Yemi Osibanjo pàrokò ìkìlọ̀ ránṣẹ́ s'áwọn amofin àti adájọ́, ka ohun tó sọ

Oríṣun àwòrán, @Yemi Osinbajo
Igbakeji aarẹ orileede Naijiria, Yemi Osinbajo ti kesi awọn onimọ ẹka idajọ lati se agbega ẹka idajọ Naijiria.
O fi ọrọ yi lede lasiko to n kopa nibi ayẹyẹ apejẹ ẹgbẹ awọn agbaọjẹ amofin ti won n pe ni: Body of Senior Advocates of Nigeria to waye nilu Eko.
Lasiko apejẹ yi, igbakeji aarẹ Osinbajo tẹnumọ pataki isẹ awọn amofin ati ipa ti wọn n ko nipa atunse awọn aisede lawujọ ati idagbasoke ilu.
''O ni eto idajọ wa dabi alumọni,kii se ti awọn to wa lẹka yi,kii se tawọn agbẹjọro tabi adajọ,ara ilu lo ni''
- Ṣé lóòtọ́ ni Bimpe Oyebade lóyún fún Lateef Adedimeji?
- Wo bí ìrìnàjò ìfẹ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ láàrin Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade
- Wo àwòrán ayẹyẹ ìgbéyàwó láàrín Lateef Adedimeji àti Adebimpe Oyebade
- Ìrìn-àjò ìfẹ́ wa kò tíì bẹ̀rẹ̀ nígbà tí mó ní Lateef Adedimeji kìí ṣe ọ̀rẹ́kùnrin mi- Mo’Bimpe
- Wo ohun tí ọkọ àti ìyàwó, Lateef Adedimeji àti Bimpe fi síta fúnra wọn to fihàn pé ọjọ́ ti súnmọ́
- Ẹ wo nkan tí àwọn akẹẹgbẹ́ Lateef Adedimeji sọ nípa f'ọ́tò ìgbéyàwó òun àti Adebimpe tó jáde
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
- Kí ló mú omijé jáde lójú Lateef Adedimeji?
Kini Osinbajo tun so?
Ojogbon Yemi Osinbajo tun ni: 'Wọn n sanwo fun wa lati pese isẹ ti iwe ofin Naijiria gbe kalẹ nipa yiyanu aawọ ati mimu idajọ wa.
Alamojuto ni wa, awa kọ la nii. Igbakigba ti eto yi ko ba sisẹ bo ti se tọ tabi bo se yẹ,o tunmọ si pe a ti kuna lojuse wa.
Ojuse wa ni lati se atunse ti nkan ba ti dẹnukọlẹ''
Bakan naa ni igbakeji aarẹ sọ pe ọna kan lati se idagbasoke eto idajọ Naijiria ni ki wọn mu agbega ba eto ẹkọ ẹka imọ ofin ki awọn to n bọ lẹyin baa le ri nkan dimu lọjọ iwaju.
"Gbogbo awa taa joko nibi loni la mọ nkan ti ko se deede pẹlu ẹka idajọ wa loni.Itan n kesi wa lati ri pe a se atunse rẹ''













