Rotimi Amaechi: Ìdádúró yóò wà lórí àwọn ṣíṣe ọ̀nà ojú irin bí China kò ṣe ya Nàìjíríà lówó mọ́

Rotimi Ameachi

Oríṣun àwòrán, @Ameachi Rotimi

Ìdádúró yóò wà lórí àwọn ṣíṣe ọ̀nà ojú irin bí China kò ṣe ya Nàìjíríà lówó mọ́ - Amaechi

Ìjọba àpapọ̀ ti di ẹ̀bi ìdádúró àwọn àkànṣe iṣẹ́ kan tó fi mọ́ àwọn ọ̀nà ojú irin látàrí àìsí owó.

Mínísítà fétò ìrìnnà, Rotimi Amaechi nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ṣàlàyé pé orílẹ̀ èdè China kò yá Nàìjíríà lówó mọ́ láti fi ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́.

Amaechi ní àwọn tì ń wá ẹ̀yàwó lọ sí ilẹ̀ Yúròòpù láti fi parí àwọn iṣẹ́ tó ti ń lọ lọ́wọ́.

Bákan náà ló ní iṣẹ́ ń lọ lọ́wọ́ lórí ọ̀nà ojú irin Abuja sí Itakpe tí yóò so mọ́ ọ̀nà ojú irin Itakpe sí Delta.

Àkọlé fídíò, Ipaniyan Ogun

Kini idi ti iṣẹ naa ko ṣe tii pari di asiko yii?

Ó ní iṣẹ́ náà kò bá ti parí bí kò bá ṣe àìgbọ́raẹni yé tó wáyé pẹ̀lú agbaṣẹ́ṣe tó ń ṣiṣẹ́ náà ṣùgbọ́n ó ní ní kété tó bá ti ní ìyanjú ni iṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ padà lẹ́yẹ ò sọkà.

Àkọlé fídíò, Alhaji Shanko

Amaechi fi ìgbàgbọ́ hàn pé àkànṣe iṣẹ́ yìí yóò mú lílọ bíbọ̀, títà àti rírà láàárín Abuja àti ẹkùn àjìndo Gúúsù orílẹ̀ èdè yìí rọrùn sí i.

Ó tẹ̀síwájú pé iṣẹ́ kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ọ̀nà ojú irin Eko sí Calabar àti ti Port Harcourt sí Maiduguri tí yóò ná wọn ní bílíọ̀nù mọ́kànlá Dọ́là.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

Kini Ameachi sọ lori pe ko gbe iṣẹ akanṣẹ si apa ẹkun re?

Bákan náà ló bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn tó ń sọ wí pé òun kò gbé àkànṣe iṣẹ́ kankan sí ẹkùn rẹ̀ pé kí wọ́n fi ẹlẹ́yàmẹ̀yà sílẹ̀.

Ó wá rọ àwọn gómìnà àti àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti gbájúmọ́ ṣíṣe àwọn ọ̀nà orí ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìwé òfin ṣe gbe kalẹ̀ bí i ojúṣe wọn.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Amaechi fi kun pé ojúṣe ìjọba àpàpọ̀ ni láti fi ètò lélẹ̀ tí àwọn gómìnà yóò tẹ̀lẹ́ lórí ṣíṣe ọ̀nà.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní olú ìlú ilẹ̀ wa, Abuja ló ń ṣiṣẹ́ lórí ọ̀nà jú irin tó so àwọn ìpínlẹ̀ pọ̀ mọ́ Abuja èyí tí wọ́n ṣe àfilọ́lẹ̀ lọ́dún tó kọjá, tí òun kò sì le sọ ohunkóhun lórí ohun tí ó fàá tí kò ì tíì parí.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