Ogun sex romp: Pásítọ̀ tó ṣe aṣemáṣe pẹ̀lú ìyá àti ọmọ méjì kó sí gbaga ọlọ́pàá

Ọkunrin ati Obinrin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yoruba ni ẹni ti a ba gbe oju oku le, yẹ ko jọ ẹni agba, igi ti a ba si fi ẹyin ti, yẹ ko gba ni duro lai fi ni lẹyin janlẹ.

Amọ eyi ko ri bẹ fun iya kan ati ọmọbinrin rẹ meji, ti wọn fi gbogbo ọkan wọn tan ojisẹ Ọlọrun kan amọ ti abamọ gbẹ yin ọrọ fun wọn.

Gẹgẹ bi atẹjade ti ile iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun fisita, ọwọ ofin ti mu pasitọ ijọ kan ni adugbo Olumore, niluu Abeokuta, Timothy Oluwatimilehin.

Ileesẹ ọlọpaa ni lori itanjẹ ati Ibalopọ pẹlu iyawo ile ati ọmọbinrin rẹ meji ni awọn mu pasitọ naa fun.

Pasitọ to n ba iya ati ọmọ se asemase

Oríṣun àwòrán, Ogun State Police

Ọkọ iyawo lo figbe ta pe Pasitọ lo ọgbọn ẹwẹ lati tan iyawo oun atawọn ọmọ jẹ ni:

Iroyin sọ pe pasitọ naa gba obinrin yii at'awọn ọmọ rẹ mejeeji sile rẹ nibi ti o ti ba gbogbo wọn ni Ibalopọ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyemi lo fọrọ yii lede fawọn akọroyin.

Ọgbẹni Oyeyemi sọ pe awọn agbofinro mu pasitọ yii lẹyin ti ọkọ rẹ mu ẹjọ rẹ wa si agọ ọlọpaa ni Adatan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkọ obinrin naa wa fi ẹjọ sun pẹlu oṣiṣẹ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn obinrin.

Oyeyemi ni ọkunrin naa salaye pe pasitọ yii fi ọgbọn tan iyawo oun ati ọmọbinrin awọn meji lọ si ile rẹ nibi ti o ti n b'awọn sun.

Lẹyin naa ni DPO agọ ọlọpaa Adatan, SP Abiodun Salau ni k'awọn ọlọpaa lọ mu pasitọ naa.

Àkọlé fídíò, Recycle Tyres: Wo bí wọ́n ṣe fi àlòkù táyà ṣe bàtà, ẹní onírọ́bà, táìsì àtí ẹ̀ṣọ́ ilé míì

Ki ni awijare Pasitọ?

Lẹyin ìfọrọwánilénuwò, pasitọ bẹrẹ si ni ka boro boro pe lootọọ ni oun b'awọn ni Ibalopọ, amọ, o tọrọ aforijin.

Pasitọ ọhun ni ede-aiyede to wa laarin obinrin naa ati ọkọ rẹ loun lo, lati tan an lọ sile oun nibi toun ti ni Ibalopọ pẹlu rẹ at'awọn ọmọ meji.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹjọ naa ti de ọdọ ajọ to n ṣewadi awọn ọdaràn to niṣe pẹlu iwa ipa s'awọn ọmọde fun iwadii kikun pẹlu erongba lati gbe ọkunrin naa lọ sile ẹjọ.