Aminu Bukar Jigawa: Ọ̀mọ ọdún mẹ́ta tí wọ́n ń wá ni wọ́n ti rí òkú rẹ̀ ní kìlómítà kan sí ìlú wọn

Oríṣun àwòrán, @NPF
Àjọ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Jigawa tí ṣàwárí òkú ọmọ ọdún mẹ́ta tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Aminu Bukar, tí wọ́n ti ń wá láti ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kìíní, ọdún 2022 ní ìjọba ìbílẹ̀ Guri ní Ìpínlẹ̀ náà.
Agbenusọ àjọ ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Jigawa, Lawan Shiisu jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta ní ọjọ́ Ẹtì, ní ìlú Dutse.
Shiisu ni bàbá ọmọ náà, Alhaji Bukar ti ṣaájú fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá pé àwọn ń wá ọmọ náà láti nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ní abúlé Dolen Zugu ni ọjọ́ náà.
- Jonathan the tortoise: Wo ìjàpá tó pé ọdún 190, òun ni ẹranko tó dàgbà jùlọ láyé
- Tí Obasanjọ bá fi PDP sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ PDP kò lè kúrò lára rẹ- Iyorchia Ayu. Alágá PDP
- Ẹ̀tànjẹ lásán ni ètò ààbò tí Tinubu ní yóò dára tí òun bá di ààrẹ Naijiria - Afenifere
- Obìnrin kan dèrò àtìmọ́lé fún ẹ̀sùn wíwẹ ọmọ rẹ̀ lómi gbígbóná nítorí kọ́kọ́rọ́
- Ọlọ́pàá dá àwọn èrò tó fẹ́ dáná sun iléẹ̀kọ́ Hanifa dúró, ìjọba Kano gbé iléẹ̀kọ́ náà tì pa
- Njẹ́ o mọ nípa ògẹ̀dẹ̀ tuntun tó lè bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lágbàyé?
Shiisu ṣàlàyé pé nígbà tí àwọn ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ náà ni wọ́n rí òkú ọmọ ọ̀hún nínú igbó Tudun Mai Jambo, èyí tí kò ju kìlómítà kan lọ sí ìlú náà.
Shiisu ní lọ́gán ni wọ́n gbe e dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn níbi tí àwọn dókítà ti kéde ikú ọmọ náà.
Nibo ni iwadii de duro?
Shiisu fi kún ìwádìí àwọn ko ṣàfihàn bóyá ejò lọ́wọ́ nínú lórí ikú Aminu.
Ó ní òkú Aminu ni àwọn ti gbé lé àwọn òbí rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún un.














