Abeokuta poison Obada: Sé lóòtọ́ ní ẹni ọdún 14 yìí fi májèlé sí oúnjẹ mọ̀lẹ́bí tó ń bá gbé ní Obada Oko? ohun tí a mọ̀ rèé..

omode naa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iroyin to gba igboroa kan ni pe ọmọ ọdun merinla kan fi majele si ounje ounjẹ ẹgbọn baba rẹ, Oloye Elizabeth Adesusi lagbegbe Obada-Oko, ipinlẹ Ogun.

Ọmọ ọdun mẹrinla kan ti a fi orúkọ bo laṣiri la gbọ pe o fi majele sinu ounjẹ ẹgbọn baba rẹ, Oloye Elizabeth Adesusi lagbegbe Obada-Oko, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun.

Bawo ni ọ̀rọ̀ se jẹ́?

Aarọ ọjọ Aje tii ṣe Mọnde to kọja yii la gbọ pe ọmọdebinrin naa, to wa ni pamari siisi (6) kọkọ ji owo ẹgbọn baba rẹ, ẹgbẹrun mẹfa naira ko, bo tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi rẹ mulẹ.

Wọn ni owo naa lo ko lọ sileẹ̀kọ́, to si lọ na baṣubaṣu.

BBC YORUBA gbọ pe alẹ ọjọ Iṣẹgun, lo fi majele, ogun ekute sinu gaari ti Adeṣusi fẹẹ mu, ṣugbọn ti wọn sọ pe ọkan lara awọn araale wọn lo gboorun to ṣajoji ninu gaari naa.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

Ẹni naa lo si pariwo sita wi pe ki wọn yẹ gaari naa wo daadaa, ko to di pe wọn ri i pe oogun ekute wa nibẹ.

Wọn ni funra ọmọdebinrin yii lo sare gba gaari naa, to si lọ daanu, ki aṣiri ma ba a tu sita.

Àkọlé fídíò, Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀

Kini wọ́n tun wa lo selẹ̀?

Ọjọru, la tun gbọ pe ọmọ naa tun fi oogun ekute sinu ọbẹ ti Adeṣusi, ẹni ti ọpọ awọn eeyan tun mọ si Iyalode ṣẹṣẹ se.

Wọn nigba ti obinrin naa dana tan, lo pe ọmọdebinrin yii lati wa jẹun, ṣugbọn ti wọn lo sọ pe oun ko jẹ.Oorun ọbẹ naa lawọn eeyan tun gbọ, ti wọn sọ pe oogun ekute wa nibẹ. Idi ree ti wọn lawọn to wa nibẹ ṣe fura sii pe oun lo ṣiṣẹ naa.

omode naa

Wọn ni bi ọrọ yii ṣe tẹ awọn kan leti lọjọ Ẹti, Fraide ana lo jẹ ki wọn pariwo rẹ sita, ti wọn si lo pada jẹwọ pe lotitọ ni.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

Nigba to n jẹwọ, wọn ni ọmọ naa sọ pe nitori wọn ko fẹ koun ṣe idanwo Common Entrance sileewe girama, lo fa a toun fi fẹẹ ṣe iku pa ẹgbọn baba oun.

Wọn ko tii lọ fi ọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti titi di asiko ti a ṣakojọpọ iroyin yii tan.