Prison Congestion: Ìdí rè é tí Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Ogun fí ṣíjú àánú wo ẹlẹ́wọ̀n 20

Abawọle ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, Others

Adajọ agba ipinlẹ Ogun ti tu awọn ẹlẹwọn ogun kan silẹ gẹgẹ bi ọna ati mu adinku ba iye awọn to wa ni ọgba ẹwọn nipinlẹ naa.

Adajọ agba Mosunmola DIpeolu fi ọrọ yi lede lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ọfisi ẹka idajọ ipinlẹ naa ni Abeokuta.

O ṣalaye pe kaakiri ẹkun idibọ mẹtẹẹta ipinlẹ naa lawọn ti mu awọn ẹlẹwọn yi ati pe igbesẹ naa di dandan lati mu adinkun ba awọn ọgba ẹwọn to kun fọfọ.

O sọ pe mẹwaa gba itusilẹ ni Abeokuta, meji ni Ijẹbu Ode, Meje lati Ilaaro ti eeyan kan si gba itusilẹ ni ọgba ẹwọn Sagamu.

Dipo awọn ọgba ẹwọn ti wn ti maa n se eto ijiroro lori ẹka idajọ ati ipo awọn ọgba ẹwọn, Coovid-19 ko faaye gba wọn ti wn si lo ọfisi ile ẹjọ giga ipinlẹ naa.

Adajọ Dipeolu sọ pe awọn yoo tun ṣe iru eto bẹẹ lẹyin oṣu mẹrin.

Àkọlé fídíò, Oyo Jailbreak: Wo ọṣẹ́ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n Abolongo ṣe fáwọn ará Oyo àti bí wọn ṣe rí wọn mú

Adajọ wa kilọ fawọn ẹlẹwọn to gba itusilẹ lati yi iwa pada to si ni inu oun dun si pe awọn eeyan n gbe ẹjọ wa siwaju ile ẹjọ.

''Awọn eeyan n gbe ẹjọ wa nitori pe wọn ti mọ ẹtọ wọn lab ofin.

Idi ree t'awa naa n fi n safiku awọn adajọ niwọn iba ti agbara ijọba ipinlẹ ṣe ka''

Bakan naa la n tẹramọ eto idanilẹkọ fawọn araalu nitori idajọ pipẹ, irẹsi lo maa n mu ba ọkan eeyan''

Àkọlé fídíò, Wo ọmọ tó kọ̀ láti sin òkú ìyá rẹ̀ fún ọdún mẹ́wàá àti ìdí tó fi kọ̀ bẹ́ẹ̀

Ipenija eto idajọ Naijiria ko ṣẹṣẹ bẹrẹ

Ipinlẹ Ogun nikan kọ lo n koju ipenija ọrọ ọgba ẹwọn to kun lakunfaya.

Kaakiri Naijiria lọpọ awọn ẹlẹwọn ko ti maa ri eto idajọ gba ni kiakia to si mu ki ẹlomiran pẹ lẹwọn ju bo ti ṣe yẹ lọ.

Pupọ awọn to jẹ ẹlẹwọn ti wọn da ẹjọ iku fun ni wọn ṣi wa lẹwọn nitori awọn Gomina kii fẹ buwọlu iwe ki wọn lọ pa awọn ọdaran wọn yi.

Laipẹ yi ni Minisita feto aabo labẹle Rauf Aregbesola fawọn ileeṣẹ ọgba ẹwọn laṣẹ pe ki wọn maa yinbọn pa ẹnikẹni to ba ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn.

Idi ni pe awọn janduku kan a maa ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn lati tu awọn akẹgbẹ wọn silẹ ti wọn a si maa pa awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn lasiko ikọluyi.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Ọna kan gbogi tawọn onwoye sọ pe wọn le rojutu ọr yi ni ki ẹka eto idajọ maa tete ṣe ẹjọ awọn ti wọn ba gbe wa si ile ẹjọ.

Eleyi ni wọn ni yoo mu adinku ba awọn to pọ biba ni ẹwọn to n duro de idajọ.

Àkọlé fídíò, Kaun