Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi: Ààrẹ Muhammadu Buhari yẹ lẹ́ni tó yẹ ká gbé òṣùbà fún lórí àwọn ohun améyérọrùn - Oluwo

Oba Akanbi Teller gboriyin fun Aare Muhammadu Buhari
Oluwo ti Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti gbóríyìn fún Ààrẹ Muhammadu Buhari fún iṣẹ́ takuntakun tó ń ṣe nídìí ìgbóguntako ìwà àjẹbánu àti ṣíṣe àwọn ohun améyérọrùn ní orílẹ̀ èdè yìí.
Ọba Akanbi ní Ààrẹ Buhari nìkan ni adarí tó jẹ́ olóòótọ́ tó gbógunti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti ìgbà tí Nàìjíríà ti wà.
"Mi ò mọ̀ wí pé mo le rí ọkọ̀ ojú irin ìgbàlódé àti ṣíṣe àtúnṣe òpópónà Eko sí Ibadan. Mi ò le gbàgbé Ààrẹ Buhari".
- Ọmọ Nàíjíríà, ẹ yé yan àwọn ‘Grandpa’ ní ààrẹ, ẹ wá ọlọ́gbọ́n ọ̀dọ́ tó tún sán-an-gun - Seyi Makinde
- Ọwọ́ aráàlú ní ètò ìdájọ́ òdodo Nàìjíríà wà, kìí ṣé ọdọ àwọn onímọ̀ ètò ìdájọ́- Osinbajo
- Àjọ SERAP gbé Ààrẹ Buhari lọ sílé ẹjọ́ nítorì kò wádìí N3B tó pòórá níléèṣẹ̀ ètò ẹ̀náwó
- Abdulsalami ní kò sẹ́ni tó pa MKO Abiola, àìsàn ló pa á, ẹbí Abiola yarí
- Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bí wọ́n ṣe rí Abba Kyari, Obi Cubana níbi ìgbéyàwò ọmọ ọ̀gá ọlọ́pàá Alkali Baba
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
Oluwo ti Iwo bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn ìjọba tó ti kọjá fún bí àwọn ohun améyérọrùn ṣe di ní orílẹ̀ èdè yìí, bí ó ṣe ní kò sí ìjọba tó tíì ṣe tó Ààrẹ Buhari lórí mímú ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà.
Oluwo fi kun pé gbogbo àwọn ọ̀nà tó so àwọn ìpínlẹ̀ ma ara wọn tó ti jẹ́ pípatì láti ọjọ́ pípẹ́ ni Ààrẹ ti parí.
Kini Oluwo tun sọ?
Bákan náà ló ṣàlàyé pe láti ìgbà tí ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Ibadan ti gba ẹ̀mí bàbá òun àti àwọn ohun tí òun máa ń rí ní ilẹ̀ òkèrè ló máa ń wu òun láti ní olórí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá àwọn ohun améyérọrùn.
Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ alukoro rẹ̀, Alli Ibraheem, Oluwo ní "fún ìgbà àkọ́kọ́ láti bí ogún ọdún sẹ́yìn, èèyàn le wakọ̀ láàárìn Eko sí Ibadan láìpé wákàtí kan, láìsí súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀".
Oluwo ni: "Olóòótọ̀ ènìyàn nikan ló le ṣe èyí láì ní rí ìdíwọ́ àwọn alágbára tó ń jẹun ibẹ̀.
"Mo fẹ́ kí àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà máa sọ nípa dáadáa àwọn olórí wa, kó má jẹ̀ẹ́ aburú wọn nìkan wọ́n má sọ."
Bẹ́ẹ̀ náà ló rọ àwọn olórí mìíràn láti máa wo àwòkọ́ṣe Ààrẹ Buhari, bó ṣe pé fún àtìlẹyìn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fún ìjọba.


















