Timothy Adegoke: Ẹkún sọ níbi ètò ìsìnkú Timothy Adegoke nílùú Eruwa

Eto isinku Timothy Adegoke ti waye nilu ile ijọsin kan niluu Eruwa, ni ipinlẹ Oyo laarọ ọjọ Satide.
Ọpọ awọn araalu, ẹbi, ara, ọrẹ ati mọlẹbi lo peju sibi eto isinku ọhun, ti gbobgo wọn si n wa ẹkun mu lasiko ti isin naa n lọ lọwọ.
Awọn mọlẹbi rẹ wọ aṣọ dudu, pẹlu fila ti wọn kọ akọle "Justice for Timothy" si lara.
- Bí ìsìn alẹ́ onígbàgbọ́ ṣe ń wáyé fún ìsìnkú Timothy Adegoke, mọ̀lẹ́bí tẹ́wọ́ gba òkú rẹ̀
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- "Á lọ yíká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti bèèrè fún ìdáǹdè Sunday Igboho"
- Àwọn ọmọbìnrin oníwọ́kuwọ́ ló mú kí ń yẹ̀bá nídìí iṣẹ́ tíátà
- Abdulsalami ní kò sẹ́ni tó pa MKO Abiola, àìsàn ló pa á, ẹbí Abiola yarí
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
Pẹlu Musulumi ati Kristiẹni ni wọn jọjọ ṣadura fun oloogbe ọhun lasiko eto isinku naa.
Awọn Musulumi lo kọkọ ṣadura ki awọn alufaa to ṣe adura, ti wọn si tun kọ orin iyin pẹlu.
Alufaa to waasu nibi eto isinku naa sọ pe Ọlọrun mọ si ohun to ṣẹlẹ si Timothy Adegoke.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
O ni "Timothy ti ku nitootọ amọ awọn ọmọ rẹ ṣi wa... awọn ọmọ rẹ yoo ju baba wọn lagbara Ọlọrun."
"O ṣenu laanu pe ni Naijiria, a ko naani ẹmi eniyan mọ, amọ gbogbo ọna ni a fi n wa owo kiri."
"Ẹni to ba n ṣe rere ko maa ṣe lọ, ẹni to n ṣe ika ko mura sii, onikalauku lo maa jere iṣẹ ọwọ rẹ... ẹnikẹni to ba lọwọ ninu iku Timothy yoo jere ẹṣẹ rẹ."1
Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ilu Eruwa ki wọn ma sọkun mọ.
O ni "Ẹyin eeyan ilu Eruwa, ẹ ma sọkun mọ, mo fẹ ki ẹ mọ pe ẹlẹṣẹ ko ni lọ lai jiya ẹṣẹ rẹ."
"Bi Naijiria ko ba sọ ododo, Ọlọrun yoo ṣe idajọ ododo... Ẹ jọwọ, ẹyin eeyan ilu Eruwa, ijọ Ọlọrun, ẹyin ẹbi, ẹ tọju awọn ọmọ oloogbe, awọn ọmọ yii yoo diru digba."
Pasitọ ọhun pari iwaasu rẹ pe "Ko si ẹni ti ko ni ku, nitori naa, ẹ jẹ ki a wa ni imura silẹ fun iku."
Ohun to kan lẹyin eto isinku ninu ṣọọṣi
Lẹyin ti wọn ba pari eto insiku ninu ṣọọṣi yii ni wọn yoo lọ si iboju ti wọn yoo sin oloogbe naa si ni ilu Eruwa yii kan naa.
Ṣaaju ni awọn araalu ọhun, to fi mọ awọn ẹbi ati ọrọ oloogbe naa ti kọkọ ṣe ifẹhomuhan lọjọ Ẹti, nibi ti wọn ti n pe fun idajọ odo lori iku rẹ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Oloye Rahman Adedoyin to ni ile itura Hilton ti Timothy ku si ni Ile Ife lọdun 2021 ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa pẹlu awọn mẹfa mii.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii ṣi n lọ lọwọ.
Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?
Omijé lójú, ọ̀rọ̀ ìdárò àti orin èpè ní ọ̀dọ́ Eruwa fi dárò ikú bí Timothy Adegoke ti yóò wọ ilẹ̀ sùn lónìí

Arakunrin Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti OAU to ku si ile itura Hilton hotel ni Ile Ife yoo wọ ilẹ sun lonii lẹyin oṣu mẹta ti iṣẹlẹ ọhun waye.
Pẹlu omije loju lawọn ẹbi, ara ati ọrẹ Timothy ti fi n beere iadọ ododo lori iku rẹ lati igba ti ọrọ naa ti ṣẹlẹ.
Timothy jade laye leyin ti o lo ṣe idanwo MBA ni fasiti Obafemi Awolowo ti Ile Ife ti o gba yara si Ile itura Hilton hotel.
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Àlàyé rèé lórí àìsàn tó ṣe mi fọ́dún mẹ́jọ tí mo fi rù kan eegun - Ogogo
- Ta ni Abiodun Oyebamiji tí APC dìbò yàn bí olùdíje gómìnà l'Ekiti
- Òǹkọ̀wé kan dèrò àtìmọ́lé torí ó bú Ààrẹ lórí ayélujára
- Sanwo-Olu kède iye tí àwọn aráàlú yóò máa wọ ọkọ̀ ojú irin ayára bí àṣá tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ́ rà
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
Ni ana ode yi ni awọn mọlẹbi oloogbe naa tẹwọ gba oku rẹ ti wọn si gbe lọ ilu Eruwa nibi ti a bi arakunrin naa si.Ọpọlọpọ awọn ọmọ ilu naa ni o jade lati ba mọlẹbi Timothy kẹdun ti wọn si parapọ lati ṣe Alẹ Abẹla titan fun ẹni wọn to ku.

