Kwara Hijab Crisis: Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí wàhálà ìgbà gbogbo lórí híjàbú wíwọ̀ láwọn iléẹ̀kọ́ Kwara?

Oríṣun àwòrán, others
Ọrọ Hijaabu wiwọ ni awọn ileẹkọ ijọba nipinlẹ Kwara tun ti n da wahala silẹ pada.
Lọjọbọ, ija waye laarin awọn obi ati akẹkọọ kan ti wọn se iwọde lọ si ileẹkọ Girama Oyun Baptist Secondary School ni Ijagbo lori pe awọn alasẹ ile ẹkọ naa ko jẹ ki awọn ọmọ wọn to wọ Hijaabu wọ kilaasi.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 1
Ọrọ yi lo di wahala ti ikọlu si waye laarin awọn ọdọ musulumi ati Kristẹni to doju ija kọ ara wọn.
Ni bayi, ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe ki wọn ti ileẹkọ naa pa titi ti alaafiayoo fi pada sibẹ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post, 2
Ijọba Kwara to gbẹnu Kọmisana feto ẹkọ Hajia Sa'adatu Modibo Kawu sọrọ sọ pe awọn bẹnu atẹ lu ikọlu to waye ni Ijagbo yi.
- Àwọn ọmọ ogun America pa olórí ISIS, Ibrahim al-Qurayshi ní Syria
- Buhari tako ọmọ bẹẹrẹ òṣì bẹẹrẹ ní Nàìjíríà, ó ṣàgbékalẹ̀ ètò láti dẹ́kun rẹ̀
- Èèyàn 26 kú nígbà tí wáyà iná já lé wọn lórí láàrin ọjà
- Àsírí èèyàn 96 tó n gbọ́ búkàátà Boko Haram tú sí ìjọba Naijiria lọ́wọ́
- Ọ̀gá àgbà NSCDC dá àwọn ẹ̀ṣọ́ àjọ náà tó wà pẹ̀lú Shina Peller padà
- A kò fi ẹbí Timothy sílẹ̀, à ń gbiyànjú pé kí wọ́n dá ẹjọ́ náà padà sí Osun dípò Abuja ni- Agbẹjọ́rò Adekilekun
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọkùnrin mẹ́rin tó fi olólùfẹ́ ọ̀kan lára wọn ṣe òògùn owó sí ẹ̀wọ̀n
Kini Komiṣọnna sọ lori iṣẹlẹ yii?
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọnna fi sita lỌjọbọ, ijọba sọ pe awọn lawọn ni ile ẹkọ Oyun Baptist Secondary School tori naa nkan to sẹlẹ yi awọn ko faramọ rara.
"Ijọba Kwara fi tọkantọkan koro oju si idẹyẹsi ẹnikankan paap awọn ọmọde nitori ẹsin.A ko ni faramọ iwa yi ni eyikeyi ileesẹ ijọba eleyi ti o ba jẹ ti ijọba''.
Kọmiṣọnna naa tẹsiwaju pe ''Pẹlu bi ijọba ati awọn ajọ rẹ se n jiroro pẹlu awọn olori ẹsin mejeeji, a ti wa pasẹ bayi pe ki wọn ti ile ẹkọ naa pa tti ti ọrọ yi yoo fi lojutu''
''A rọ awọn agbofinro lati se iwadii lori ọrọ yi ki wọn si mu ẹnikẹni to ba lọwọ ninu isẹlẹ yi kawọn eeyan baa le kọgbọn lara rẹ.Ijọba n beere fun alaafia nitori wahala kii so eso rere''.
Ki lawọn ọlọpaa sọ?
Ileesẹ ọlọpaa fi ọrọ sita ninu atẹjade lati ọwọ agbẹnusọ wọn Ajayi Okasanmi pe awọn fẹ fi da araalu Kwara loju pe alaafia ti pada si agbegbe naa.
O ni ''ikọ kogberegbe ati awọn ọlọpaa to wa nilẹ ni ijagbo ti da alaafia pada si agbegbe naa ti wọn si duro digbi la ti ri pe wahala kankan ko waye nibẹ''
Agbofinro se alaye pe ọrọ hijaabu lo da wahala silẹ laarin awọn musulumi ati Kristẹni ti o ti n waye ti pẹ nipinlẹ Kwara.
''Eleyi to kan wa ni ọrọ wahala to bẹ silẹ laarin awọn eeyan ijagbọ ati awọn obi musulumi ti wọn n se iwọde.Wọn pada wa doju ija kọ ara wọn pẹlu ohun ija oloro''
Igba akọkọ kọ ni yi ti iru nkan bayi n waye:
Ni Naijiria,ọrọ wiwọ hijaabu yi ko sẹsẹ maa waye.
Ni ipinlẹ Kwara ni paapa ilu Ilorin, ọrọ yi da wahala silẹ laipẹ eleyi to mu ki ijọba ti awọn ileẹkọ mẹwaa kan ti awọn Kristẹni n se akoso rẹ.
