ 'owanbẹ' kan ti pin epo bẹntiro ninu kẹẹgi gẹgẹ bi ẹbun amurele fun awọn eeyan to wa sibi ayẹyẹ owanbẹ naa.
Fidio naa gbilẹ to bẹẹ gẹẹ ti ijọba ipinlẹ Eko ti fi atẹjade sita pe oun yoo ṣewadii rẹ ti oun yoo si awọn to wa nidi rẹ jofin.
Bakan naa lawọn eeyan kaakiri agbaye ti n sọrọ lori rẹ. Bi awọn kan ṣe n fi ọrọ naa ṣe awada ti wọn si n wi pe aṣọ igba la n da fun igba.
- Àwọn ǹkan márùn ùn tó lè padà tẹ̀yìn ìkọlù Russia sí Ukraine jáde
- Ìdí rèé tí a fi kéde lílo Hijab àti àwọn ìmúra míràn fún ọlọ́pàá obìnrin Nàìjíríà- Ilééeé ọlọ́pàá
- Sé lóòtọ́ ní ẹni ọdún 14 yìí fi májèlé sí oúnjẹ mọ̀lẹ́bí tó ń bá gbé ní Obada Oko? ohun tí a mọ̀ rèé..
- Russia kéde ìdádúró ṣíṣe ìkọlù sí àwọn ìlú méjì ní Ukraine
- Ìwádìí ti ń lọ lórí àwọn tó pín bẹntiró níbi ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' l'Eko - Ìjọba Eko
Wọn ni ohun to n ṣẹlẹ nilu, iyẹn ọwọngogo epo bẹntiro lo ṣokunfa igbesẹ naa.
Amọ awọn miran ni iwa ait gba a ni eyi ti o si lewu pupọ fun gbogbo awọn to wa nibẹ.
Ailarojinlẹ mi lo ṣokunfa iṣẹlẹ pinpin epo bẹntiro nibi ayẹyẹ owanbẹ mi- Erelu Ọkin

Oríṣun àwòrán, Screenshot/lapearlnyc/instagram
Nibayii, arabinrin to ṣe pati owanbẹ naa, Erelu Ọkin ti jade sita lati tọrọ aforiji lori iṣẹlẹ naa.
Erelu Ọkin gbe atẹjade aforiiji rẹ ranṣẹ sori oju opo instagram rẹ, pẹlu orukọ 'lapearlnyc'
O ni asiko ailarojinlẹ oun ni iṣẹlẹ naa ati pe ohun ko gbero ati ṣe ijamba fun ẹnikẹni tabi awujọ.
"Erongba mi ni lati fi imore han fawọn alejo mi fun fifarahan lainaani bi ilu ṣe kan gogo si lasiko yii"
O ni oun ti joko ronu jinlẹ lori ọrọ naa, oun si tọrọ aforiji fun awọn ọrọ to ti ẹyin rẹ yọ.
Gẹgẹbi ERELU OKIN, afojusun mi ni lati mu adun ba igbesi aye awọn eeyan, n o si maa tiraka ati maa tubọ ṣe ohun to tọ siwaju ati siwaju sii."












