Ìgbẹ́jọ́ n tẹ̀síwáju lọ́la lóri Ọmọ Deborah Olorundare tó ní ìpèníjà ọpọlọ tí wọ́n jí gbé ní Ondo

Akure

Oríṣun àwòrán, Others

Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba méjì ni wọ́n fi ẹsùn kàn pé wọ́n ta ọmọ Deborah

Igbẹjọ yoo tẹsiwaju loni lori ẹsun jiji ọmọ arabirin Deborah Olorundare ti o ni ipenija ọpọlọ ni ipinlẹ Ondo ti wọn fi kan awọn oṣiṣẹ ijọba meji.

Awọn oṣiṣẹ naa, Adeyemi Sarumi ati Florence Orisamehin ni wọn koju ẹsun ilẹdi apọ pọ ati ijinigbe.

Ọmọ Deborah ti wọn tọju si ile awọn ọmọ alailobi kan nipinlẹ Ondo ki iya rẹ fi le gbadun ni ijọba sọpe awọn afẹsunkan naa ta fun obirin kan ni miliọnu kan naira.

Amọ, ni ipẹjọ akọkọ lori ọrọ ọun, awọn afẹsunkan sọ fún Onídájọ Adeyemi Fasanmi pe awọn ko jẹbi awọn ẹsun naa High Court Akure

Àkọlé fídíò, Eba

Onidajọ Fasanmi wa fun awọn mejeeji ni beeli miliọnu kan naira ati oniduro wọn ti o gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba ti owa ni akaṣọ kejila soke.

Ti a ko ba gbagbe, Ijọba ipinlẹ Ondo ti o jẹ olupẹjọ ti fi orukọ ẹlẹri mẹwaa silẹ lati gbẹ ẹjọ yii lẹsẹ.

Adari awọn agbẹjọro awọn olupẹjọ, Bunmi Koyenikan, lo wipe ijọba ti ṣetan ẹjọ bi ko ṣe ti iwe ti awọn olujẹjọ beere fun.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Agbẹjọro awọn afẹsunkan mejeeji, Steve Adebọwale ati Victor Olatoyegun, sọpe wọn ko le tẹsiwaju pẹlu ẹjọ yii ni ọjọ naa nitori pe wọn nilo lati gba awọn iwe akọsilẹ kan latọwọ awọn olupẹjọ lati fi ṣegbe lẹyin ẹjọ wọn.

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?