Bawo ni idaro iwọde naa se lọ si?
Nibi ti wọn ti n tan abẹla naa ni wọn ti pe fun idajo ododo lori iku arakunrin naa.
Obitibiti eeyan lo jade lati kopa ninu eto abẹla titan ọhun.
Se ni omije n bọ loju awọn ọdọ to n se iwọde naa, ti wọn si n kọ orin epe fun gbogbo awọn eeyan to lọwọ ninu iku Timothy.
Koda, ṣe ni wọn n fi ina abẹla jo aworan ẹni to ni ile itura ti Timothy ku si, Ọmọba Ramon Adedoyin.
Adedoyin ni awọn eeyan ilu Eruwa ati ọpọ eeyan gbagbọ pe o lọwọ ninu iku aitọjọ Timothy.Timothy fi baba, iya, ẹgbon, iyawo, ọmọ mẹta ati aburo si aye lọ.

Bi Timothy Adegoke ṣe jade laye lairotẹlẹ:
Timothy Adegoke la gbọ pe o de si ile itura Hilton lati Abuja lọjọ Kaarun oṣu Kọkanla ti o si fẹ sun sibẹ ki o baa le ribi kopa ninu idanwo ẹka ileẹkọ OAU ti yoo waye lọjọ keji.
Lọjọ Keje Oṣu Kọkanla ni wọn kede pe Adegoke ti di awati lẹyin ti iyawo ati awọn mọlẹbi rẹ ko gburo rẹ mọ.
Lẹyin tawọn mọlẹbi fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa Edun Abon Police, wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka to n ṣe iwadii iwa ọdaran iyẹn State Criminal Investigation Department lọjọ Kẹsan oṣu Kọkanla.
Abalọ ababọ, ọlọpaa lawọn ri oku Adegoke ninu saare kan ti wọn sin in si ti wọn si ti gbe oku naa lọ fun ayẹwo lati mọ ohun to ṣeku pa.
Bakan naa wọn lawọn ti mu eeyan mẹfa kan tawọn fura si pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.
Ọlọpaa ni iwadii ṣi n tẹsiwaju ati pe awọn n fi ọrọ wa Ramon Adegoke Atobatele Adedoyin lẹnu lati mọ ohun to ṣẹlẹ gaan.
Ileeṣẹ ọlọpaa Osun mu oludari ile itura Hilton ti Timothy Adegoke ku si
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti kede pe awọn ti mu alaga ati oludasilẹ ile itura Hilton Hotel and Resort, Ile-Ife, Ramon Adegoke Atobatele Adedoyin.
Eyi ko si ṣẹyin iwadii ti wọn lawọn n ṣe lori iku akẹkọọ fasiti Obafemi Awolowo, OAU, Timothy Adegoke ti wọn ni o de si ile itura Hilton ko to ṣaadede poora.
Ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa Opalola Yemisi fi ṣọwọ si BBC, o ni ṣaaju ki awọn to mu Adedoyin, awọn ti mu eeyan mẹfa kan ti awọn fura si pe wọn mọ si iku akẹkọọ yii.
Ramon Adedoyin ti ọlọpaa mu lori iku Timothy Adegoke gba ileẹjọ lọ, ohun ti ile ẹjọ sọ ree
Oloye Ramon Adegoke Adedoyin to jẹ ọkan lara awọn afurasi ti ọlpaa mu si ahamọ lori iku akẹkọọ fasiti Obafẹmi Awolowọ, OAU ni ile Ifẹ tawọn eeyan kan pa si ileetura Hilton nilu Ile ifẹ ti gba ile ẹjọ giga apapọ kan lọ nilu Abuja lati beere fun beeli.
Ninu ẹjọ ti oloye Adedoyin pe labẹ ẹtọ ọmọniyan, agba oye ilu ile Ifẹ naa rọ ile ẹjọ giga apap naa lati paṣẹ ki ọlọpaa tu oun silẹ kuro ni ahamọ wọn naa titi di igba ti wọn yoo fi pari iwadii ti wọn n ṣe.
Oloye Adedoyin tun beere fun anfani lati ri itọju iwosan to wu u titi di igba ti awọn lọpaa yoo fi pari iwadii wọn lori iṣẹlẹ naa. Gẹgẹ bi ara awọn ohun to fi han ile ẹjọ, o ni oun ni aisan ẹjọ riru ati itọ ṣuga.
Oloye Adedoyin ti wa lahamọ awọn agbofinro fun ọsẹ diẹ bayii, lati ọjọ karundinlogun oṣu kọkanla ọdun 2021 lẹyin ti iroyi lu si igboye aye pe arakunrin Timothy Adegoke ko agbako awọn apanijaye kan lasiko to fi wa nileetura Hilton to jẹ ti oloye Adedoyin.

















