Adegboruwa vs Police Dress Code Hijab: Agbẹjọ́rò àgbà yí ní lílò Hijab fáwọn ọlọ́pàá obìnrin takò òfin Nàìjíría, àlàyé rèé

Itako ti bẹrẹ si ni ba ikede ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lori igablaaye ti wọn fi fun awọn ọlọpaa obinrin lati maa wọ Hijab sabẹ fila gẹgẹ bi imura wọn lẹnu iṣẹ.
Agbẹjọro agba kan lorileede naa Ebun-Olu Adegboruwa lo fi ọrọ itako yii sita loju opo rẹ ni Facebook to si ti bẹrẹ si ni mu iriwisi ọtọọtọ wa.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ẹsin tawọn oṣiṣẹ ijọba baa n sin gbọdọ jẹ imọsinu wọn tori naa ọga agba ọlọpaa Naijiria ko lẹtọ lati lo ipo rẹ fi fẹsẹ ẹsin rinlẹ nidi iṣẹ ọlọpaa.
- Omidan tó ń wọ Hijab gba adé arẹwà Miss Nigeria fún ìgbà àkọ́kọ́
- Amasa Firdaus di agbẹjọro
- Ẹ kó àwọn ọmọ yín lọ sílé ẹ̀kọ́ àwọn Musulumi tí ẹ bá fẹ́ kí wọ́n máa lo Hijab - Oyedepo
- 'Ìjọba Kwara kàn fẹ́ fi ọ̀rọ̀ Hijab dá ìjà sílẹ̀ láàrin Krìstíẹ́ní àti Mùsùlùmí ni'
- Ìlẹ̀kẹ̀ otútú ọgbọ̀n, Ìrọ́kẹ́, àwa ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ náà fẹ́ káwọn ọmọ wa máa wọ lọ sílé ìwé - Elebuibon
O ni ẹsẹ iwe ofin Naijiria abala Kẹwaa sọ pe gbogbo awọn to jẹ oṣiṣẹ ijọba ko gbọdọ ṣ'ègbè lẹyin ẹsin kankan.
O tẹsiwaju pe bẹẹ naa ni ofin yi tako idẹyẹsi tori naa wahala ti ko lopin ni ọga ọlọpaa fẹ da silẹ lori igbalaaye lilo Hijab fawọn obinrin ọlọpaa.
Kini kawọn obinrin ọlọpaa Kristẹni tabi ẹlẹsin abalaye ṣe ?
Agbẹjọro agba Ebun-Olu Adegoruwa fi awọn ibeere kan gbe esi rẹ si igbesẹ ileeṣẹ ọlọpaa lẹyin.
''Iru aṣọ wo lo fẹ kawọn obinrin ẹlẹsin Kristẹni ijọ Aguda maa wọ? Awọn ti ijọ Cele nkọ to ṣe pe awọn kii wọ bata rara?''
''Ati pe bawo lo ṣe fẹ ki awọn ọlọpaa obinrin ẹlẹsin abalaye maa ṣe? Ṣe ki wọn maa so bantẹ sara aṣọ wọn ni?''
O kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe laduru nkan to n koju ileeṣẹ ọlọpaa bi owo, irinṣẹ ati nkan miran, ko yẹ ko jẹ pe ọrọ aṣọ ẹsin lo yẹ ko jẹ wọn logun.
Ko sọ boya ohun yo pe wọn lẹjọ ṣugbọn o ni ki ijọba gbajumọ iṣẹ kikoju awọn iwa ọdaran lawujọ.
Ebun-Olu Adegoruwa ti n dasi ọrọ Hijab ni Naijiria
Agbẹjọro agba ni Adegoruwa jẹ ti o si maa n da si ọrọ lori iṣejọba ati awọn ohun mii to kan Naijiria.
Bi ko ba maa dasi ọrọ pipin ipo oṣelu taa mọ si Zoning, Adegoruwa a tun maa da si ọrọ awọn ajafẹtọmọniyan to n koju idẹyẹsi lọdọ ijọba.
Koda o tun da si ọrọ Abba Kyari ọga ọlọpaa ti wọn lo ṣe aṣemaṣe.
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti gbọ̀ngàn tí wọ́n ti ṣe ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé l'Eko
- Obìnrin tó wà nídí ayẹyẹ 'ówàńbẹ̀' táwọn kan ti pín bẹntiró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn àmúrelé l'Eko ti yọjú síta
- Sé lóòtọ́ ní ẹni ọdún 14 yìí fi májèlé sí oúnjẹ mọ̀lẹ́bí tó ń bá gbé ní Obada Oko? ohun tí a mọ̀ rèé..
Loju opo rẹ ni Facebook, o ṣapejuwe ara rẹ gẹgẹ bi ajafẹtọmọniyan ati oluṣọ aguntan ninu ijọ Kristẹni, RCCG.
Ṣaaju asiko yi, Adegboruwa ti mẹnu ba ọrọ lilo Hijab paapa ni ipinlẹ Kwara to si ni ko yẹ ki ijọba da si ọrọ lilo Hijab ni ile ẹkọ Oyun Baptist High School.
Gẹgẹ bo ti ṣe sọ ninu apilẹkọ rẹ lori ọrọ yi, ''mo ti ri aridaju pe ipinlẹ Kwara kii ṣe ipinlẹ mususlumi tabi Kristẹni tori naa ko yẹ ki ijọba fẹ gbe ibọn lati gbe lẹyin tabi ni itako ẹlẹsin kan''
Awuyewuye Hijab ati ọna abayọ
Naijriia nikan kọ ni orileede agbaye ti wahala lilo Hijab fawọn obinrin ẹlẹsin musulumi ti n da awuyewuye silẹ lagbaye.
