Boko Haram sponsors: Àsírí èèyàn 96 tó n gbọ́ búkàátà ìgbésùnmọ̀mí ní Naijiria tú sí ìjọba lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ to n ṣe iwadii ọtẹlẹmuyẹ lori owo nina ni Naijiria ti tu aṣiri eeyan mẹrindinlọgọrun to n gbọ bukaata awọn agbesunmọmi.
Aṣiri eeyan okoolenirinwo ati mẹrin (424) to jẹ alatilẹyin ati alajọṣiṣẹpọ awọn olowo naa tun tu.
Minisita fun eto iroyin, Lai Mohammed lo sọ ọrọ yii lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ nipa bi iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari sẹ n gbogun ti iwa ibajẹ ni Ọjọbọ.
O ni iwadii ti ajọ naa ṣe laarin ọdun 2020 si 2021 ni aṣiri naa ti tu.
Mohammed tun ṣalaye pe ajọ naa tun tu aṣiri ileeṣẹ mẹtalelaadoje, ati ileeṣẹ to n ṣe paṣipaarọ owo mẹtalelọgbọn, to ni nkan sẹ e pẹlu igbesunmọmi ni Naijiria.
Ṣugbọn ko darukọ awọn eniyan naa tabi ti ileeṣẹ ti aṣiri wọn tu.
- Ìjọba Kano fẹ̀sùn oníkókó márùn ún kan àwọn afurasí tó pa ọmọ ọdún márùn ún Hanifa
- Ọdaràn làwọn tó ń pè fún ìdìbò dípò 'Restructuring' tí a n béèrè- Iba Gani Adams OPC
- Àwọn agbébọn pa ọgọ́ta èèyàn ní ibùdó ìfiniwọ̀ ní DR Congo
- Oògùn olóró tó lé ní mílíọ̀nù kan la rí gbà lọ́wọ́ àwọn awakọ̀ Onitsha sí Kano- Àjọ NDLEA
- Iná jó oko Obasanjo to wà ní ìpínlẹ Benue, Ẹbọra Òwu bínú, Ortom ni kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ní kíá
Yatọ si eyi, eeyan mẹrindinlọgbọn ni Lai Mohammed tun sọ pe aṣiri wọn tu pe agbesunmọmi ni wọn.
O ni "atupalẹ abọ iwadii ti ajọ naa sẹ lo mu ki ọwọ tẹ eeyan mẹrindinlọgbọn naa ati awọn meje miran to jẹ oluranlọwọ wọn.
"Apapọ eeyan marunlelogoji ti yoo fojuwina igbẹjọ laipẹ.
"Koda, ijọba yoo gba awọn dukia wọn."
O ti pẹ diẹ ti igbesunmọmi ti n gbilẹ ni Naijiria, paapaa ni Ila oorun Ariwa.
Ẹgbẹẹgbẹrun eeyan lo si ti ku ti awọn miran si di alainilelori.












