Armed Men Stripping Students Naked: Kìí ṣe Nàíjíríà ni wọn ti tú àkẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò

Awọn akẹkọọ ati agbebọn

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ẹnu ọjọ mẹta yii ni fidio kan bẹrẹ si n ja lori ayelujara, nibi ti awọn agbebọn kan ti n fi tipatikuku mu awọn akekọọ kan bọ ara wọn si ihoho.

Awọn akẹkọọ naa ko ju bii ọmọ ọdun mẹtaa lọ, wọn si wọ aṣọ alawọ buluu to jẹ ti ile ẹkọ wọn.

Inu oṣu kinni ti a wa yii naa ni iṣẹlẹ naa waye, ọpọ eeyan si ti n pin fọran naa lori ayelujara, paapaa lori ikanni atẹjiṣẹ WhatsApp.

Awọn to n pin fidio ọhun n fi atẹjiṣẹ si pe awọn akẹkọọ kan ni ipinlẹ Kebbi, ni Naijiria lo wa ninu fidio ọhun lẹyin ti wọn ko sọwọ awọn agbebọn.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ipinlẹ Kebbi ni iṣẹlẹ naa ti waye, lawọn mii n sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ orilẹede mii ni.

Awọn wo lo wa ninu fidio naaati pe nibo ni iṣẹlẹ naa ti waye?

Iwadii ileeṣẹ iroyi BBC ti fi han pe orilẹ-ede Cameroon ni iṣẹlẹ naa ti waye, lodi si iroyin to n lọ lori ikanni WhatsApp pe ipinlẹ Kebbi ni Naijiria ni.

Gunmen stripping students naked

Bo tilẹ jẹ pe a ko le darukọ awọn akẹkọọ naa, ile ẹkọ girama Government High School, to wa ni Buea, ni iha Guusu Iwo-oorun Cameroon ni wọn ti n kawe.

Ayẹwo iwadii BBC tun fi han pe awọn agbebọn naa lo ya fidio ọhun.

Lara awọn ede ti wọn sọ ninu fọnran naa ni ede Pidgin, to jẹ ede to gbajumọ ni Naijiria, Cameroon atawọn orillẹ-ede mii ni Afrika.

Àkọlé fídíò, Zazzu Portable: Èmi ni mo ni Zazzu Zeh, orúkọ mi ló wà níbẹ̀ àmọ́ wọ́n fẹ́ gbá mi

Nibo ni ilu Buea wa?

Buea jẹ ilu kan lapa Guusu Iwọ-oorun Cameroon, o si jẹ ilu kan ti awọn ọmọ ẹgbẹ alatako atawọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi n da laamu lati igba pipẹ wa.

Awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọ naa jẹ ti iha awọn ọmọ Cameroon ti wọn n sọ ede Gẹẹsi, ti wọn si n fẹ iyapa kuro lara awọn to n sọ ede French ni Cameroon.

Lara awọn ọna ti awọn ọmọ ẹgbẹ naa fi n ja fun ominira ni bi wọn ṣe n kọlu awọn ile ẹkọ atawọn ile iṣẹ ni Cameroon.

Lọdun 2020, awọn ẹgbẹ naa kọlu ile ẹkọ Mother Francisca International Bilingual Academy, niluu Kumba, nibi ti wọn ṣekupa akẹkọọ meje, ti awọn mii si farapa yanayana.

Iroyin ni ẹgbẹ naa ti kọkọ gbiyanju lati doju idije Afcon to n lọ lọwọ ni Cameroon bolẹ.

Ilu Buea ati Limbe wa lara awọn ilu ti ifẹsẹwọnṣe Afcon to n lọ lọwọ ti waye.

Àkọlé fídíò, Wo ọmọ tó kọ̀ láti sin òkú ìyá rẹ̀ fún ọdún mẹ́wàá àti ìdí tó fi kọ̀ bẹ́ẹ̀