Timothy Adegoke: Mọ̀lẹ́bí sọ ìdí tí wọn ṣe fẹ́ sin olóògbé

Ikede isinku Timoth Adegoke

Oríṣun àwòrán, Olugbade Adegoke

Awọn mọlẹbi Timothy Adegoke, akẹkọọ fasiti OAU to ku sile itura Hilton ni Ile Ife ti tẹwọ gba oku rẹ lọwọ ijọba lọna ati sin.

Wọn gbe oku Adegoke fun awọn ẹbi rẹ ni ile ẹkọṣẹ iṣegun LAUTECH to wa niluu Osogbo, ki wọn to gbe oku naa lọ si ilu Eruewa ni ipinlẹ Oyo, nibi ti yoo ti wọ kaa ilẹ sun.

Iroyin ni alẹ ọjọ Ẹti ni wọn yoo ṣe isin aṣalẹ onigbagbọ fun, nigba ti wọn yoo sin oku naa lọjọ Abamẹta, iyẹn ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2022 yii.

Adegoke dagbere faye lẹyin to padanu ọpọlọpọ ẹjẹ nile itura ọhun loru ọjọ to wọ sibẹ.

Olugbade Adegoke, to jẹ ẹgbọn oloogbe naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe gbogbo eto lo ti wa nilẹ lati sin oku rẹ.

Timothy Adegoke

Oríṣun àwòrán, ads4nairablog

O ni "Gbogbo ohun to yẹ ni a ti ṣe lati sin oku aburo mi, a si ti kede bi eto isinku naa yoo ṣe lọ fun gbogbo ọmọ Naijiria."

Ṣaaju ni oku naa ti kọkọ wa ni faisiti LAUTECH, niluu osogbo fun ọpọlọpọ ọjọ nitori iwadii ti ileeṣẹ ọlọpaa n ṣe lori rẹ.

Ẹgbọn oloogbe naa ṣalaye siwaju si pe "A ti ri pe wọn ko nilo oku rẹ mọ ninu iwadii ti ọlọpaa n ṣe... nitori naa a ṣe pinnu lati gbe oku naa kuro nile igbokupamọsi to wa ni LAUTECH lati lọ sin."

Ibi ti ọlọpaa ba iwadii wọn de:

Rahmon Adedoyin to ni ile itura Hiton ti Timothy ku si, atawọn mẹfa mii ṣi wa ni ahamọ ọlọpaa lori isẹlẹ ọhun.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ko tii fi esi ayẹwo oku oloogbe naa ti wọn ṣe lọjọ kẹjọ, oṣu Kejila, ọdun 2021 lede.Timothy Adegoke yóò wọ ilẹ̀ sùn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, bí ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe lọ rèé

Bakan naa ni agbẹjọro afurasi ti sọ pe irọ ni awọn iroyin to n lọ nigboro lori esi ayẹwo oku naa, ati fidio CCTV kan ti awọn iroyin kan sọ pe o ṣafihan bi afurasi to jẹ onibara rẹ ati ọmọ rẹ ṣe gbẹmi oloogbe ọhun.

Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa ti ni awọn ko ni fi nnkankan pamọ nipa ohun ti oju awọn ba to nipa iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ

Ki lo ti wayelori isẹlẹ naa tẹlẹ:

Timothy Adegoke ni akẹkọọ to n gboye kun oye ni fasiti Obafemi Awolowo nilu Ile Ife amọ to ku sile itura Hilton nilu naa lasiko to fẹ lọ se idanwo.

Awọn ẹbi Adegoke lo figbe ta fun ileesẹ ọlọpaa pe awọn ko gburo ọkunrin naa lati igba to ti de si Ile Ife, ti iwadii si bẹrẹ lọgan lati mọ bo se poora.

Awọn osisẹ ile itura Hilton naa, to jẹ ti gbajumọ kan ni Ile Ife, Ọmọọba Rahmon Adedoyin, sẹ fun awọn ọlọpaa pe ọkunrin naa ko wa sile itura ọhun.

Amọ iwadii nipa bo se sanwo ile itura naa lati banki rẹ ni ori foonu rẹ tu asiri pe ile itura naa lo sun si, ti awọn osisẹ si pada jẹ wọ pe o wa sọdọ awọn nile itura ọhun amọ o ti ku.

Wọn mu awọn ọlọpaa lọ sibi ti wọn sin oku Timothy naa si, ti wọn si ko awọn osisẹ naa ati ẹni to ni ile itura ọhun, Ọmọọba Rahmon Adedoyin.

Bakan naa ni awọn osisẹ ọhun ni ọmọ Raheem, tii se ọmọkunrin Rahmon Adedoyin gan lo lewaju awọn lati sin oloogbe naa, ti onitọun si ti salọ.

Ileesẹ ọlọpaa ti wa kede pe awọn n wa Raheem Adedoyin ọhun, ko le wa sọ ohun to mọ nipa iku Timothy Adegoke.

Isẹlẹ yii ka ọpọ ọmọ Naijiria lara, ti wọn si fẹ mọ ibi ti igi ọrọ naa yoo wo si, eyi si lo mu ki ọga ọlọpaa ilẹ wa kede pe ki wọn maa ko gbogbo awọn afurasi nidi isẹlẹ naa wa si olu ileesẹ ọlọpaa ni Abuja.

Awọn afurasi naa si ti n jẹjọ niwaju ile ẹjọ giga ilu Abuja.