Anambra Mortuary Fire: Àwọn ẹbí bú sẹ́kún nígbà tí wọn kò rí òkú èèyàn wọn gbé lọ sin

Oríṣun àwòrán, Citizen Televison Nigeria
Awọn Yoruba maa n gbadura pe ki Eleduwa jẹ ki a fi ọwọ rọri ku.
Awọn oku to le ni irinwo ni ina ti jo bayii ni mọṣuari ile iwosan ijọba to wa niluu Onitsha nipinlẹ Anambra.
Ina ọhun ni a gbọ pe o jo fun wakati mẹta ni mọṣuari ile iwosan ọhun to wa lẹyin ile iwosan naa.
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ pásítọ̀ tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìyá àti ọmọ méjì
- "Á lọ yíká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti bèèrè fún ìdáǹdè Sunday Igboho"
- Omijé lójú, ọ̀rọ̀ ìdárò àti orin èpè ní ọ̀dọ́ Eruwa fi dárò ikú bí Timothy Adegoke ti yóò wọ ilẹ̀ sùn lónìí
- Ọmọ Nàíjíríà, ẹ yé yan àwọn ‘Grandpa’ ní ààrẹ, ẹ wá ọlọ́gbọ́n ọ̀dọ́ tó tún sán-an-gun - Seyi Makinde
- Òjòwú-bìnrin fi ẹ̀rọ ìlọṣọ gbígbónà jó ọkọ ní abẹ́ àti ojú láti ojú oorun, ó sì gba ibẹ̀ kú
- Dókítà àti Nọ́ọ̀sì di atọrọjẹ torí àjẹsílẹ̀ owọ oṣù mẹ́jọ
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
Ki lo ṣokunfa ina to jo mọṣuari?
Ohun ti a gbọ ni pe igbo to wa lẹyin mọṣuari ile iwosan yii ni ina ti ṣẹyọ ti o si ran mọ mọṣuari naa.
A tun gbọ wi pe awọn oṣiṣẹ mọṣuari ọhun gbiyanju lati pa ina naa pẹlu omi ati ọsẹ.
Ṣugbọn wọn ni lati ranṣẹ pe awọn panapana lẹyin ti ina ọhun burẹkẹ sii.
Awọn kan ni a gbọ pe wọn san oko to wa lẹyin mọṣuari naa ti wọn si fi ina sii ki ina ọhun to ran mọ mọṣuari.

Oríṣun àwòrán, Chimezie Akpota/Faceboook
Kinni awọn ẹbi to gbe oku si mọṣuari sọ?
Niṣe lawọn ẹbi to wa gbe oku eeyan wọn ni mọṣuari bu sẹkun lẹyin tawọn oku ti jona raurau.
Ọpọ ninu wọn lo wa gbe oku ti wọn gbe si mọṣuari lati le sin in ṣugbọn wọn o ri oku ti wọn maa gbe lọ sile.
Ọkan lara wọn to ba awọn akọroyin sọrọ, Charles Ozor, ṣalaye pe ọrọ naa ti daru mawọn loju lẹyin tawọn oku ti jona di eeru.
O ni awọn eeyan maa reti awọn lati gbe oku pada de tawọn ba n bọ.
Alakoso mọṣuari sọrọ lori iṣẹlẹ ina to jo nibẹ
Alakoso mọṣuari naa to pe orukọ ara rẹ ni Emma sọ pe oun lọ si Awka lati lọ awọn oku kan wa nigba ti iṣẹlẹ naa waye.
Nibẹ ni wọn ti pe mi lori ago pe ina ti n jo mọṣuari.
Lẹsẹkẹsẹ naa ni mo kuro ni Awka ti mo bẹrẹ si ni sare pada, ṣugbọn ki n to pada de, nkan ti bajẹ.
Emma ni ''ati oku tutu ati gbigbẹ ni ina jo ninu mọṣuari.
O ṣeeṣe ko jẹ pe kẹmika ti a maa n fi itọju awọn oku lo ṣe okunfa iṣẹlẹ ina ọhun tori kẹmika naa maa n gbana bi epo bẹntiro ni.
Kinni ọga awọn panapana sọ lori iṣẹlẹ ọhun?
Ọga ileeṣẹ panapana ipinlẹ Anambra, Ọgbẹni Martin Agbili to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe lootọọ ni ina to jo mọṣuari ọhun wa lati inu igbo to wa lẹyin ile iwosan naa.
O ṣalaye pe ileeṣẹ panapana ti rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati san igbo to ba wa layika ile wọn.
Ọgbẹni Martin ni ''a tun kilọ fun wọn pe ki wọn ye dana sun igbo tori lasiko ọyẹ ni a wa yii, ina le ṣẹyọ nibi kibi.
Awọn to gbiyanju lati pa ina ọhun fara ṣeṣe amọ ko si ẹni kankan to ku.''













