Hope Uzodinma and David Umahi: Ṣé lóòtọ́ ni gómìnà ìpínlẹ̀ Abia àti Imo wọ àṣo àsíá Biafra bí o ṣe jáde lórí ayélujára?

Gomina

Awọn ajijagbara Biafra ni wọn ṣe olupin awọn ẹda aworan Umahi ati Uzodinma ninu kootu alawọ pupa, dudu ati ewe eyi to jẹ asia Biafra.

Lori itakun twitter bakan naa ni eni kan ti takoto aworan naa si afẹfẹ to si kọ sibẹ wipe "ẹ jeki a fọn rere aworan yìí, ni kete ti Umahi ba ri, o máa daku nitori awọn eya hausa Fulani o le gbagbọ wipe wọn ti dọgbọn si aworan naa

Gbajugbaja adari awon ajijangbara Biafra lórí itakun abanidore Facebook ti fi awọn aworan kan ti o je ti gomina meji sọwọ sori itakun Facebook rẹ pẹlu ibeere wipe njẹ awọn ọkunrin wọnyii ni ẹjẹ Biafra ninu wọn bi.

Àkọlé fídíò, Eba

Awon gomina mejeeji ni wọn je ọmọ egbe oṣelu oloṣuṣu ọwọ ( APC ) to n ṣ'akoso awọn ipinlẹ meji lara awọn ipinlẹ marun lẹkun ila oorun gusu orileede Naijiria.

David Umahi darapo mo egbe APC lati inu egbe oselu PDP loṣu kejila ọdun 2020 lati inu ẹgbẹ oselu PDP.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Bẹẹ naa ni Uzodinma jawe olubori di gomina ipinlẹ Imo loṣu kinni ọdun 2020 latari ipinnu ile ẹjọ to ga julọ to sọ wipe Emeka Ihedioha kọ lo gbe'gbaoroke idije ibo gomina.

Awon gomina mejeeji ni eebu wọn n jẹyọ ninu awọn gbolohun ipolongo ikọ to n pe fun idasilẹ olominira Biafra.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Gomina Umahi lo ti bu enu ate lu iko naa nita gbangba ati awọn adawole rẹ nita gbangba ni paapa ipe re lati yapa ila oorun gusu kuro lara orileede Naijiria.

Lẹnu lọọlo yii, o kede re wipe ipinle t'oun, iyen Ebonyi ko le wa lara Biafra to si tun sọ wipe oun setan lati du ipo aare orileede Naijiria.

Àkọlé fídíò, BIAFRA at 50: Ìhàlẹ̀ ológun ni Gowon ni ká kọ́kọ́ fi bẹ̀rẹ̀- Aladejẹbi