Justice for Hanifa: Buhari àtàwọn ọmọ Nàìjíríà míràn banújẹ́ lórí ikú Hanifa ti olùkọ rẹ̀ pa ní Kano

hanifa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lori ọrọ Hanifa to jẹ ọmọ ọdun marun un ti awọn oniṣẹ ibi seku pa ni ipinlẹ Kano naa ni ọrọ ti n ba ọrọ bọ si.

Gbogbo bi ọrọ yii ṣe ti bẹrẹ naa ni BBC ti n mu u wa fun un yin titi ti ọwọ fi tẹ awọn afurasi ti ọkan ninu wọn jẹ olukọ Hanifa Abubakar ti wọn pa lẹyin ti wọn gba owo itanran millionu mefa lọwọ Obi rẹ ki wọn to pa a. Ẹ̀yin Òbí Hanifa, ẹ gba kádàrá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó dùn mi yìí- Muhammadu Buhari

Ibi ti ọrọ de duro bayii ni pe awọn olugbẹ Kano ti fariga lori iku Hanifa ni eyi ti ọpọ ọmọ Naijiria ti n pariwo lori ayelujara pẹlu #Justice for Hanifa lori ayelujara.

Awọn Olugbe ilu Kano gbiyanju lati dan sun ile ẹ̀kọ́ Hanifa

Awọn ọlọpaa ni ilu Kano ni ariwa Naijiria sa ipa wọn lati ma jẹ ki erongba awọn ara ilu kan waye nibẹ

Eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe fẹ dana sun ileẹ̀kọ́ North West Preparatory School tó n jẹ Noble Kids School nibi ti wọn ti ri oku ọmọdebinrin Hanifa ti awọn oniṣẹ ibi pa.

Noble Kids yii lo wa ni agbegbe Kwanar Dakata nijoba ibile Nasarawa ni ipinlẹ Kano.

Bi awọn ero to n binu yii ṣe n gbiyanju lati dan sun ibẹ ni awọn agbofinro naa si da wọn lẹkun pe ori bibẹ kọ ni oogun ori fifọ.

Àkọlé fídíò, Tọktaya afọju ti Eledua tun fi ibeji ta lọrẹ

Ijọba ipinlẹ Kano gbe ileẹ̀kọ́ ti wọn ti ba oku Hanifa ti pa:

Nibi ọrọ de duro bayii ni pe ijọba ipinlẹ Kano ti dide si ọrọ iku Hanifa yii.

Ijoba ti paṣẹ pe ki ileẹkọ Noble Kids naa di titi pa bayii ni agbegbe Kwanra Dakata nijoba ibile Nasarawa ni ipinle Kano.

Akowe agba fun igbimọ awọn ile aladani ni Kano. Asoju Musa Kawu so fun awon olugbe Kano pe igbimo naa yoo fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro ninu iṣẹ iwadii wọn.

Àkọlé fídíò, Buga Jesse

Musa Kawu ni won yoo geb igbimo kan dide lati se iwadii nipa bi awon ile ẹkọ aladani ati arannnilọwọ ṣe n ṣe lasiko yii.

Ọpọ awọn eeyan lo n beere fun idajo kopẹkopẹ si Abdulmalik Mohammed Tanko ti wọn fẹsun kan pe o pa Hanifa.

Hanifa

Oríṣun àwòrán, @family

Ẹ̀yin Òbí Hanifa, ẹ gba kádàrá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó dùn mi yìí- Muhammadu Buhari

Aarẹ Muhammadu Buhari naa ti darapọ mọ awọn ọmọ Naijiria to n fọnmu lori ayelujara lori ọrọ omodebinrin Hanifa ti awọn oniṣẹ ibi pa ni Kano.

Leyin naa ni awọn ajinigbe kan n beere fun owo itanran ni eyi ti awọn ẹbi rẹ si san

Leyin o reyin ni wọn ba oku Hanifa ninu ọgba ile ẹkọ rẹ ni Kano.

Eyi si ti bi ibinu awọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye lori ayelujara ni eyi ti won fi n beere fun idajo ododo lori Hanifa pe #Justice for Hanifa bayii.

Kini Aarẹ Buhari sọ?

Bashir Ahmed to jẹ oluranlọwọ fun Aare Buhari lori eto ifitonileti lori ayelujara naa fi soju opo twitter re pe:

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

O ni Aarẹ Buhari ba ẹbi Hanifa kẹdun lorukọ Naijiria.

Hanifa

Oríṣun àwòrán, StateHouse/ family

Bakan naa lo tun parowa fun awọn agbofinro lati ṣiṣẹ won bi iṣẹ nile ẹjọ lori awọn afurasi ti ọwọ ti kan lori ẹsun ipaniyan naa.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Hanifa

Oríṣun àwòrán, Hanifa

Wo bí ọlọ́pàá ṣe rí òkú ọmọ ọdún márùn-ún tí wọ́n ní olùkọ́ rẹ̀ jígbé

Inu ibanujẹ ni awọn to n gbe ni agbegbe Kawaji, nipinlẹ Kano wa bayii lẹyin ti wọn ri oku ọmọ ọdun marun un, Hanifa Abubakar ti awọn kan ji gbe lọjọ kẹrin, oṣu Kejila, ọdun 2021.

