Ekiti APC Primary: Abiodun Oyebamiji ni APC dìbò yàn gẹ́gẹ́bí olùdíje fún ipò gómìnà l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Facebook/Biodun Oyebanji
Eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ Ekiti ti pari.
Abiodun Oyebanji si ni oludije to jawe olubori fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ naa.
Oyebamiji ni ibo ẹgbẹrun mọkanlelọgọrun ati ẹẹdẹgbẹrin o le mẹta, (101703) lati bori ero idibo yiyan oludije fun ipo gomina naa eleyi to ti fa ọpọlọpọ awuyewuye.
Awọn oludije meje ti kọkọ fariga pe awọn ko ni kopa ninu eto idibo naa ayafi ti wọn ba wọgile eto ọhun ki wọn si mojuto awọn ẹhonu wọn gbogbo.
- Òǹkọ̀wé kan dèrò àtìmọ́lé torí ó bú Ààrẹ lórí ayélujára
- Deji Akure tó lu aya rẹ̀ lójú títì, tí wọn rọ̀ lóyé, ti jáde láyé
- Ẹ̀yín àgbà Yorùbá, ẹ dìde yanjú aáwọ̀ òṣèlú láàrin Tinubu àti Osinbajo, bíbẹ̀ẹ́kọ́... - Ajulo
- Wo ohun tí ìjọba Oyo ṣe fún ẹni tí ọlọ́pàá SARS lù fọ́ lójú lẹ́yìn àbọ̀ ìgbìmọ̀ EndSARS
- Ìdìbò abẹ́nú sípò gómìnà ẹgbẹ́ òsèlú PDP l'Ekiti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu
- Ìdìbò láti yan olùdíje APC fún ipò gómìnà l'Ekiti ń parí lọ, àmọ́...
- Bisi Kolawole, àyànfẹ Fayose ni olùdíje PDP fún ipò gómìnà l’Ekiti

Bi esi ibo naa ṣe lọ niyi:
Iye awọn ọmọ ẹgbẹ APC ni ipinlẹ Ekiti -183,560
Iye awọn to ṣe ayẹwo lati dibo- 107877
Iye awọn to dibo- 104983
Iye ibo ti awọn oludije kọọkan gba
Bamidele Faparusi - 376
Kayode Ojo- 767
Michael Ọpẹyẹmi Bamidele- 760
Adeyeye - 691
Olufemi Bamiṣile- 400
Abiodun Oyebamiji- 101, 703

Biodun Oyebanji,Kọmiṣana, olukọ fasiti tẹlẹ to fẹ ṣe Gomina bayii:
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe laipẹ yi pẹlu ileeṣẹ iroyin This Day,Biodun Oyebanji sọ pe ohun to wu oun ni ki Gomina Kayode Fayemi ṣatilẹyin fun un ninu idibo Gomina.
Ni bayi to ti wa jaweolubori gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ oṣelu APC ninu idibo Gomina, ala naa ti n sunmọ imuṣẹ bọ diẹdiẹ.
Ṣaaju ko to du ipo yi, Biodun Oyebanji ti di ipo Kọmisana mu nipinlẹ Ekiti to si tun ṣe akọwe agba si ijọba ipinlẹ Ekiti.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Biodun Oyebanji
Gẹgẹ bo ti ṣe sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo taa n wi yi, o ni ''mo ti wa ni ijọba fun ọdun mọkanla ninu ọdun mẹẹdọgbọn ti a le sọ pe wọn ti da ipinlẹ Ekiti silẹ''
Labẹ ijọba Gomina Kayode Fayemi, Biodun Oyebanji ti baa ṣiṣẹ pọ ni saa meji to lo lori oye ni ipadabọ rẹ gẹgẹ bi Gomina ipinlẹ Ekiti.
Bi eeyan ba wo eleyi, o jọ pe ọrọ tawọn oludije iyoku n sọ pe ayanfẹ Gomina Fayemi ni Oyebanji fẹ jọ bi ootọ botilẹ jẹ pe Gomina Fayemi ko ti figba kan polongo fun.
Ki ni awọn oludije yoku n sọ nipa esi idibo yi
Ohun ti wọn sọ ṣaaju ati lasiko idibo naa to waye lỌjọbọ ni a le fidi rẹ mulẹ.
Ninu awọn oludije mẹjọ fun ipo yi labẹ asia APC awọn meje sọ pe awọn ko le kopa ninu eto idibo naaa nitori o ni ọwọ madaru ninu.
Wọn fẹsun kan awọn eleto idibo naa ti ijọba yan lati ba awọn eleyi to wa lati olu ileeṣẹ ẹgbẹ ni Abuja pe wọn n gbe lẹyin Biodun Oyebanji.
Ọrọ yi kawọn lara debi pe awọn alatilẹyin wọn ṣe iwọde ifẹhonuhan si olu ileeṣẹ ẹgbẹ APC ni Ekiti ti wọn si sọ pe eto idibo naa ko le yanrantin fun idi eyi.
Bayi ti idbo ti pari ti wọn si ti kede Oyebanji gẹgẹ bi oludije, a o maa reti boya awọn oludije yoku yoo gbaruku ti tabi wọn yoo kọri si iwaju igbimọ ti yoo gbẹjọ ẹhonu lori idibo naa.
O ku sọwọ igbimọ ẹhonu esi idibo-Oyebanji
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ile rẹ to wa ni Ikogosi Biodun Oyebanji sọ pe inuoun dun si eto idibo naa.
O gbosuba kare fun Gomina Mohammed Badaru ipinlẹ Jigawa to dari eto naa to si ni idibo naa ko ni aayẹ gẹgẹ bi awọn akẹgbẹ rẹ to ku ti ṣe ọ.

O ni igbimọ kotẹmilọrun APC ni o wa ku sọwọ wọn bayi lati gbọ eyikeyi ikunsinu tawọn eeyan le ni lori eto idibo naa.
''Ilana ẹgbẹ wa faaye silẹ fawọn to ba fẹ pẹjọ kotẹmilọrun.Wn ni ẹtọ lori ero wọn ṣugbọn ẹgbẹ ni yoo sọ ibi ti ọrọ yoo ja si''


