Ni orileede India, ọrọ yi da họwuhọwu silẹ ni awọn ile ẹkọ to wa ni ipinlẹ Karnataka to si mu kawọn ẹlẹsin Hindu doju ija kọ awọn musulumi nibẹ.
Igbalaaye tabi ikọdi lilo Hijab jẹ nkan tawọn kan n sọ pe ko yẹ ki awọn eeyan maa ja si ṣugbọn lọpọ igba kii ri bẹ.
Labẹ ofin Naijiria, igbalaaye wa fun ẹnikẹni lati ṣe sin to ba wu lai si idiwọ ṣugbọn to ba ti kan ọrọ wiwọ Hijab ni ibiṣẹ tabi ni ile ẹkọ aṣigbọ maa n waye.
Bi a ko ba gbagbe akẹkọọ agbẹjọro kan torukọ rẹ n jẹ Firdaus Amosa gbe ikọ agba awọn agbẹjọro lọ sile ẹjọ to si jare lori ẹtọ rẹ lati lo Hijab pẹlu aṣọ agbẹjọro to ba wọ.
Lọpọ igba awọn eeyan ti n pe fun igbọra ẹni ye lori ọrọ yi lalae fa wahala.
Ibi ti ọrọ ti aṣọ ọlọpaa ati hijabu yi yoo jasi ko ye wa bayi. Oju ree iran ree.

Ìdí rèé tí a fi kéde lílo Hijab àti àwọn ìmúra míràn fún ọlọ́pàá obìnrin Nàìjíríà- Ilééṣé ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, MPAC Nigeria
Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria ti kede imura fawọn agbofinro obinrin nilẹ naa.
Iyipada imura yi jẹ eleyi ti wọn lo wa ni ibamu pẹlu imura awọn ọlọpaa obinrin lagbaye.
Labẹ ilana tuntun yi wọn yoo lanfaani lati wọ yẹti,hijab tabi awọn ibori miran labẹ fila wọn lasiko ti wọn ba wọ aṣọ ibiṣẹ ọlọpaa.
Ọga agba patapata ileeṣẹ ọlọpaa, Usman Alkali Baba, lo ṣe ifilọlẹ imura yi lasiko ipade pẹlu awọn ọga ọlọpaa lọjọ Kẹta oṣu kẹta taa wa ninu rẹ yi.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Adele Alukoro ọlọpaa, Muyiwa Adejobi sọ ninu atẹjade pe igbesẹ yi yoo fun ọlọpaa kọọkan lẹtọ imura to wu lalae fi ẹya tabi ẹsin ṣe,
O tẹsiwaju pe kaakiri agbaye ni wọn ti n ṣamulo iru aṣọ ati imura yi ki awọn eeyan baa le ṣe iṣẹ wọn bo ti se yẹ.
Lara awọn orileede to sọ pe wọn ti n lo iru aṣọ tabi imura bayi ni Canada, ilẹ Amẹrika ,Sweden, Turkey, Australia ati illẹ Gẹẹsi.
Awọn wo ni imura yi wa fun
Muyiwa Adejobi ṣalaye pe imura yi kii ṣe dandan bi kii ṣe pe ki onikaluku mu eleyi to ba rọ lọrun.
O ni ọga ọlọpaa ti wa pa laṣẹ pe ki wọn ri pe wọn tẹle ilana yi lai si iyatọ laarin awọn to ba fẹ ṣe amulo rẹ.
O fi kun pe eleyi yoo jẹ ọna kan gbogi lati faaye gba awọn obinrin pẹlu ibọwọ fun aṣa ati iṣẹṣẹ ibi ti wọn ba ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Aworan oga olopaa Naijiria
Ni Naijiria paapa ati ni awọn orileede mii lagbaye imura fawọn obinrin jẹ nkan tawọn eeyan a maa ran lẹnu.
Yala nidi iṣẹ ọlọpaa ni tabi iṣẹ miran, awọn ajafẹtmọniyan maa n tẹnumọ bo ṣe ṣe pataki lati faaye lẹ fun aṣa ati igbagbọ awọn eeyan nibi iru imura ti wọn ba fẹ.
Ọrọ yi paapa ni orileede Naijiria tawọn musulumi n beere anfani fawọnb obinrin latui lo Hijab jẹ nkan to n fa awuyewuye.
Ki lawọn ẹlẹsin musulumi sọ si igbalaye lati lo Hijab yi
Ẹgbẹ ajafẹtọ awọn musulumi kọọkan ti n gbosuba kare fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lori igbalaye lati lo Hijab ninu imura awọn ọlọpaa obinrin Naijiria.
Ninu atẹjade kan ti alaga Muric ẹka ipinlẹZamfara,Ọjọgbọn Ahmad Galadima fi sita, o ni ohun manigbagbe ni igbesẹ yi jẹ ninu akọsilẹ jija fun ẹtọ obinrin musulumi ni Naijiria.
''Igbesẹ yi jẹ ọna ti awọn olori ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria fi n ṣe agbega fifi aaye gba onikaluku lati ṣe ẹsin rẹ bo ṣe yẹ.A dupẹ pe ọga ọlọpaa tẹti si ipe wa lati mu iyipada yi wa''



















