Oodua Peoples Congress: Ọdaràn làwọn tó ń pè fún ìdìbò dípò 'Restructuring' tí a n béèrè- Iba Gani Adams

Gani Adams

Oríṣun àwòrán, @Iba Gani Adams

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba Gani Adams ti kesi aarẹ Muhammadu Buari lati ri pe o fi iwe ofin miran parọ ti 1999 to wa nilẹ saaju ki idibo ọdun 2023 to waye.

Adari ati agbaọjẹ ilẹ Yoruba yi ni ki aarẹ Buhari mu atunto ba orileede Naijiria ati pe nkan to seese ni ti aarẹ ba fi ọkan si.

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni Ile Ife nibi asekagba ajọdun Oduduwa lọjọ Aje ni o ti fi ọrọ yi lede.

Kini Iba Gani Adams tun so nibẹ?

Iba Gani Adams sọ pe ẹnikẹni to ba n pe fun idio labẹ eto ijọba yi,ọdaran lo yẹ ki wọn pe onitọhun.

O sọ pe ''atunse iwe ofin Naijria gbọdọ waye saaju idibo ọdun 2023.Mi o ni sọ pe ki idibo ma waye ni 2023 sugbọn o se pataki ti a ba fẹ tẹsiwaju gẹgẹ bi orileede, ki a se atunto si agbegbe''

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

''Bi a ko ba se eleyi, mo nigbagbọ pe ẹnikẹni ti a ba yan sipo, ko ni ri nkankan se labẹ eto taa n tẹle yi.Bi a ba dibo wọle fun , yoo maa sojo lati fọwọ kan iwe ofin.Buhari n palẹmọ bayii, asiko diẹ lo wa fun lati tun eto yi se kuro nibi to wa bayii.''

Àkọlé fídíò, Alhaji Shanko

Gani Adams wa kesi awọn ile asofin ati alẹnulọrọ lati mu iyipada ba iwe ofin si ti ẹda ọdun 1960 ati 1963 ki Naijiria baa le ni ilọsiwaju.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Lakotan, Gani Adams kesi Ooni Ile Ife Oba Adeyeye Ogunwusi pe ki o ba awọn Gomina ipinlẹ kaarọ o jiire lati ya ọjọ sọtọ fayajọ ayẹyẹ Oduduwa to jẹ babanla awọn Yoruba.