Ekiti PDP Primary: Lẹ́yìn wàhálà tó kọ́kọ́ bẹ́ sílẹ̀, ìdìbò abẹnú sípò gómìnà ẹgbẹ́ òsèlú PDP l'Ekiti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu

Ekiti PDP Primary

Eto idibo lati yan oludije ẹgbẹ oṣelu PDP fun idibo gomina to n bọ nipinlẹ Ekiti ti n lọ lọwọ nilu Ekiti.

Awọn aṣoju kaakri awọn ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ si nii dibo fun oludije ti wọn fẹ bayii.

Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Emmanuel Udom lo n lewaju iko oludibo tawọn adari gbe kalẹ.

Awọn oludije meje lo bẹrẹ idije naa ki obinrin kan ṣoṣo to wa ninu wọn, Sẹnetọ Abiọdun Olujimi to binu yọwọ kuro ninu rẹ.

Ekiti PDP Primary

Olujinmi fẹsun kan awọn alakoso ibo naa pe wọn dẹyẹsi awọn aṣoju lati ijọba ibilẹ wọn.

Ekiti PDP Primary

Awọn aṣoju naa n to lọwọwọ lati dibo wọn nigba ti awon alamojuto idibo naa ba ti pe orukọ ijọba ibilẹ to ba kan.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Mo tí yọwọ́ nínú ìdíje sípò gómìnà l'Ekiti, torí ìyanjẹ́ pé mo jẹ́ obìnrin - Abiodun Olujinmi

Awọn asoju to wọya ija

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP to n dije fun ipo gomina nipinlẹ Ekiti, Sẹnetọ Abiodun Olujinmi ti kede pe oun ti yọwọ yọsẹ ninu idije naa.

Olujinmi lo fidi ọrọ yii mulẹ fun ikọ iroyin BBC Yoruba to wa nibi idibo abẹnu ẹgbẹ PDP ni Ekiti eyi to wa lati fa oludije gomina kalẹ ti yoo soju ẹgbẹ oselu naa losu Kẹfa ti ibo gomina yoo waye.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Sẹnetọ Olujimi ni iyalẹnu lo jẹ fun oun pe awọn aṣoju to wa lati ijọba ibilẹ oun ni wọn n yọ bi ẹni yọ jiga.

Alaye ree lori idi ti Olujinmi fi yọwọ ninu idije sipo gomina labẹ ẹgbẹ PDP:

Lasiko to n ba BBC sọrọ, Olujinmi ni igbesẹ ọhun waye labẹ akanṣe eto ayẹwo asoju ti wọn pe ni automatic delegate, ti wọn si fi awọn aṣoju ijọba ibilẹ awọn oludije yooku silẹ ni pipe.

O ni oun ti fi iwe ẹhonu silẹ fun igbimọ naa labẹ gomina Emmanuel Udom tipinlẹ Delta ti oun si ti sọ fun wọn pe oun ko ṣe mọ.

Olujinmi ni kii se pe oun yẹba kuro ninu idije naa lati ju ọwọ silẹ fun Oloye Segun Oni, tii se oludije miran ninu ibo abẹnu naa.

Sẹnetọ naa fikun pe iyanjẹ nla ti ẹgbẹ oselu naa se fun oun lo mu ki oun pinnu lati yọwọ ninu idije sipo gomina naa.

Awọn asoju

"Mo ti sọ fun alaga igbimọ to n se kokari eto idibo abẹnu naa, eyiun gomina Emmanuel Udoh pe n ko dije mọ.

Idi ni pe se ni wọn se adinku iye awọn asoju to y ki n ko wa sibi idibo abẹnu naa.

Ninu asoju mejilelaadọrin to kan mi, se ni wọn sọ pe asoju mejila pere ni ki n ko wa nijba ibilẹ naa.

Lapapọ ninu asoju marundinlaadọsan to yẹ ko ti ọdọ mi wa, mọkanlelọgọfa pere ni wọn gba pe ki n ko wa.

Awọn oludije yoku ni gbogbo asoju to yẹ ki wọn ko wa pe perepere lai din ẹyọ kan soso, ti temi nikan ni wọn din ku.

Ta lo le gba iru rẹ, eyi si fihan pe wọn ko fẹ mi ninu idije naa ni, boya nitori pe mo jẹ obinrin."

Awọn asoju to wọya ija

Wahala ranpẹ bẹ silẹ nibudo ayẹwo orukọ awọn asoju:

Wayi o, se ni ede aiyede waye lasiko ayẹwo orukọ awọn asoju ti yoo dibo nibi ibo abẹnu ẹgbẹ oselu PDP to n waye ni Ekiti.

Wahala naa bẹrẹ nigba ti ọkan lara awọn aṣoju fariga lori ọrọ iwe orukọ awọn oludije.

Se ni awọn asoju naa n ti ara wọn sihin -sọhun, ti wọn si n fa ara wọn ni asọ, koda se ni wọn yọ ọwọ si ara wọn nigba ti ọrọ naa gbona tan.

Ọpẹlọpẹ awọn agbofinro to wa nibi ibo abẹnu naa ni ko jẹ ki aawọn naa fọnna soju.

Awọn eekan ẹgbẹ PDP

Ko ni si arumọjẹ ninu ibo abẹnu to n waye ni Ekiti - Awọn alasẹ PDP

Ọgbẹni Kabir Bappa Jauro, to ba awọn aṣoju lati ijọba ibilẹ kọọkan sọrọ fi da wọn loju pe ko ni si arumọjẹ kankan ni idibo naa ati pe ẹni ti awọn ọmọ ẹgbẹ ba n fẹ nipa ibo wọn ni yoo jade gẹgẹbi oludije.

Bakan naa lo gbe ilana ti eto ayẹwo naa yoo ba jade kalẹ pẹlu arọwa si won kati rii pe alaafia jọba lasiko idibo naa.

Ẹwẹ, Gomina Udom ti gunlẹ si ibudo ayẹwo orukọ awọn asoju ti yoo dibo fun Oludije gomina ipinlẹ Ekiti lẹgbẹ oṣelu PDP.

Gomina Udom ni Alaga igbimọ to n ṣe kokaari eto idibo lati yan oludije fun ipo gomina Ekiti labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.

Lara awọn eekan to ti wa nikalẹ naa ni igbakeji gomina ipinlẹ Ọsun nigba kan ri, Erelu Oluṣọla Ọbada.