Awọn oludari ile ẹkọ Kristẹni yi sọ pe awọn ko le gba ki wọn maa wọ hijaabu wa si ile ẹkọ awọn nitori o tako ilana ẹsin awọn.
Nigba naa lọhun, Victor Dada to jẹ olori ijọ itẹbọmi sọ pe awọn kọdi awọn akẹkọọ yi lati wọ ile ẹkọ awọn nitori awọn ko faaye gba iru imura bayi
Ni tawọn musulumi, wọn ni ile ẹkọ wọnyi kii se ti awọn Kristẹni bi kii se pe ijọba lo da wọn silẹ.
Nigba ti awọn Kristieni sọ pe awọn lo da awọn ileẹkọ naa silẹ pẹlu owo awọn ọmọ ijọ ki ijọba to gba a lọwọ wọn nigba naa.
Ọrọ naa di ranto ti ikọlu si waye laarin awọn musulumi ati Kristẹni ni ile ẹkọ Baptist to wa ni Surulere.
Ijọba gbe igbesẹ pe ki wọn ti ile ẹkọ naa paa ti wọn si pada wa si lẹyin ti wọn ni ile ẹjọ giga ati kotẹmilọrun ti fun awọn ni akoso ile ẹkọ naa tipẹ.
Alaafia pada sugbọn o da bi ẹni pe ikunsinu yi ko ti tan nilẹ.
Ninu awọn ile ẹkọ ti ijọba lawọn gba pada lọwọ awọn Kristẹni la ti ri.
Cherubim & Seraphim College Sabo Oke
ST. Anthony College, Offa Road
ECWA School, Oja Iya, Surulere
Baptist Secondary School
Bishop Smith Secondary School, Agba Dam.
CAC Secondary School Asa Dam road.
St. Barnabas Secondary School Sabo Oke.
St. John School Maraba.
St. Williams Secondary School Taiwo Isale, ati St. James Secondary School Maraba.
Ni nkan bi ọsẹ to kọja ni wahala tuntun ti ile ẹkọ Baptist Oyun yi bẹrẹ si ni rugbo ko to wa di pe o di ranto.
Ko si sẹyin bi awọn olukọ ti se da awọn akẹkọọ kan pada sile nitori pe wọn lo hijaabu wa si ileẹkọ.
Ọrọ yi di nkan tawọn musulumi kan se fidio ti wọn si ya aworan awọn akẹkọọ yi soju opo ayelujra.
- Ohun tí ó ṣokùnfà ikú Fadlullah Agboluaje, akẹ́kọ̀ọ́ tó kú sí Ukraine ní ọjọ́ kejì tó dé ibẹ̀
- Ìdìtẹ̀gbàjọba tó fẹ́ wáyé ní orílẹ̀-èdè Guinea Bissau, wo ohun tí a lè fìdíẹ̀ múlẹ̀ nípa rẹ̀
- Alukoro JAMB wọ́ Ahmed Isah Brekete lọ síwájú Adájọ, ₦6bn lo n bèèrè lówó gbà má bínú
- Ẹ foríjìnmí, ẹlẹ́ran ara ni mí- Gbajúgbajà adẹ́rìnpòṣónú, Bae_U
- ASUU Fasiti Obafemi Awolowo fárígá, ìyansẹ́lódì tẹ̀síwájú lórí pínpín owó àjemọ́n;ú àwon Olùkọ́
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
Nitori ariwo lori ọrọ yi, ileesẹ eto ẹkọ Kwara kan si ile ẹkọ naa ti wọn si kilọ fawọn olukọ ati alasẹ ileẹkọ naa pe ki wọn maa se doju le akẹkọọ kankan lori wiwọ hijaabu tabi pọn dandan pe ki ọmọ wọ hijaabu tabi fila gẹgẹ bi imura.
Lẹyin ikilọ yi lawọn obi akẹkọọ musulumi naa se iwọde lọ si ile ijọba Kwara pe awọn ile ẹkọ naa ko tẹle asẹ ijọba.
- Abdulsalami ní kò sẹ́ni tó pa MKO Abiola, àìsàn ló pa á, ẹbí Abiola yarí
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti sàfihàn àwọn òníjàgídíjàgán méjìdínlọ́gọ́rùn ún lónìí ní Ado Ekiti
- Àjọ SERAP gbé Ààrẹ Buhari lọ sílé ẹjọ́ nítorì kò wádìí N3B tó pòórá níléèṣẹ̀ ètò ẹ̀náwó
- Wo àwọn ìgbéyàwó tí ayé pariwo wọ́n lọ́dún tó lọ
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
- Ọwọ́ aráàlú ní ètò ìdájọ́ òdodo Nàìjíríà wà, kìí ṣé ọdọ àwọn onímọ̀ ètò ìdájọ́- Osinbajo






