Ibatan Hanifa, Suraju Sulaiman, sọ fun BBC pe ọ̀fọ̀ nla lo jẹ nigba ti awọn ri oku ọmọde naa ninu ile kan nile ẹkọ to n lọ.

"A ri oku rẹ nibi ti wọn sin in si ninu ile ẹkọ to n lọ."

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna sọ pe awọn ti mu afurasi mẹta to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa.

Afurasi akọkọ ni olukọ ile ẹkọ ti ọmọ naa n lọ.

Olopaa naa ni pe: "Lẹyin to ji i gbe tan, o gbe e lọ si ile rẹ nibi to ti lo ọsẹ meji.

Sugbọn bo ṣe kẹẹfin pe iwadii ti fẹ sun kan an, lo fun ọmọ naa ni majele jẹ, eyi to ṣeku pa a."

Wo bí ọlọ́pàá ṣe rí òkú ọmọ ọdún márùn-ún tí wọ́n ní olùkọ́ rẹ̀ jígbé

Àkọlé fídíò, Kaun

Owo Itanran n kọ?

Agbẹnusọ ọlọpaa, Haruna sọ pe "ko to o pa Hanifa, lo ti kọkọ pe ẹbi rẹ, to si beere fun miliọnu mẹfa Naira gẹgẹ bi owo itusilẹ rẹ.

Wọn san owo naa fun un. Ṣugbọn o pada pa ọmọ naa.

"Lẹyin to pa a lo pe awọn afurasi meji yooku pe ki wọn o ba a sin oku rẹ sinu iboji kotopo ti wọn gbẹ sinu ọgba ile ẹkọ."

Hanifa

Oríṣun àwòrán, @family

Bawo ni ijinigbe Hanifa ṣe waye?

Ibatan ọmọde naa, Ogbẹni Suraju sọ fun BBC pe Hanifa ma n lọ si ile ẹkọ Keu kan, Dahiru Bauchi Islamic School, ti ko jina si ile wọn.

Oun ati awọn ọmọde yooku ni adugbo si lo jọ ma n lọ, ti wọn tun jọ ma n pada sile awọn obi kaluku wọn.

Àkọlé fídíò, Ẹlẹ́wọ̀n: Ọgbà ẹ̀wọ̀n ni mo ti kàwé yege ní ìdánwò Jamb

Suraju sọ pe: "Ni ọjọ Satide, ọjọ kẹrun, oṣu Kejila, ọdun 2021, bi wọn ṣe jade ile Keu ni aago marun-un irọlẹ.

Nigba ti wọn si n pada sile ni ọkunrin kan to wa kẹkẹ ẹlẹsẹmẹrin (Keke Napep) sọ fun awọn ọmọde marun-un naa pe ki wọn wọle ki oun le gbe wọn de ile wọn.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe làlùyọ pẹ̀lú ìpèníjà ara tí èmi náà ń lọ ọ́fíìsì gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ìjọba - Raymond Adegoke

Ibatan naa ni: "Gbogbo wọn ba wọle sinu kẹkẹ rẹ. Bo ṣe wọ inu adgbo wa lo ja awọn mẹrin silẹ, to si sọ fun wọn pe oun fẹ ẹ gbe Hanifa rin kaakiri diẹ ki oun to o gbe pada.

Lati igba naa ni Hanifa ti di awati."

Igbese wo ni ẹ̀bi ti gbe?

Arakunrin Suraju sọ pe lẹyin iṣẹlẹ naa ni awọn ara adugbo ṣẹṣẹ sọrọ pe awọn maa n ri ọkunrin onikẹkẹ kan ti oju rẹ jẹ ajoji ninu adugbo naa lati bi ọsẹ kan ṣaaju iṣẹlẹ ijinigbe.

Ẹẹmeji si ni wọn ti beere ọrọ lọwọ rẹ pe taa lo n wa ni adugbo, nitori pe o le gbe kẹkẹ rẹ silẹ nigba mii, ti yoo si joko.

Àkọlé fídíò, 'Mo sọ fún Dókítà pé èmi ò lè gé ọyàn mi, pé ṣọ́ọ̀ṣì yóò fi àdúrà ṣẹ́gun àìsàn jẹjẹrẹ ọmú mi'

Lẹyin naa ni wọn sọ fun un pe ko gbọdọ wa si adugbo naa mọ.

Ati pe Oun si ni wọn fura si.

"Nkan to ba ni ninu jẹ ni pe ko si eyikeyi awọn ọmọde naa to ranti oju ọkunrin onikẹkẹ Napep ọhun mọ."