Ogun Insecurity: Kí ló mú kí wọn dáná sun oríadé àti èèyàn mẹ́ta míì?

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olaayinde Odetola
Oriade kan ni ilu Agodo ati awọn ọrẹ rẹ mẹta ti kagbako iku gbigbona lọwọ awọn janduku kan to dana sunwọn.
Iṣẹlẹ yi waye ni ilu Agodo lẹba Papalanto ni ijọba ibilẹ Ewekoro ni ipinlẹ Ogun.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun Abimbola Oyeyemi lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn akọroyin.
- Àwọn ọmọ ogun ti dìtẹ̀gbàjọba ni Burkina Faso
- Ìwádìí rèé lórí fídíò tó ṣàfihàn bí agbébọn ṣe tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò
- Ìjọba Kano gbẹ́sẹ̀lé ìwé àṣẹ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ aládàni lẹ́yìn ikú ọmọdébìnrin Hanifa Abubakar
- Agbébọn tú alápatà mẹ́ta tí wọ́n jí gbé sílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n gba ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó
- Àwọn ajínigbé pa Pásítọ̀ kan, jí obìrin kan, ọmọ rẹ̀ mẹ́rin gbé lọ
Gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ Alagodo ilu Agodo, Oba Ayinde Odetola ati awọn ọrẹ rẹ mẹta lawọn janduku yi ṣe ikọlu si ti wọn si dana sun wọn.
Inu ọkọ wọn ni ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe wọn pa awọn mẹtẹẹta wọnyi si lẹyin ti wọn dari sinu ilu ni nkan bi ago mkanla owurọ ọjọ Aje
A tun gbọ pe ẹgbọn Oba ti wọn pa yi,Oloye Adenike Akintade sọ pe awọn afurasi to pa ọba Ayinde Odetola naa lo pa aburo rẹ laipẹ yi.
Ṣe lootọ ni ọrọ yi ni ṣe pẹlu ọrọ oye Ọba jijẹ?
Lẹnu nkan taa ri kojọ lori iṣẹlẹ yi, o dabi ẹni pe ọrọ iku Oba yi ati awọn eeyan mẹta mii ninkan ṣe pẹlu ọrọ oye jijẹ.
Gẹgẹ baa ti ṣe gbọ, laipẹ yi ni wahala bẹrẹ lyin ti Alake ilu Ẹgba,Oba Micheal Gbadebo fi Ayinde Odetola jẹ ọba lagbegbe to wa labẹ akoso Owu.
Awọn araalu la gbọ pe wọn tako iyansipo rẹ yi pe awọn tawn jẹ eeyan Owu ko le gba ki eeyan Ake wa jẹ Ọba le awọn lori.
Bi a ba wo ọrọ ti ẹgbọn Oba to ku yi sọ fun akọrọyin Punch o jọ pe alaye yi le fẹsẹ mulẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olaayinde Odetola
O ni ''Wọn ṣẹṣẹ ni ki n maa lọ sile nile iwosan ti mo ti n gba itọju ni afi bi mo si ṣe gbọ nipa iku aburo mi ni nkan bi ago mọkanla owurọ''
''Oba Odetola padanu aburo rẹ kan laipẹ yi lori wahala yi.Awọn janduku kan ni wọn ṣaa pa.Loni Kabiesi ko si laye mọ. O ma ṣe o''
Kini Ileeṣẹ ọlọpaa wa sọ nipa iṣẹlẹ yi?
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun Abimbola Oyeyemi to fidi ọrọ yi mulẹ s fun Punch pe awọn se abẹwo si ilu Agodo.
O lawọn kọwọrin pẹlu oluranlọwọ lori ọrọ aabo si Gomina Dapo Abiodun, Ọgbẹni Olusola Subair ati Kọmisana ọlọpaa Lanre Bankole.
Wahala oye jijẹ a maa da wahala silẹ lawọnmm agbegbe kan nilẹ Yoruba ṣugbọn a ko ti ri akọsilẹ iru eleyi ti wọn wa dana sun ọba nitori oye jijẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/razaq.olafuyi.9
Alukoro ọlọpaa ni paroparo ni ilu da nigba tawọn de ibẹ.
O fi kun pe Kọmisana ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ.
Lori iye eeyan to ba iṣẹlẹ naa lọ, o ṣalaye pe eeyan kan ṣoṣo lawọn ri ti wọn dana sun.''A ko mọ boya Ọba ni tabi kii ṣe Oba ni wọn dana sun''
















